JOBU 5
5
1“Pe ẹnìkan nisinsinyii;
ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni dá ọ lóhùn?
Ẹni mímọ́ wo ni o lè tọ̀ lọ?
2Dájúdájú ibinu a máa pa òmùgọ̀,
owú jíjẹ a sì máa pa aláìmọ̀kan.
3Mo ti rí òmùgọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀,
ṣugbọn lójijì, ibùgbé rẹ̀ di ìfibú.
4Kò sí ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀,
wọ́n di àtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹnubodè,
kò sì sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n là.
5Àwọn tí ebi ń pa níí jẹ ìkórè oko rẹ̀,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrin ẹ̀gún
ni ó ti mú un jáde,
àwọn olójúkòkòrò a sì máa wá ohun ìní rẹ̀ kiri.
6Ìṣòro kì í hù láti inú erùpẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ìyọnu kì í ti inú ilẹ̀ jáde.
7A bí eniyan sinu wahala
bí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè.
8“Ní tèmi, n óo máa wá OLUWA,
n óo fọ̀rọ̀ mi lé Ọlọrun lọ́wọ́;
9ẹni tíí ṣe ohun ńlá
tí eniyan kò lè rídìí,
ati àwọn ohun ìyanu tí kò lóǹkà.#Sir 43:32
10A máa rọ òjò sórí ilẹ̀,
a sì máa bomi rin oko.
11A máa gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga,
a sì máa pa àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ mọ́.
12A máa da ète àwọn alárèékérekè rú,
kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn.
13Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn;
ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin.#1 Kọr 3:19
14Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan,
wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni.
15Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn,
ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára.
16Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka,
a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.
17“Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí Ọlọrun bá bá wí,
nítorí náà, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olodumare.#Owe 3:11-12; Heb 12:5-6
18Ó ń ṣá ni lọ́gbẹ́,
ṣugbọn ó tún ń dí ọgbẹ́ ẹni.
Ó ń pa ni lára,
ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ ló tún fi ń ṣe ìwòsàn.#Hos 6:1
19Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ìnira lọpọlọpọ ìgbà,
bí ibi ń ṣubú lu ara wọn,
kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ.
20Ní àkókò ìyàn,
yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú.
Ní àkókò ogun,
yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
21Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gàn,
o kò ní bẹ̀rù nígbà tí ìparun bá dé.
22Ninu ìparun ati ìyàn,
o óo máa rẹ́rìn-ín,
o kò ní bẹ̀rù àwọn ẹranko ìgbẹ́.
23O kò ní kan àwọn òkúta ninu oko rẹ,
àwọn ẹranko igbó yóo wà ní alaafia pẹlu rẹ.
24O óo máa gbé ilé rẹ ní àìséwu.
Nígbà tí o bá ka ẹran ọ̀sìn rẹ,
kò ní dín kan.
25Àwọn arọmọdọmọ rẹ yóo pọ̀,
bí ewéko ninu pápá oko.
26O óo di arúgbó kí o tó kú,
gẹ́gẹ́ bí ọkà tií gbó
kí á tó kó o wá síbi ìpakà.
27Wò ó! A ti wádìí àwọn nǹkan wọnyi,
òtítọ́ ni wọ́n.
Gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.”
Currently Selected:
JOBU 5: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010