MAKU 8
8
1Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ọpọlọpọ eniyan tún wà lọ́dọ̀ Jesu, tí wọn kò rí nǹkan jẹ, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, 2“Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà pẹlu mi, wọn kò ní ohun tí wọn yóo jẹ mọ́. 3Bí mo bá ní kí wọn túká lọ sí ilé wọn ní ebi, yóo rẹ̀ wọ́n lọ́nà, nítorí àwọn mìíràn ninu wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.”
4Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Níbo ni a óo ti rí ohun tí a óo fún gbogbo àwọn wọnyi jẹ ní aṣálẹ̀ yìí?”
5Jesu bi wọ́n pé, “Burẹdi mélòó ni ẹ ní?”
Wọ́n ní, “Meje.”
6Ó bá pàṣẹ kí àwọn eniyan jókòó ní ilẹ̀. Ó mú burẹdi meje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. 7Wọ́n tún ní àwọn ẹja kéékèèké díẹ̀. Ó gbadura sí i, ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pín in fún àwọn eniyan. 8-9Àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó ẹ̀rúnrún àjẹkù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ ńlá meje. Àwọn eniyan tí wọn jẹun tó bí ẹgbaaji (4,000). Lẹ́yìn náà Jesu ní kí wọn túká. 10Lẹsẹkẹsẹ ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá lọ sí agbègbè Dalimanuta.
Àwọn Farisi ń fẹ́ Àmì
(Mat 16:1-4)
11Àwọn Farisi jáde lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò nípa fífi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run hàn wọ́n.#Mat 12:38; Luk 11:16 12Inú rẹ̀ bàjẹ́, ó ní, “Nítorí kí ni àwọn eniyan ṣe ń wá àmì lóde òní? Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé a kò ní fún wọn ní àmì kan.”#Mat 12:39; Luk 11:29
13Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó lọ sí òdìkejì òkun.
Ìwúkàrà Àwọn Farisi ati Ti Hẹrọdu
(Mat 16:5-12)
14Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu gbàgbé láti mú burẹdi lọ́wọ́ àfi ọ̀kan ṣoṣo tí wọn ní ninu ọkọ̀ ojú omi. 15Jesu bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati ìwúkàrà Hẹrọdu.”#Luk 12:1
16Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò ní burẹdi ni.”
17Nígbà tí Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàrin ara yín pé nítorí ẹ kò ní burẹdi lọ́wọ́ ni? Ẹ kò ì tíì mọ̀ sibẹ, tabi òye kò ì tíì ye yín? Àṣé ọkàn yín le tóbẹ́ẹ̀? 18Ẹ ní ojú lásán ni, ẹ kò ríran? Ẹ ní etí lásán ni, ẹ kò fi gbọ́ràn?#Jer 5:21; Isi 12:2; Mak 4:12. 19Ẹ kò ranti nígbà tí mo bu burẹdi marun-un fún ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan, agbọ̀n mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Mejila.”
20Ó tún bi wọ́n pé, “Nígbà tí mo fi burẹdi meje bọ́ àwọn ẹgbaaji (4,000) eniyan, agbọ̀n ńlá mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Meje.”
21Ó tún bi wọ́n pé, “Kò ì tíì ye yín sibẹ?”
Jesu Wo Afọ́jú kan Sàn ní Bẹtisaida
22Wọ́n dé Bẹtisaida. Àwọn ẹnìkan mú afọ́jú kan wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó fọwọ́ kàn án. 23Ó bá fa afọ́jú náà lọ́wọ́ jáde lọ sí ẹ̀yìn abúlé, ó tutọ́ sí i lójú. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ o rí ohunkohun?”
24Ọkunrin náà ríran bàìbàì, ó ní, “Mo rí àwọn eniyan tí ń rìn, ṣugbọn bí igi ni wọ́n rí lójú mi.”
25Lẹ́yìn náà Jesu tún fi ọwọ́ kàn án lójú. Ọkunrin náà tẹjú mọ́ àwọn nǹkan tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ojú rẹ̀ sì bọ̀ sípò, ó wá rí gbogbo nǹkan kedere, títí kan ohun tí ó jìnnà. 26Jesu wí fún un pé, kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má ṣe wọ inú abúlé lọ.#8:26 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní gbolohun tí ó yàtọ̀ sí èyí, báyìí: Ó ní, “Má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni ninu abúlé.”
Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni Tí Jesu Í Ṣe
(Mat 16:13-20; Luk 9:18-21)
27Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí àwọn abúlé tí ó wà lẹ́bàá ìlú Kesaria ti Filipi. Bí wọ́n ti ń lọ ní ọ̀nà, ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan ń pè mí?”
28Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ń pè ọ́ ní Johanu Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn ní Elija ni ọ́, àwọn mìíràn tún ní ọ̀kan ninu àwọn wolii ni ọ́.”#Mak 6:14-15; Luk 9:7-8
29Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́, ta ni ẹ̀yin ń pè mí?”#Joh 6:68-69.
Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.”
30Ó bá kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni.
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀
(Mat 16:21-28; Luk 9:22-27)
31Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn pé, “Ọmọ-Eniyan níláti jìyà pupọ. Àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin yóo ta á nù, wọn yóo sì pa á, ṣugbọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹta yóo jí dìde.” 32Ó ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn kedere. Nígbà náà ni Peteru mú un, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí. 33Ṣugbọn Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá Peteru wí. Ó ní, “Kó ara rẹ kúrò níwájú mi, ìwọ Satani. Ìwọ kò kó ohun ti Ọlọrun lékàn àfi ti ayé.”
34Ó pe àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti gbàgbé ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó wá máa tẹ̀lé mi.#Mat 10:38; Luk 14:27 35Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là.#Mat 10:39; Luk 17:33; Joh 12:25 36Nítorí anfaani kí ni ó jẹ́ fún eniyan kí ó jèrè gbogbo dúkìá ayé yìí, ṣugbọn kí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀? 37Kí ni eniyan lè fi ṣe pàṣípààrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? 38Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú èmi ati ọ̀rọ̀ mi ní àkókò burúkú yìí, tí àwọn eniyan kò ka nǹkan Ọlọrun sí, Ọmọ-Eniyan yóo tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli mímọ́.”
Currently Selected:
MAKU 8: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010