YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 10

10
Adura Olùpọ́njú
1Kí ló dé tí o fi jìnnà réré, OLUWA,
tí o sì fara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?
2Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní;
jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ.
3Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀,
Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA.
4Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀,
kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀.
5Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un.
Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ;
ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.
6Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú,
ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro.
7Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀;
ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.#Rom 3:14
8Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé,
níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀;
ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa.
9Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba;
ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀;
ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ.
10Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba,
ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú.
11Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé,
OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.”
12Dìde, OLUWA; Ọlọrun, wá nǹkankan ṣe sí i;
má sì gbàgbé àwọn tí a nilára.
13Kí ló dé tí eniyan burúkú fi ń kẹ́gàn Ọlọrun,
tí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò ní bi mí?”
14Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan,
nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà,
kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san;
nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé,
ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba.
15Ṣẹ́ eniyan burúkú ati aṣebi lápá,
tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú rẹ̀,
má sì jẹ́ kí ọ̀kan ninu wọn farasin.
16OLUWA ni ọba lae ati laelae.
Àwọn orílẹ̀-èdè yóo pòórá lórí ilẹ̀ rẹ.
17OLUWA, o óo gbọ́ igbe àwọn tí a nilára;
o óo mú wọn lọ́kàn le,
o óo sì dẹ etí sílẹ̀ sí igbe wọn
18kí o lè ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn aláìníbaba
ati àwọn ẹni tí à ń pọ́n lójú,
kí ọmọ eniyan, erùpẹ̀ lásánlàsàn, má lè dẹ́rù bani mọ́.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 10: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Videos for ORIN DAFIDI 10