YouVersion Logo
Search Icon

LUKU 22

22
Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Jesu
(Mat 26:1-5, 14-16; Mak 14:1-2, 10-11; Joh 11:45-53)
1Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Àìwúkàrà tí à ń pè ní Àjọ̀dún Ìrékọjá.#Eks 12:1-27 2Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe pa Jesu nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan.
3Satani bá wọ inú Judasi tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. 4Ó bá lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili láti bá wọn sọ̀rọ̀ bí ọwọ́ wọn yóo ṣe tẹ Jesu. 5Inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ètò láti fún un ní owó. 6Ó gbà bẹ́ẹ̀; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ lọ́nà tí ọ̀pọ̀ eniyan kò fi ní mọ̀.
Ìpalẹ̀mọ́ fún Àsè Ìrékọjá
(Mat 26:17-25; Mak 14:12-21; Joh 13:21-30)
7Nígbà tí ó di ọjọ́ Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọ́n níláti pa ẹran àsè Ìrékọjá, 8Jesu rán Peteru ati Johanu, ó ní, “Ẹ lọ ṣe ìtọ́jú ohun tí a óo fi jẹ àsè Ìrékọjá.”
9Wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á lọ ṣe ètò sí?”
10Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ẹ bá wọ inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín. Ẹ tẹ̀lé e, ẹ bá a wọ inú ilé tí ó bá wọ̀. 11Kí ẹ sọ fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ni sọ pé níbo ni yàrá ibi tí òun óo ti jẹ àsè Ìrékọjá pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn òun wà?’ 12Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí a ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.”
13Ni wọ́n bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.
Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa
(Mat 26:26-30; Mak 14:22-26; 1 Kọr 11:23-25)
14Nígbà tí ó tó àkókò oúnjẹ, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn aposteli rẹ̀. 15Ó sọ fún wọn pé, “Ó ti mú mi lọ́kàn pupọ láti jẹ àsè Ìrékọjá yìí pẹlu yín kí n tó jìyà. 16Nítorí mo sọ fun yín pé n kò tún ní jẹ ẹ́ mọ́ títí di àkókò tí yóo fi ní ìtumọ̀ tí ó pé ní ìjọba Ọlọrun.”
17Ó bá mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní, “Ẹ gba èyí, kí ẹ pín in láàrin ara yín. 18Nítorí mo sọ fun yín pé láti àkókò yìí lọ, n kò tún ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo fi dé.”
19Ó bá mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú, ó bá fún wọn. Ó ní, “Èyí ni ara mi tí a fun yín. [Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” 20Bákan náà ni ó gbé ife fún wọn lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Ife yìí ni majẹmu titun tí Ọlọrun ba yín dá pẹlu ẹ̀jẹ̀ mi tí a ta sílẹ̀ fun yín.]#Jer 31:34
21“Ṣugbọn ṣá o, ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ń bá mi tọwọ́ bọwọ́ níbi oúnjẹ yìí.#O. Daf 41:9 22Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti yan ìpín tirẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé!”
23Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí wádìí láàrin ara wọn pé ta ni ìbá jẹ́ ninu wọn tí yóo dán irú rẹ̀ wò.
Ìjiyàn Nípa Ẹni Tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ
24Ìjiyàn kan wà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé ta ni ó jẹ́ ẹni pataki jùlọ.#Mat 18:1; Mak 9:34; Luk 9:46 25Jesu sọ fún wọn pé, “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn. Àwọn aláṣẹ wọn ni wọ́n ń pè ní olóore wọn. 26Ṣugbọn tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ẹni tí yóo bá jẹ́ ẹni tí ó ṣe pataki jùlọ ninu yín níláti dàbí ọmọ tí ó kéré jùlọ. Ẹni tí yóo jẹ́ aṣaaju níláti máa ṣe bí iranṣẹ.#Mat 20:25-27; Mak 10:42-44 #Mat 23:11; Mak 9:35 27Nítorí ta ni eniyan pataki? Ẹni tí ó jókòó tí ó ń jẹun ni, tabi ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ? Mo ṣebí ẹni tí ó ń jẹun ni. Ṣugbọn èmi wà láàrin yín bí ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ.#Joh 13:12-15
28“Ẹ̀yin ni ẹ dúró tì mí ní gbogbo àkókò ìdánwò mi. 29Gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti fi ìjọba fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà fi ìjọba fun yín, 30kí ẹ lè bá mi jẹ, kí ẹ sì bá mi mu ninu ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli mejila.#Mat 19:28
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun
(Mat 26:31-35; Mak 14:27-31; Joh 13:36-38)
31“Simoni! Simoni! Ṣọ́ra o! Satani ti gba àṣẹ láti dán gbogbo yín wò, bí ìgbà tí eniyan bá ń fẹ́ fùlùfúlù kúrò lára ọkà. 32Ṣugbọn mo ti gbadura fún ọ Simoni, pé kí igbagbọ rẹ kí ó má yẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá ronupiwada, mu àwọn arakunrin rẹ lọ́kàn le.”
33Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Oluwa, mo ṣetán láti bá ọ wẹ̀wọ̀n, ati láti bá ọ kú.”
34Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Peteru mò ń sọ fún ọ pé kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ẹẹmẹta ni ìwọ óo sọ pé o kò mọ̀ mí rí!”
