ORIN DAFIDI 108
108
Adura Ìrànlọ́wọ́ láti Borí Ọ̀tá
1Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun
ọkàn mi dúró ṣinṣin.
N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.
Jí, ìwọ ọkàn mi!
2Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu!
Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu,
3OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan,
n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
4Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,
òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.
5Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun,
kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé.
6Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,
fi ọwọ́ agbára rẹ gbà wá, kí o sì dá mi lóhùn.
7Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,
ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,
n óo sì pín àfonífojì Sukotu.
8Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase.
Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,
Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
9Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé,
n óo sì hó ìhó ìṣẹ́gun lórí Filistia.”
10Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?
Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu?
11Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?
Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa lọ sójú ogun mọ́.
12Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,
nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan.
13Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a óo ṣe akin;
nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 108: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010