JOBU 34
34
1Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní,
2“Ẹ gbọ́rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n,
ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ ní ìmọ̀,
3nítorí bí ahọ́n ti í máa ń tọ́ oúnjẹ wò,
bẹ́ẹ̀ ni etí náà lè máa tọ́ ọ̀rọ̀ wò
4Ẹ jẹ́ kí á yan ohun tí ó tọ́,
kí á jọ jíròrò ohun tí ó dára láàrin ara wa.
5Jobu sọ pé òun kò jẹ̀bi,
ó ní Ọlọrun ni ó kọ̀ tí kò dá òun láre.
6Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jàre, Ọlọrun ka òun kún òpùrọ́,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò dẹ́ṣẹ̀, ọgbẹ́ òun kò ṣe é wòsàn.
7“Ta ló dàbí Jobu,
tí ń kẹ́gàn Ọlọrun nígbà gbogbo,
8tí ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́,
tí ó sì ń bá àwọn eniyan burúkú rìn?
9Nítorí ó ń sọ pé, ‘Kò sí èrè kankan,
ninu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun.’
10“Nítorí náà ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin olóye,
Ọlọrun kì í ṣe ibi,
Olodumare kì í ṣe ohun tí kò tọ́.
11Nítorí a máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀
ati gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀.
12Nítòótọ́, Ọlọrun kì í ṣe ibi,
bẹ́ẹ̀ ni Olodumare kì í dájọ́ èké.
13Ta ló fi í ṣe alákòóso ayé,
ta ló sì fi jẹ olórí gbogbo ayé?
14Bí Ọlọrun bá gba ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
tí ó sì gba èémí rẹ̀ pada sọ́dọ̀,
15gbogbo eniyan ni yóo ṣègbé,
tí wọn yóo sì pada di erùpẹ̀. #O. Daf 62:12
16“Bí ẹ bá ní òye, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ.
17Ǹjẹ́ ẹni tí ó kórìíra ìdájọ́ ẹ̀tọ́ lè jẹ́ olórí?
Àbí ẹ lè dá olódodo ati alágbára lẹ́bi?
18Ẹni tí ó tó pe ọba ní eniyan lásán,
tí ó tó pe ìjòyè ní ẹni ibi;
19ẹni tí kì í ṣe ojuṣaaju fún àwọn ìjòyè,
tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju talaka lọ,
nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.
20Wọn á kú ikú òjijì, ní ọ̀gànjọ́ òru;
á mi gbogbo eniyan jìgìjìgì, wọn a sì kú.
Ikú á mú àwọn alágbára lọ láì jẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn wọ́n.
21Nítorí pé ojú rẹ̀ tó gbogbo ọ̀nà tí eniyan ń tọ̀,
ó sì rí gbogbo ìrìn ẹsẹ̀ wọn.
22Kò sí ibi òkùnkùn biribiri kankan,
tí àwọn eniyan burúkú lè fi ara pamọ́ sí.
23Nítorí Ọlọrun kò nílò láti yan àkókò kan fún ẹnikẹ́ni,
láti wá siwaju rẹ̀ fún ìdájọ́.
24Á pa àwọn alágbára run láìṣe ìwádìí wọn,
á sì fi àwọn ẹlòmíràn dípò wọn.
25Nítorí pé ó mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
á bì wọ́n ṣubú lóru, wọn á sì parun.
26Á máa jẹ wọ́n níyà ní gbangba,
nítorí ìwà ibi wọn.
27Nítorí pé wọ́n kọ̀ láti tẹ̀lé e,
wọn kò náání ọ̀nà rẹ̀ kankan,
28wọ́n ń jẹ́ kí àwọn talaka máa kígbe sí Ọlọrun,
a sì máa gbọ́ igbe àwọn tí a ni lára.
29“Bí Ọlọrun bá dákẹ́,
ta ló lè bá a wí?
Nígbà tí ó bá fi ojú pamọ́,
orílẹ̀-èdè tabi eniyan wo ló lè rí i?
30Kí ẹni ibi má baà lè ṣe àkóso,
kí ó má baà kó àwọn eniyan sinu ìgbèkùn.
31“Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tíì sọ fún Ọlọrun pé,
‘Mo ti jìyà rí, n kò sì ní gbẹ̀ṣẹ̀ mọ́.
32Kọ́ mi ní ohun tí n kò rí,
bí mo bá ti ṣẹ̀ rí, n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́?’
33Ṣé yóo san ẹ̀san fún ọ lọ́nà tí ó tẹ́ ọ lọ́rùn,
nítorí pé o kọ̀ ọ́?
Nítorí ìwọ ni o gbọdọ̀ yan ohun tí ó bá wù ọ́, kì í ṣe èmi,
nítorí náà, sọ èrò ọkàn rẹ fún wa.
34Àwọn tí wọ́n lóye yóo sọ fún mi,
àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọn ń gbọ́ mi yóo sọ pẹlu pé,
35‘Jobu ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀,
ó ń sọ̀rọ̀ láìní òye tí ó jinlẹ̀.’
36À bá lè gbé ọ̀rọ̀ Jobu yẹ̀wò títí dé òpin,
nítorí pé ó ń sọ̀rọ̀ bí eniyan burúkú.
37Ó fi ọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá;
ó ń pàtẹ́wọ́ ẹlẹ́yà láàrin wa,
ó sì ń kẹ́gàn Ọlọrun.”
Currently Selected:
JOBU 34: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010