I. Kor 3
3
Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun
1ARÁ, emi kò si le ba nyin sọ̀rọ bi awọn ti iṣe ti Ẹmí, bikoṣe bi awọn ti iṣe ti ara, ani bi awọn ọmọ-ọwọ ninu Kristi.
2Wàra ni mo ti fi bọ́ nyin, kì iṣe onjẹ: nitori ẹ kò iti le gbà a, nisisiyi na ẹ kò iti le gbà a.
3Nitori ẹnyin jẹ ti ara sibẹ: nitori niwọnbi ilara ati ìja ati ìyapa ba wà larin nyin, ẹnyin kò ha jẹ ti ara ẹ kò ha si nrìn gẹgẹ bi enia?
4Nitori nigbati ẹnikan nwipe, Emi ni ti Paulu; ti ẹlomiran si nwipe, Emi ni ti Apollo; ẹnyin kò ha iṣe enia bi?
5Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbagbọ́, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun.
6Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wá.
7Njẹ kì iṣe ẹniti o ngbìn nkankan, bẹ̃ni kì iṣe ẹniti mbomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o nmu ibisi wá.
8Njẹ ẹniti ngbìn, ati ẹniti mbomirin, ọkan ni nwọn jasi: olukuluku yio si gba ère tirẹ̀ gẹgẹ bi iṣẹ tirẹ̀.
9Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbà Ọlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin.
10Gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, bi ọlọ́gbọn ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ipilẹ sọlẹ, ẹlomiran si nmọ le e. Ṣugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e.
11Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi.
12Njẹ bi ẹnikẹni ba mọ wura, fadaka, okuta iyebiye, igi, koriko, akekù koriko le ori ipilẹ yi;
13Iṣẹ́ olukuluku enia yio hàn. Nitori ọjọ na yio fi i hàn, nitoripe ninu iná li a o fi i hàn; iná na yio si dán iṣẹ olukuluku wò irú eyiti iṣe.
14Bi iṣẹ ẹnikẹni ti o ti ṣe lori rẹ̀ ba duro, on ó gbà ère.
15Bi iṣẹ ẹnikẹni ba jóna, on a pàdanù: ṣugbọn on tikararẹ̀ li a o gbalà, ṣugbọn bi ẹni nlà iná kọja.
16Ẹnyin kò mọ̀ pe tẹmpili Ọlọrun li ẹnyin iṣe, ati pe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin?
17Bi ẹnikan bá ba tẹmpili Ọlọrun jẹ, on ni Ọlọrun yio parun; nitoripe mimọ́ ni tẹmpili Ọlọrun, eyiti ẹnyin jẹ.
18Ki ẹnikẹni máṣe tàn ara rẹ̀ jẹ. Bi ẹnikẹni ninu nyin laiye yi ba rò pe on gbọ́n, ẹ jẹ ki o di aṣiwere, ki o le ba gbọ́n.
19Nitori ọgbọ́n aiye yi wèrè ni lọdọ Ọlọrun. Nitori a ti kọ ọ pe, Ẹniti o mu awọn ọlọgbọ́n ninu arekereke wọn.
20A si tún kọ ọ pe, Oluwa mọ̀ ero ironu awọn ọlọgbọ́n pe, asan ni nwọn.
21Nitorina ki ẹnikẹni máṣe ṣogo ninu enia. Nitori tinyin li ohun gbogbo,
22Iba ṣe Paulu, tabi Apollo, tabi Kefa, tabi aiye, tabi ìye, tabi ikú, tabi ohun isisiyi, tabi ohun igba ti mbọ̀; tinyin ni gbogbo wọn;
23Ẹnyin si ni ti Kristi; Kristi si ni ti Ọlọrun.
Currently Selected:
I. Kor 3: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.