NEHEMAYA 2
2
Nehemaya lọ sí Jerusalẹmu
1Ní oṣù Nisani, ní ogún ọdún tí Atasasesi ọba gorí oyè, mo gbé ọtí waini tí ó wà níwájú rẹ̀ fún un. N kò fajúro níwájú rẹ̀ rí. 2Nítorí náà, ọba bi mí léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi fajúro? Ó dájú pé kò rẹ̀ ọ́. Ó níláti jẹ́ pé ọkàn rẹ bàjẹ́ ni.” 3Ẹ̀rù bà mí pupọ.
Mo bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ẹ̀mí ọba gùn! Báwo ni ojú mi kò ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí ibojì àwọn baba mi wà, ti di ahoro, tí iná sì ti jó àwọn ẹnubodè rẹ̀?” #2A. Ọba 25:8-10; 2Kron 36:19; Jer 52:12-14
4Ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Kí ni ohun tí o wá fẹ́?”
Nítorí náà, mo gbadura sí Ọlọrun ọ̀run. 5Mo bá sọ fún ọba pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn, tí èmi iranṣẹ rẹ bá sì rí ojurere rẹ, rán mi lọ sí Juda, ní ìlú tí ibojì àwọn baba mi wà, kí n lọ tún ìlú náà kọ́.”
6Ayaba wà ní ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba, ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “O óo lò tó ọjọ́ mélòó lọ́hùn-ún? Ìgbà wo ni o sì fẹ́ pada?” Inú ọba dùn láti rán mi lọ, èmi náà sì dá ìgbà fún un.
7Mo fún ọba lésì pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn bẹ́ẹ̀, kí kabiyesi kọ̀wé lé mi lọ́wọ́ kí n lọ fún àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò, kí wọ́n lè jẹ́ kí n rékọjá lọ sí Juda, 8kí ó kọ ìwé sí Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, kí ó fún mi ní igi kí n fi ṣe odi ẹnu ọ̀nà tẹmpili, ati ti odi ìlú, ati èyí tí n óo fi kọ́ ilé tí n óo máa gbé.” Ọba ṣe gbogbo ohun tí mo bèèrè fún mi, nítorí pé Ọlọrun lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi.
9Mo bá tọ àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò lọ mo fún wọn ní lẹta tí ọba kọ. Ọba rán àwọn olórí ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tẹ̀lé mi. 10Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ará Horoni ati Tobaya iranṣẹ ọba, ará Amoni gbọ́, inú bí wọn pé ẹnìkan lè máa wá alaafia àwọn ọmọ Israẹli.
11Mo bá wá sí Jerusalẹmu mo sì wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. 12Mo gbéra ní alẹ́ èmi ati àwọn eniyan díẹ̀, ṣugbọn n kò sọ ohun tí Ọlọrun mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe ní Jerusalẹmu fún ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹranko kankan pẹlu mi àfi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn. 13Mo gbéra lóru, mo gba Ẹnubodè Àfonífojì. Mo jáde sí kànga Diragoni, mo gba ibẹ̀ lọ sí Ẹnubodè Ààtàn. Bí mo ti ń lọ, mò ń wo àwọn ògiri Jerusalẹmu tí wọ́n ti wó lulẹ̀ ati àwọn ẹnu ọ̀nà tí wọ́n ti jó níná. 14Lẹ́yìn náà, mo lọ sí Ẹnubodè Orísun ati ibi Adágún ọba, ṣugbọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn kò rí ọ̀nà kọjá. 15Lóru náà ni mo gba àfonífojì Kidironi gòkè lọ, mo sì ṣe àyẹ̀wò odi náà yíká, lẹ́yìn náà, mo pẹ̀yìndà mo sì gba Ẹnubodè Àfonífojì wọlé pada. 16Àwọn ìjòyè náà kò sì mọ ibi tí mo lọ tabi ohun tí mo lọ ṣe, n kò sì tíì sọ nǹkankan fún àwọn Juu, ẹlẹgbẹ́ mi: àwọn alufaa, ati àwọn ọlọ́lá, tabi àwọn ìjòyè ati àwọn yòókù tí wọn yóo jọ ṣe iṣẹ́ náà.
17Lẹ́yìn náà, mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí irú ìyọnu tí ó dé bá wa! Ẹ wò ó bí Jerusalẹmu ṣe parun tí àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì jóná. Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á kọ́ odi Jerusalẹmu, kí á lè fi òpin sí ìtìjú tí ó dé bá wa.” 18Mo sọ fún wọn nípa bí Ọlọrun ṣe lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi ati nípa ọ̀rọ̀ tí ọba bá mi sọ.
Wọ́n sì dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á múra kí á sì kọ́ ọ.” Wọ́n sì gbáradì láti ṣe iṣẹ́ rere náà.
19Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ará Horoni ati Tobaya iranṣẹ ọba, ará Amoni ati Geṣemu ará Arabia gbọ́, wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń pẹ̀gàn wa pé, “Kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ̀ ń dìtẹ̀ mọ́ ọba ni?”
20Mo fún wọn lésì pé, “Ọlọrun ọ̀run yóo mú wa ṣe àṣeyọrí, àwa iranṣẹ rẹ̀ yóo múra, a óo sì mọ odi náà, ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò ní ìpín, tabi ẹ̀tọ́, tabi ìrántí ní Jerusalẹmu.”
Currently Selected:
NEHEMAYA 2: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010