Idà Meji
35Ó wá sọ fún wọn pé, “Nígbà tí mo ran yín níṣẹ́ tí mo sọ fun yín pé kí ẹ má mú àpò owó ati igbá báárà lọ́wọ́, ati pé kí ẹ má wọ bàtà, kí ni ohun tí ẹ ṣe aláìní?”#Mat 10:9-10; Mak 6:8-9; Luk 9:3; 10:4
Wọ́n dáhùn pé, “Kò sí!”
36Ó wá sọ fún wọn pé, “Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un lọ́wọ́; ẹni tí ó bá ní igbá báárà, kí òun náà gbé e lọ́wọ́. Ẹni tí kò bá ní idà, kí ó ta ẹ̀wù rẹ̀ kí ó fi ra idà kan. 37Nítorí mo wí fun yín pé ohun gbogbo tí a ti kọ sílẹ̀ nípa mi níláti ṣẹ, pé, ‘A kà á kún àwọn arúfin.’ Ohun tí a sọ nípa mi yóo ṣẹ.”#Ais 53:12
38Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wò ó! Idà meji nìyí.”
Ó sọ fún wọn pé, “Ó tó!”
Adura Lórí Òkè Olifi
(Mat 26:36-46; Mak 14:32-42)
39Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e. 40Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa gbadura kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”
41Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura. 42Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [ 43Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi. 44Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.]
45Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́. 46Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”
Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá
(Mat 26:47-56; Mak 14:43-50; Joh 18:3-11)
47Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ ni àwọn eniyan bá dé. Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ni ó ṣiwaju wọn. Ó bá súnmọ́ Jesu, ó fi ẹnu kò ó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. 48Jesu sọ fún un pé, “Judasi! O sì fi ẹnu ko Ọmọ-Eniyan ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ láti fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́?”
49Nígbà tí àwọn tí ó wà pẹlu Jesu rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé kí á fa idà yọ?” 50Ni ọ̀kan ninu wọ́n bá ṣá ẹrú olórí alufaa kan, ó bá gé e ní etí ọ̀tún.
51Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀.” Ó bá fọwọ́ kan etí ẹrú náà, etí náà sì san.
52Ó wá sọ fún àwọn olórí alufaa, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn àgbà tí wọ́n wá mú un pé, “Ọlọ́ṣà ni ẹ pè mí ni, tí ẹ fi kó idà ati kùmọ̀ wá? 53Ṣebí ojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili. Ẹ kò ṣe fọwọ́ kàn mí? Ṣugbọn àkókò yín ati ti aláṣẹ òkùnkùn nìyí.”#Luk 19:47; 21:37
Peteru Sẹ́ Jesu
(Mat 26:57-58, 69-75; Mak 14:53-54, 66-72; Joh 18:12-18, 25-27)
54Wọ́n bá mú Jesu, wọ́n fà á lọ sí ilé Olórí Alufaa. Ṣugbọn Peteru ń tẹ̀lé wọn lókèèrè. 55Àwọn kan dá iná sáàrin agbo-ilé, wọ́n jókòó yí i ká, Peteru náà wà láàrin wọn. 56Ọmọdebinrin kan wá rí i, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu.”
57Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “N kò tilẹ̀ mọ ọkunrin yìí!”
58Nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ẹlòmíràn tún rí i, ó ní, “Ìwọ náà wà láàrin wọn.”
Ṣugbọn Peteru ní, “Ọkunrin yìí, n kò sí níbẹ̀!”
59Nígbà tí ó tó bíi wakati kan, ọkunrin kan tún sọ pẹlu ìdánilójú pé, “Láìsí àní-àní ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu, nítorí ará Galili ni.”
60Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Ọkunrin yìí, n kò mọ ohun tí ò ń sọ!”
Lẹsẹkẹsẹ, ó fẹ́rẹ̀ ma tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, àkùkọ bá kọ. 61Oluwa yipada, ó wo Peteru, Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ìwọ yóo sẹ́ mi lẹẹmẹta.” 62Peteru bá jáde lọ, ó bú sẹ́kún, ó bẹ̀rẹ̀ sí hu gan-an.
Wọ́n Fi Jesu Ṣẹ̀sín
(Mat 26:67-68; Mak 14:65)
63Àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣọ́ Jesu ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń lù ú. 64Wọ́n daṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń bi í pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́?” 65Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọ oríṣìíríṣìí ìsọkúsọ sí i.
Wọ́n Mú Jesu Lọ siwaju Ìgbìmọ̀
(Mat 26:59-66; Mak 14:55-64; Joh 18:19-24)
66Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin péjọ, wọ́n fa Jesu lọ siwaju ìgbìmọ̀ wọn. 67Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, ṣé ìwọ ni Mesaya náà?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá sọ fun yín, ẹ kò ní gbàgbọ́. 68Bí mo bá sì bi yín ní ìbéèrè, ẹ kò ní dáhùn. 69Láti àkókò yìí, Ọmọ-Eniyan yóo jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun Olodumare.”
70Gbogbo wọn wá bi í pé, “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọrun?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹnu ara yín ni ẹ fi sọ pé, èmi ni.”
71Ni wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Nítorí àwa fúnra wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó fẹnu ara rẹ̀ sọ.”

Currently Selected:

LUKU 22: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in