ÌWÉ ÒWE 16
16
1Èrò ọkàn ni ti eniyan
ṣugbọn OLUWA ló ni ìdáhùn.
2Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó mọ́ lójú ara rẹ̀,
ṣugbọn OLUWA ló rí ọkàn.
3Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́,
èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere.
4OLUWA a máa jẹ́ kí ohun gbogbo yọrí sí bí ó bá ti fẹ́,
ó dá eniyan burúkú fún ọjọ́ ìyọnu.
5OLUWA kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ agbéraga,
dájúdájú kò ní lọ láìjìyà.
6Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀,#Tob 12:9
ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò.
7Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn,
a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia.
8Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo,#Tob 12:8
sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ.
9Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀,
ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni.
10Pẹlu ìmísí Ọlọrun ni ọba fi ń sọ̀rọ̀,
ìdájọ́ aiṣododo kò gbọdọ̀ ti ẹnu rẹ̀ jáde.
11Ti OLUWA ni òṣùnwọ̀n pípé,
iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí à ń wọ̀n.
12Àwọn ọba kórìíra ibi ṣíṣe,
nítorí nípa òdodo ni a fìdí ìjọba múlẹ̀.
13Inú ọba a máa dùn sí olódodo,
ọba sì máa ń fẹ́ràn àwọn tí ń sọ òtítọ́.
14Iranṣẹ ikú ni ibinu ọba,
ọlọ́gbọ́n eniyan níí tù ú lójú.
15Ìyè wà ninu ojurere ọba,
ojurere rẹ̀ sì dàbí ṣíṣú òjò ní àkókò òjò àkọ́rọ̀.
16Ó sàn kí eniyan ní òye ju kí ó ní wúrà lọ,
ó sì sàn kí eniyan yan ìmọ̀ ju kí ó yan fadaka lọ.
17Olóòótọ́ kì í tọ ọ̀nà ibi,
ẹni tí ń ṣọ́ra, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń pamọ́.
18Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun,
agídí ní ń ṣáájú ìṣubú.
19Ó sàn kí eniyan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹlu àwọn talaka
ju kí ó bá agbéraga pín ìkógun lọ.
20Yóo dára fún ẹni tí ó bá ń gbọ́ràn,
ẹni tí ó bá sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ní ayọ̀.
21Àwọn tí wọ́n gbọ́n ni à ń pè ní amòye,
ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára a máa yíni lọ́kàn pada.
22Orísun ìyè ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tí wọn ní i,
agọ̀ sì jẹ́ ìjìyà fún àwọn òmùgọ̀.
23Ọgbọ́n inú níí mú kí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tọ̀nà,
ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa yíni lọ́kàn pada.
24Ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára dàbí afárá oyin,
a máa mú inú ẹni dùn, a sì máa mú ara ẹni yá.
25Ọ̀nà kan wà tí ó tọ́ lójú eniyan,#Owe 14:12
ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.
26Ebi níí mú kí òṣìṣẹ́ múra síṣẹ́,
ohun tí a óo jẹ ní ń lé ni kiri.
27Eniyan lásán a máa pète ibi,
ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni.
28Ṣòkèṣodò a máa dá ìjà sílẹ̀,#Sir 28:13-26
ọ̀rọ̀ àhesọ a máa tú ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.
29Ìkà eniyan tan aládùúgbò rẹ̀,
ó darí rẹ̀ lọ sọ́nà tí kò tọ́.
30Ẹni tí ó bá ń ṣẹ́jú sí ni, ète ibi ló fẹ́ pa,
ẹni tí ó bá ń fúnnu pọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ burúkú ni yóo sọ jáde.
31Adé ògo ni ewú orí,
nípa ìgbé ayé òdodo ni a fi lè ní i.
32Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ,
ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ.
33À máa ṣẹ́ gègé kí á lè mọ ìdí ọ̀ràn,
ṣugbọn OLUWA nìkan ló lè pinnu ohunkohun.
Currently Selected:
ÌWÉ ÒWE 16: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010