JOBU 28
28
Ọ̀rọ̀ Ìyìn Nípa Ọgbọ́n
1“Dájúdájú, ibìkan wà tí wọ́n ti ń wa fadaka,
ibìkan sì wà tí wọ́n ti ń yọ́ wúrà.
2Inú ilẹ̀ ni a ti ń wa irin,
a sì ń yọ́ idẹ lára òkúta.
3Eniyan á sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀,
a sì ṣe àwárí irin,
ninu ọ̀gbun ati òkùnkùn biribiri.
4Wọn á gbẹ́ kòtò ninu àfonífojì,
níbi tí ó jìnnà sí ibi tí eniyan ń gbé,
àwọn arìnrìnàjò á gbàgbé wọn,
wọn á takété sí àwọn eniyan, wọn á sì máa rọ̀ dirodiro sọ́tùn-ún sósì.
5Ní ti ilẹ̀, inú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde,
ṣugbọn lábẹ́ rẹ̀, ó dàbí ẹnipé iná ń yí i po,
ó gbóná janjan.
6Safire ń bẹ ninu àwọn òkúta rẹ̀,
wúrà sì ni erùpẹ̀ rẹ̀.
7Ẹyẹ àṣá kò mọ ipa ọ̀nà ibẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ojú gúnnugún kò tó o.
8Àwọn ẹranko onigbeeraga kò tíì tẹ ojú ọ̀nà náà,
kinniun kò sì tíì gba ibẹ̀ kọjá rí.
9“Eniyan á dá ọwọ́ rẹ̀ lé òkúta akọ, á gbẹ́ ẹ,
á sì hú òkè ńlá tìdítìdí.
10Á gbẹ́ ihò sinu àpáta,
ojú rẹ̀ a sì tó àwọn ìṣúra iyebíye.
11Á dí orísun àwọn odò,
tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi lè sun,
á sì wá àwọn ohun tí ó pamọ́ jáde.
12Ṣugbọn níbo ni a ti lè rí ọgbọ́n?
Níbo sì ni ìmọ̀ wà?#Sir 1:16; Bar 3:15
13“Ẹnikẹ́ni kò mọ ọ̀nà ibi tí ó wà;
bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ilẹ̀ alààyè.
14Ibú sọ pé, ‘Kò sí ninu mi,’
òkun sì ní, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi.’
15Wúrà iyebíye kò lè rà á,
fadaka kò sì ṣe é díwọ̀n iye rẹ̀.
16A kò lè fi wúrà Ofiri díwọ̀n iye rẹ̀,
tabi òkúta onikisi tabi safire tí wọ́n jẹ́ òkúta olówó iyebíye.
17Ọgbọ́n níye lórí ju wúrà ati dígí lọ,
a kò lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà dáradára ṣe dípò rẹ̀.
18Kí á má tilẹ̀ sọ ti iyùn tabi Kristali,
ọgbọ́n ní iye lórí ju òkúta Pali lọ.
19A kò lè fi wé òkúta topasi láti ilẹ̀ Etiopia,
tabi kí á fi ojúlówó wúrà rà á.#Bar 3:29-31
20“Níbo ni ọgbọ́n ti ń wá;
níbo sì ni ìmọ̀ wà?
21Ó pamọ́ lójú gbogbo ẹ̀dá alààyè,
ati lójú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.
22Ìparun ati ikú jẹ́wọ́ pé,
‘Àhesọ ni ohun tí a gbọ́ nípa rẹ̀.’
23“Ọlọrun nìkan ló mọ ọ̀nà rẹ̀,
òun nìkan ló mọ ibùjókòó rẹ̀.#Bar 3:35-37
24Nítorí pé ó ń wo gbogbo ayé,
ó sì ń rí ohun gbogbo tí ó wà lábẹ́ ọ̀run.
25Nígbà tí ó fún afẹ́fẹ́ ní agbára,
tí ó sì ṣe ìdíwọ̀n omi,
26nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,
tí ó sì lànà fún mànàmáná.
27Lẹ́yìn náà ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde,
ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò.#Sir 1:9,19
28Nígbà náà ni ó sọ fún eniyan pé,
‘Wò ó, ìbẹ̀rù OLUWA ni ọgbọ́n,
kí á yẹra fún ibi sì ni ìmọ̀.’ ”#O. Daf 111:10; Owe 1:7; 9:10
Currently Selected:
JOBU 28: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010