NEHEMAYA 11
11
Àwọn Eniyan Tí Wọn Ń Gbé Jerusalẹmu
1Àwọn olórí àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu, àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù dìbò láti yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá láti lọ máa gbé Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, àwọn mẹsan-an yòókù sì ń gbé àwọn ìlú yòókù. 2Àwọn eniyan náà súre fún àwọn tí wọ́n fa ara wọn kalẹ̀ láti lọ máa gbé Jerusalẹmu.
3Àwọn ìjòyè ní àwọn agbègbè wọn ń gbé Jerusalẹmu, ṣugbọn ní àwọn ìlú Juda, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ń gbé orí ilẹ̀ rẹ̀, ní ìlú wọn, títí kan àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati àwọn ìran iranṣẹ Solomoni. 4Àwọn ọmọ Juda kan, ati àwọn ọmọ Bẹnjamini kan ń gbé Jerusalẹmu. Àwọn ọmọ Juda náà ni: Ataaya, ọmọ Usaya, ọmọ Sakaraya, ọmọ Amaraya, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Mahalaleli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Pẹrẹsi.#Neh 7:73
5Bẹ́ẹ̀ náà ni Maaseaya, ọmọ Baruku, ọmọ Kolihose, ọmọ Hasaya, ọmọ Adaya, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sakaraya, ọmọ ará Ṣilo.
6Gbogbo àwọn ọmọ Peresi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu jẹ́ akọni, wọ́n jẹ́ ọtalenirinwo ó lé mẹjọ (468).
7Àwọn ọmọ Bẹnjamini ni: Salu ọmọ Meṣulamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaaya, ọmọ Kolaya, ọmọ Maaseaya, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaya.
8Lẹ́yìn rẹ̀ ni Gabai ati Salai. Àpapọ̀ gbogbo àwọn ọmọ Bẹnjamini wá jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mejidinlọgbọn (928). 9Joẹli ọmọ Sikiri ni alabojuto wọn, Juda ọmọ Hasenua ni igbákejì rẹ̀ ní ìlú náà. 10Àwọn alufaa ni: Jedaaya ọmọ Joiaribu ati Jakini; 11Seraaya, ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí ilé Ọlọrun, 12ati àwọn arakunrin wọn tí wọ́n jọ ṣe iṣẹ́ ilé náà, wọ́n jẹ́ ẹgbẹrin lé mejilelogun (822).
Adaya ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelalaya, ọmọ Amisi, ọmọ Sakaraya, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malikija, 13ati àwọn arakunrin rẹ̀, àwọn baálé baálé lápapọ̀ jẹ́ ojilerugba ó lé meji (242).
Amaṣisai, ọmọ Asareli, ọmọ Asai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Imeri, 14ati àwọn arakunrin rẹ̀. Alágbára ati akọni eniyan ni wọ́n, wọ́n jẹ́ mejidinlaadoje (128). Sabidieli ọmọ Hagedolimu ni alabojuto wọn. 15Àwọn ọmọ Lefi ni: Ṣemaaya, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Bunni.
16Ṣabetai ati Josabadi, láàrin àwọn olórí ọmọ Lefi, ni wọ́n ń bojútó àwọn iṣẹ́ òde ilé Ọlọrun.
17Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sabidi, ọmọ Asafu, ni olórí tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìdúpẹ́ ninu adura, ati Bakibukaya tí ó jẹ́ igbákejì ninu àwọn arakunrin rẹ̀, Abuda, ọmọ Ṣamua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni. 18Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní ìlú mímọ́ náà jẹ́ ọrinlerugba ó lé mẹrin (284). 19Àwọn aṣọ́nà ni, Akubu, Talimoni ati àwọn arakunrin wọn, àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ mejilelaadọsan-an (172).
20Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà ní àwọn ìlú Juda, kaluku sì ń gbé orí ilẹ̀ ìní rẹ̀. 21Ṣugbọn àwọn iranṣẹ tẹmpili ń gbé ilẹ̀ Ofeli, Siha ati Giṣipa sì ni olórí wọn.
22Usi ni alabojuto àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu. Usi yìí jẹ́ ọmọ Bani, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mika, lára àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin. Òun ni olùdarí ìsìn ninu ilé Ọlọrun. 23Ọba ti fi àṣẹ lélẹ̀ nípa iṣẹ́ àwọn akọrin, ètò sì wà fún ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa fún wọn lojoojumọ.
24Petahaya ọmọ Meṣesabeli, lára àwọn ọmọ Sera, ọmọ Juda, ni aṣojú ọba nípa gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli.
Àwọn Tí Wọn Ń Gbé Àwọn Ìlú Kéékèèké ati Àwọn Ìlú Ńlá
25Ọ̀rọ̀ lórí àwọn ìletò ati àwọn pápá oko wọn, àwọn ará Juda kan ń gbé Kiriati Ariba ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, àwọn mìíràn sì ń gbé Diboni ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ati ní Jekabuseeli ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, 26ati ní Jeṣua, ati ní Molada, ati ní Betipeleti, 27ní Hasariṣuali ati ní Beeriṣeba, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, 28ní Sikilagi ati ní Mekona ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, 29ní Enrimoni, ní Sora, ati ní Jarimutu, 30ní Sanoa, ati Adulamu, ati àwọn ìletò àyíká wọn, ní Lakiṣi ati àwọn ìgbèríko rẹ̀, ati ní Aseka ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀. Wọ́n pàgọ́ láti Beeriṣeba títí dé àfonífojì Hinomu.
31Àwọn eniyan Bẹnjamini náà ń gbé Geba lọ sókè, títí dé Mikimaṣi, Aija, Bẹtẹli, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, 32ní Anatoti, 33Nobu, Ananaya ati Hasori, ní Rama ati Gitaimu, 34ní Hadidi, Seboimu, ati Nebalati, 35ní Lodi, ati Ono, àfonífojì àwọn oníṣọ̀nà. 36A sì pa àwọn ìpínlẹ̀ àwọn ọmọ Lefi kan ní Juda pọ̀ mọ́ ti àwọn ọmọ Bẹnjamini.
Currently Selected:
NEHEMAYA 11: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010