YouVersion Logo
Search Icon

JOBU 9

9
1Jobu dáhùn pé:
2“Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí,
ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?
3Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn,
olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè.
4Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀,
agbára rẹ̀ sì pọ̀.
Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ?
5Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀;
tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú.
6Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀,
àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì.
7Ó pàṣẹ fún oòrùn,
oòrùn kò sì yọ;
ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé;
8òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ,
tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀.
9Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run:
Beari, Orioni, ati Pileiadesi
ati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù.
10Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá,
ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà.
11Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i,
ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀.
12Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà,
ta ló lè dá a dúró?
Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’#Job 4:17 #Bar 3:34-35 #Job 38:31; Amos 5:8
13“Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,
yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀.
14Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́?
Kí ni kí n sọ?
15Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi,
sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn.
Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú,
lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí.
16Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́,
tí ó sì dá mi lóhùn,
sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi.
17Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀,
ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí;
18kò ní jẹ́ kí n mí,
ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi.
19Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni,
agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ!
Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́,
ta ló lè pè é lẹ́jọ́?
20Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi,
sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí;
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀,
sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.
21N kò lẹ́bi,
sibẹ n kò ka ara mi kún,
ayé sú mi.
22Kò sí ìyàtọ̀ lójú rẹ̀,
nítorí náà ni mo fi wí pé,
ati ẹlẹ́bi ati aláìlẹ́bi ni ó ti parun.
23Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀,
tí ó já sí ikú òjijì,
a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn.
24A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,
ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú.
Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun,
ta ló tún tó bẹ́ẹ̀?
25“Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete,
kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn.
26Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi,
bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa.
27Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi,
kí n sì tújúká;
kí n má ronú mọ́;
28ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí,
nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀.
29Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá mi lẹ́bi,
kí ni mo tún ń ṣe wahala lásán fún?
30Ọṣẹ yòówù tí mo lè fi wẹ̀,
kódà kí n fi omi yìnyín fọ ọwọ́,
31sibẹ o óo tì mí sinu kòtò ìdọ̀tí.
Kódà n óo di ohun ìríra sí aṣọ ara mi.
32Ọlọrun kì í ṣe eniyan bíì mi,
tí mo fi lè fún un lésì,
tí a fi lè jọ rojọ́ ní ilé ẹjọ́.
33Kò sí ẹnìkẹta láàrin àwa mejeeji,
tí ó lè dá wa lẹ́kun.
34Kí ó sọ pàṣán rẹ̀ sílẹ̀,
kí ó má nà mí mọ́!
Kí ìbẹ̀rù rẹ̀ má sì pá mi láyà mọ́!
35Kí n baà le sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù,
nítorí mo mọ inú ara mi.

Currently Selected:

JOBU 9: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in