ORIN DAFIDI 100
100
Orin Ìyìn
1Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé.
2Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA.
Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀.
3Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun,
òun ló dá wa, òun ló ni wá;
àwa ni eniyan rẹ̀,
àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀.
4Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́,
kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn.
Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,
kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀.
5Nítorí OLUWA ṣeun;
ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae,
òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.#1Kron 16:34; 2Kron 5:13; 7:3; Ẹsr 3:11; O. Daf 106:1; 107:1; 118:1; 136:1; Jer 33:11
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 100: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010