YouVersion Logo
Search Icon

I. Sam 11

11
Saulu Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni
1NAHAṢI ara Ammoni si goke wá, o si do ti Jabeṣi-Gileadi: gbogbo ọkunrin Jabeṣi si wi fun Nahaṣi, pe, Ba wa da majẹmu, awa o si ma sìn ọ.
2Nahaṣi ara Ammoni na si da wọn lohùn pe, Nipa bayi li emi o fi ba nyin da majẹmu, nipa yiyọ gbogbo oju ọtun nyin kuro, emi o si fi i ṣe ẹlẹyà li oju gbogbo Israeli.
3Awọn agba Jabeṣi si wi fun u pe, Fun wa li ayè ni ijọ meje, awa o si ran onṣẹ si gbogbo agbegbe Israeli bi ko ba si ẹniti yio gbà wa, awa o si jade tọ ọ wá.
4Awọn iranṣẹ na si wá si Gibea ti Saulu, nwọn rohìn na li eti awọn enia: gbogbo enia na si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun.
5Si kiye si i, Saulu bọ̀ wá ile lẹhin ọwọ́ malu lati papa wá; Saulu si wipe, Ẽṣe awọn enia ti nwọn fi nsọkun? Nwọn si sọ ọ̀rọ awọn ọkunrin Jabeṣi fun u.
6Ẹmi Ọlọrun si bà le Saulu nigbati o gbọ́ ọ̀rọ wọnni, inu rẹ̀ si ru pipọ.
7O si mu malu meji, o rẹ́ wọn wẹwẹ, o si ran wọn si gbogbo agbegbe Israeli nipa ọwọ́ awọn onṣẹ na, wipe, Ẹnikẹni ti o wu ki o ṣe ti ko ba tọ Saulu ati Samueli lẹhin, bẹ̃ gẹgẹ li a o ṣe si malu rẹ̀. Ibẹ̀ru Oluwa si mu awọn enia na, nwọn si jade bi enia kanṣoṣo.
8O si kà wọn ni Beseki, awọn ọmọ Israeli si jẹ ọkẹ mẹ̃dogun enia; awọn ọkunrin Juda si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun.
9Nwọn si wi fun awọn iranṣẹ na ti o ti wá pe, Bayi ni ki ẹ wi fun awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi; Li ọla, lakoko igbati õrùn ba mu, ẹnyin o ni iranlọwọ. Awọn onṣẹ na wá, nwọn rò o fun awọn ọkunrin Jabeṣi; nwọn si yọ̀.
10Nitorina awọn ọkunrin Jabeṣi wi pe, lọla awa o jade tọ nyin wá, ẹnyin o si fi wa, ṣe bi gbogbo eyi ti o tọ loju nyin.
11O si ri bẹ̃ lọla na, Saulu si ya awọn enia na si ẹgbẹ mẹta; nwọn si wá ãrin ogun na ni iṣọ owurọ̀, nwọn si pa awọn ara Ammoni titi o fi di igba imoru ọjọ: o si ṣe awọn iyoku fọnka, tobẹ̃ ti meji wọn ko kù ni ibi kan.
12Awọn enia na si wi fun Samueli, pe, Tani wipe, Saulu yio ha jọba lori wa? mu awọn ọkunrin na wá, a o si pa wọn.
13Saulu si wi pe, a kì yio pa ẹnikẹni loni yi; nitoripe loni li Oluwa ṣiṣẹ igbala ni Israeli.
14Nigbana ni Samueli wi fun awọn enia na pe, Wá, ki a lọ si Gilgali, ki a le tun ijọba na ṣe nibẹ.
15Gbogbo enia na si lọ si Gilgali; nibẹ ni nwọn gbe fi Saulu jọba niwaju Oluwa ni Gilgali: nibẹ ni nwọn gbe ru ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa; nibẹ ni Saulu ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli si yọ ayọ̀ nlanla.

Currently Selected:

I. Sam 11: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in