YouVersion Logo
Search Icon

ÌWÉ ÒWE 22

22
1Orúkọ rere dára láti yàn ju ọrọ̀ pupọ lọ,
kí á rí ojurere sì dára ju kí á ní fadaka ati wúrà lọ.
2Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé,
OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.
3Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́,
ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà,
ó sì kó sinu ìyọnu.
4Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè.
5Ẹ̀gún ati tàkúté ń bẹ lọ́nà àwọn ẹlẹ́tàn,
ẹni tí ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóo jìnnà sí wọn.
6Tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn,#Sir 6:18
bí ó bá dàgbà tán, kò ní kúrò ninu rẹ̀.
7Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí,
ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó.
8Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú,
pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun.
9Olójú àánú yóo rí ibukun gbà,
nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀.
10Lé pẹ̀gànpẹ̀gàn síta, ìjà yóo rọlẹ̀,
asọ̀ ati èébú yóo sì dópin.
11Ẹni tí ó fẹ́ ọkàn mímọ́,
tí ó sì ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu yóo bá ọba ṣọ̀rẹ́.
12Ojú OLUWA ń ṣọ́ ìmọ̀ tòótọ́,
ṣugbọn a máa yí ọ̀rọ̀ àwọn alaigbagbọ po.
13Ọ̀lẹ a máa sọ pé, “Kinniun wà níta!
Yóo pa mí jẹ lójú pópó!”
14Ẹnu alágbèrè obinrin dàbí kòtò ńlá,
ẹni tí OLUWA bá ń bínú sí níí já sinu rẹ̀.
15Ìwà agídí dì sí ọkàn ọmọde,
ṣugbọn pàṣán ìbáwí níí lé e jáde.
16Ẹni tí ó ni talaka lára kí ó lè ní ohun ìní pupọ,
tabi tí ó ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ yóo pada di talaka.
Ọgbọ̀n Gbolohun tí Ọlọ́gbọ́n Sọ
17Tẹ́tí rẹ sílẹ̀ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n,
kí o sì fi ọkàn sí ẹ̀kọ́ mi,
18nítorí yóo dára tí o bá pa wọ́n mọ́ lọ́kàn rẹ,
tí o sì ń fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ jáde.
19Ìwọ ni mo sọ wọ́n di mímọ̀ fún lónìí, àní ìwọ,
kí ó le jẹ́ pé OLUWA ni o gbẹ́kẹ̀lé.
20Ṣebí mo ti kọ ọgbọ̀n àkọsílẹ̀ fún ọ lórí ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n,
21láti fi ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì jẹ́ òtítọ́ hàn ọ́,
kí o lè fi ìdáhùn pípé fún ẹni tí ó rán ọ.
-1-
22Má ja talaka lólè, nítorí pé ó jẹ́ talaka,
má sì dájọ́ èké fún ẹni tí ara ń ni.
23Nítorí OLUWA yóo gbèjà wọn,
yóo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń jẹ wọ́n níyà.
-2-
24Má bá oníbìínú eniyan kẹ́gbẹ́,
má sì bá onínúfùfù da nǹkan pọ̀.
25Kí o má baà kọ́ ìwà rẹ̀,
kí o sì fi tàkúté mú ara rẹ.
-3-
26Má bá wọn ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tó fẹ́ yá owó,
má bá wọn ṣe onídùúró fún onígbèsè.
27Tí o kò bá rí owó san fún olówó,
olówó lè pé kí wọn gba ibùsùn rẹ.
-4-
28Má hú ohun tí àwọn baba ńlá rẹ rì mọ́lẹ̀,
tí wọ́n fi pa ààlà kúrò.
-5-
29Ṣe akiyesi ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ rẹ̀,
àwọn ọba ni yóo máa bá ṣiṣẹ́,
kì í ṣe àwọn eniyan lásán.
-6-

Currently Selected:

ÌWÉ ÒWE 22: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in