ORIN DAFIDI 22
22
Igbe Ìrora ati Orin Ìyìn
1Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀,
tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi,
kí o sì ràn mí lọ́wọ́?
2Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án,
ṣugbọn o ò dáhùn;
mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́.
3Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́,
o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́.
4Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé;
wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n.
5Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n;
ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n.#Mat 27:46; Mak 15:34
6Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan;
ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.
7Gbogbo àwọn tí ó rí mi ní ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́;
wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi;
wọ́n sì ń mi orí pé,
8“Ṣebí OLUWA ni ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́;
kí OLUWA ọ̀hún yọ ọ́, kí ó sì gbà á là,
ṣebí inú rẹ̀ dùn sí i!”#Mat 27:39; Mak 15:29; Luk 23:35 #Mat 27:43
9Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi;
ìwọ ni o sì mú mi wà láìséwu nígbà tí mo wà ní ọmọ ọmú.
10Ìwọ ni wọ́n bí mi lé lọ́wọ́;
ìwọ ni Ọlọrun mi
láti ìgbà tí ìyá mi ti bí mi.
11Má jìnnà sí mi,
nítorí pé ìyọnu wà nítòsí,
kò sì sí ẹni tí yóo ràn mí lọ́wọ́.
12Àwọn ọ̀tá yí mi ká bí akọ mààlúù,
wọ́n yí mi ká bí akọ mààlúù Baṣani tó lágbára.
13Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi bí kinniun,
bí kinniun tí ń dọdẹ kiri tí ń bú ramúramù.
14Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi,
gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé;
ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́.
15Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì,
ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu;
o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú.
16Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá;
àwọn aṣebi dòòyì ká mi;
wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya.#22:16 tabi “fà ya bíi ti kinniun.”
17Mo lè ka gbogbo egungun mi
wọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí.
18Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,
wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi.#Mat 27:35; Mak 15:24; Luk 23:34; Joh 19:24
19Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, má jìnnà sí mi!
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, ṣe gírí láti ràn mí lọ́wọ́!
20Gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ idà,
gbà mí lọ́wọ́ àwọn ajá!
21Já mi gbà kúrò lẹ́nu kinniun nnì
gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwo ẹhànnà mààlúù!
22N óo ròyìn orúkọ rẹ fún àwọn ará mi;
láàrin àwùjọ àwọn eniyan ni n óo sì ti máa yìn ọ́:
23Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ máa yìn ín!
Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ fi ògo fún un,
ẹ dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
24Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́;
kò sì ṣá wọn tì,
bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn,
ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é.
25Ìwọ ni n óo máa yìn láàrin àwùjọ àwọn eniyan;
n óo san ẹ̀jẹ́ mi láàrin àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA.
26Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó;
àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín!
Kí ẹ̀mí wọn ó gùn!
27Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWA
wọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀;
gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdè
ni yóo sì júbà níwájú rẹ̀.
28Nítorí OLUWA ló ni ìjọba,
òun ní ń jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.
29Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀;
gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọ
ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀,
àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè.
30Ìran tí ń bọ̀ yóo máa sìn ín;
àwọn eniyan yóo máa sọ̀rọ̀ OLUWA fún àwọn ìran tí ń bọ̀.
31Wọn óo máa kéde ìgbàlà rẹ̀ fún àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,
pé, “OLUWA ló ṣe é.”
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 22: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010