ORIN DAFIDI 12
12
Adura Ìrànlọ́wọ́
1Gbani, OLUWA; nítorí àwọn olódodo kò sí mọ́;
àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàrin àwọn ọmọ eniyan.
2Olukuluku ń purọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀;
ọ̀rọ̀ ìpọ́nni èké ati ẹ̀tàn ni wọ́n ń bá ara wọn sọ.
3Kí OLUWA pa gbogbo àwọn tí ń fi èké pọ́nni run, ati àwọn tí ń fọ́nnu,
4àwọn tí ń wí pé,
“Ẹnu wa yìí ni a óo fi ṣẹgun,
àwa la ni ẹnu wa; ta ni ó lè mú wa?”
5OLUWA wí pé, “Nítorí ìnira àwọn aláìṣẹ̀,
ati nítorí ìkérora àwọn tí à ń pọ́n lójú,
n óo dìde nisinsinyii,
n óo sì dáàbò bò wọ́n bí ọkàn wọn ti ń fẹ́.”
6Ìlérí tó dájú ni ìlérí OLUWA,
ó dàbí fadaka tí a yọ́ ninu iná ìléru amọ̀,
tí a dà ninu iná nígbà meje.
7Dáàbò bò wá, OLUWA, pa wá mọ́ laelae
kúrò lọ́wọ́ irú àwọn eniyan báwọ̀nyí.
8Àwọn eniyan burúkú ń yan kiri,
níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ ibi.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 12: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010