ORIN DAFIDI 87
87
Ìyìn Sioni
1Ní orí òkè mímọ́ ni ìlú tí OLUWA tẹ̀dó wà.
2OLUWA fẹ́ràn ẹnubodè Sioni ju gbogbo ìlú
yòókù lọ ní ilẹ̀ Jakọbu.
3Ọpọlọpọ nǹkan tó lógo ni a sọ nípa rẹ,
ìwọ ìlú Ọlọrun.
4Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi,
n óo dárúkọ Ijipti#87:4 Rahabu ni ó wà ninu Bibeli Heberu. Orúkọ yìí jẹ́ àdàpè fún ilẹ̀ Ijipti... Wo Aisaya 30:7. ati Babiloni,
Filistia ati Tire, ati Etiopia.
Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.”
5A óo wí nípa Sioni pé,
“Ibẹ̀ ni a ti bí eléyìí ati onítọ̀hún,”
nítorí pé Ọ̀gá Ògo yóo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
6OLUWA yóo ṣírò rẹ̀ mọ́ wọn
nígbà tí ó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,
“Ní Sioni ni a ti bí eléyìí.”
7Àwọn akọrin ati àwọn afunfèrè ati àwọn tí ń jó yóo máa sọ pé,
“Ìwọ, Sioni, ni orísun gbogbo ire wa.”
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 87: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010