YouVersion Logo
Search Icon

LUKU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìyìn Rere Luku fi Jesu hàn wá gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí fún Israẹli ati Olùgbàlà gbogbo eniyan. Luku kọ ọ́ sinu àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé Ẹ̀mí Oluwa ló pe Jesu láti “waasu Ìròyìn Ayọ̀ fún àwọn òtòṣì.” Ìtara fún àwọn eniyan tí wọ́n ṣe aláìní ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni ó sì kún inú Ìyìn Rere yìí, pataki jùlọ ninu àwọn orí tí wọ́n wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí tí ó ṣe ìkéde dídé Jesu, bẹ́ẹ̀ náà sì tún ni ní ìparí ìwé Luku, nígbà tí Jesu gòkè re ọ̀run. Ẹni tí ó kọ Ìyìn Rere Luku náà ni ó kọ ìtàn ìtànkálẹ̀ ìsìn igbagbọ ninu ìwé Ìṣe Àwọn Aposteli.
Gẹ́gẹ́ bí a ti to “Àwọn ohun tí ó wà ninu ìwé yìí ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí”, apá keji ati apá kẹfa kún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó jẹ́ pé ninu Ìyìn Rere yìí nìkan ni a ti sọ nípa wọn. Lára irú ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi ni orin tí àwọn angẹli kọ, ati ìbẹ̀wò àwọn olùṣọ́-aguntan ní àkókò tí a bí Jesu. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìtàn bí Jesu ṣe lọ sinu Tẹmpili nígbà tí ó wà ní ọmọde, ati òwe Aláàánú ará Samaria, ati ti ọmọ tí ó sọnù. Jákèjádò ìwé Ìyìn Rere yìí ni ẹni tí ó kọ ọ́ tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ adura, ati ti Ẹ̀mí Mímọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni ti ipa tí àwọn obinrin kó ninu iṣẹ́ tí Jesu ṣe láyé, ati ọ̀rọ̀ lórí bí Ọlọrun ṣe máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-4
Ìbí Johanu Onítẹ̀bọmi ati ti Jesu, ati ìgbà èwe wọn 1:5–2:52
Iṣẹ́ tí Johanu Onítẹ̀bọmi ṣe 3:1-20
Ìrìbọmi ati ìdánwò Jesu 3:21–4:13
Iṣẹ́ tí Jesu ṣe ní gbangba ní Galili 4:14–9:50
Láti Galili dé Jerusalẹmu 9:51–19:27
Ọ̀sẹ̀ ìkẹyìn Jesu ní Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀ 19:28–23:56
Ajinde, ìfarahàn, ati ìgòkè-re-ọ̀run Oluwa 24:1-53

Currently Selected:

LUKU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in