YouVersion Logo
Search Icon

JOBU 39

39
1“Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ?
Ṣé o ti ká àgbọ̀nrín mọ́ ibi tí ó ti ń bímọ rí?
2Ǹjẹ́ o lè ka iye oṣù tí wọ́n fi ń lóyún?
Tabi o mọ ìgbà tí wọ́n bímọ?
3Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀,
tí wọ́n sì bímọ?
4Àwọn ọmọ wọn á di alágbára,
wọn á dàgbà ninu pápá,
wọn á sì lọ, láìpadà wá sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn mọ́.
5“Ta ló fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ lómìnira
tí ó sì tú ìdè rẹ̀?
6Mo fi inú pápá ṣe ilé rẹ̀,
ilẹ̀ oníyọ̀ sì di ibùgbé rẹ̀.
7Ó ń pẹ̀gàn ìdàrúdàpọ̀ inú ìlú ńlá,
kò gbọ́ ariwo àwọn tí wọn ń fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣiṣẹ́.
8Ó ń rìn káàkiri àwọn òkè bí ibùjẹ rẹ̀,
ó sì ń wá ewéko tútù kiri.
9“Ṣé ẹfọ̀n ṣetán láti sìn ọ́?
Ṣé yóo wá sùn ní ibùjẹ ẹran rẹ lálẹ́?
10Ṣé o lè so àjàgà mọ́ ọn lọ́rùn ní poro oko,
tabi kí ó máa kọ ebè tẹ̀lé ọ?
11Ṣé o lè gbẹ́kẹ̀lé e nítorí pé agbára rẹ̀ pọ̀,
tabi kí o fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ fún un láti ṣe?
12Ṣé o ní igbagbọ pé yóo pada,
ati pé yóo ru ọkà rẹ̀ wá sí ibi ìpakà rẹ?
13“Ògòǹgò lu ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ninu ọláńlá rẹ̀,
ṣugbọn kò lè fò bí ẹyẹ àkọ̀?
14Ó yé ẹyin rẹ̀ sórí ilẹ̀,
kí ooru ilẹ̀ lè mú wọn,
15ó gbàgbé pé ẹnìkan le tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ kí wọn sì fọ́,
ati pé ẹranko ìgbẹ́ lè fọ́ wọn.
16Ògòǹgò kò náání àwọn ọmọ rẹ̀,
ó ń ṣe sí wọn bí ẹni pé kì í ṣe òun ló bí wọn,
kò bìkítà bí wahala rẹ̀ tilẹ̀ já sí asán;
17nítorí pé Ọlọrun kò fún un ní ọgbọ́n ati òye.
18Ṣugbọn nígbà tí ó bá ṣetán ati sáré,
a máa fi ẹṣin ati ẹni tí ó gùn ún ṣe yẹ̀yẹ́.
19“Ṣé ìwọ ni o fún ẹṣin lágbára,
tí o sì fi agbára ṣe gọ̀gọ̀ sí i lọ́rùn?
20Ṣé ìwọ lò ń mú kí ó máa ta pọ́nún bí eṣú,
tí kíké rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù?
21Ó fẹsẹ̀ walẹ̀ ní àfonífojì,
ó yọ̀ ninu agbára rẹ̀,
ó sì jáde lọ sí ojú ogun.
22Kò mọ ẹ̀rù, ọkàn rẹ̀ kì í rẹ̀wẹ̀sì,
bẹ́ẹ̀ ni kì í sá fún idà.
23Ó gbé apó ọfà sẹ́yìn, tí ń mì pẹkẹpẹkẹ, pẹlu ọ̀kọ̀
tí ń kọ mànà, ati apata.
24Ó ń fi ẹnu họlẹ̀ pẹlu ìgboyà ati ìwàǹwára,
nígbà tí ipè dún, ara rẹ̀ kò balẹ̀.
25Nígbà tí fèrè dún, ó kọ, ‘Hàáà!’
Ó ń gbóòórùn ogun lókèèrè,
ó ń gbọ́ igbe ọ̀gágun tí ń pàṣẹ.
26“Ṣé ìwọ lo kọ́ àwòdì bí a ti í fò,
tí ó fi na ìyẹ́ rẹ̀ sí ìhà gúsù?
27Ṣé ìwọ ni o pàṣẹ fún idì láti fò lọ sókè,
tabi láti tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sórí òkè gíga?
28Ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí òkè gíga-gíga,
ninu pàlàpálá àpáta.
29Níbẹ̀ ni ó ti ń ṣọ́ ohun tí yóo pa,
ojú rẹ̀ a sì rí i láti òkèèrè réré.
30Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa mu ẹ̀jẹ̀,
ibi tí òkú bá sì wà ni idì máa ń wà.”#Mat 24:28; Luk 17:37

Currently Selected:

JOBU 39: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in