YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 14

14
Èrè Òmùgọ̀
1Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò sí.”
Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere.
2OLUWA bojú wo ilẹ̀, láti ọ̀run wá,
ó wo àwọn ọmọ eniyan,
láti mọ̀ bí àwọn kan bá wà tí wọ́n gbọ́n,
tí wọn ń wá Ọlọrun.
3Gbogbo wọn ti ṣìnà,
gbogbo wọn pátá ni wọ́n sì ti bàjẹ́;
kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,
kò sí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo.#Rom 3:10-12
4Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?
Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,
àwọn tí kì í ké pe OLUWA.
5Níbẹ̀ ni a óo ti dẹ́rù bà wọ́n gidigidi,
nítorí Ọlọrun ń bẹ pẹlu àwọn olódodo.
6Ẹ̀yin ń fẹ́ da ètò aláìní rú,
ṣugbọn OLUWA ni ààbò rẹ̀.
7Ìbá ti dára tó kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá!
Nígbà tí OLUWA bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada,
Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 14: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Videos for ORIN DAFIDI 14