YouVersion Logo
Search Icon

I. Sam 18

18
1O si ṣe, nigbati o ba Saulu sọ̀rọ tan, ọkàn Jonatani si fà mọ ọkàn Dafidi, Jonatani si fẹ ẹ bi ontikararẹ̀.
2Saulu si mu u sọdọ lọjọ na, ko si jẹ ki o lọ sọdọ baba rẹ̀ mọ.
3Jonatani on Dafidi si ba ara wọn mulẹ; nitoripe o fẹ ẹ gẹgẹ bi o ti fẹ ọkàn ara rẹ̀.
4Jonatani si bọ aṣọ ileke ti o wà li ara rẹ̀ o si fi i fun Dafidi, ati ihamọra rẹ̀, titi de idà rẹ̀, ọrun rẹ̀, ati amure rẹ̀.
5Dafidi a si ma lọ si ibikibi ti Saulu rán a, a ma huwa ọlọgbọ́n: Saulu si fi i jẹ olori ogun, o si dara loju gbogbo awọn enia, ati pẹlupẹlu loju awọn iranṣẹ Saulu.
Saulu bẹ̀rẹ̀ sí jowú Dafidi
6O si ṣe, bi nwọn ti de, nigbati Dafidi ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, awọn obinrin si ti gbogbo ilu Israeli jade wá, nwọn nkọrin nwọn si njo lati wá ipade Saulu ọba, ti awọn ti ilù, ati ayọ̀, ati duru.
7Awọn obinrin si ndá, nwọn si ngbe orin bi nwọn ti nṣire, nwọn si nwipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbarun tirẹ̀.
8Saulu si binu gidigidi, ọ̀rọ na si buru loju rẹ̀ o si wipe, Nwọn fi ẹgbẹgbarun fun Dafidi, nwọn si fi ẹgbẹgbẹrun fun mi, kili o si kù fun u bikoṣe ijọba.
9Saulu si nfi oju ilara wo Dafidi lati ọjọ na lọ.
10O si ṣe ni ijọ keji, ti ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá si ba le Saulu, on si sọtẹlẹ li arin ile; Dafidi si fi ọwọ́ rẹ̀ ṣire lara duru bi igba atẹhinwa; ẹṣín kan mbẹ lọwọ Saulu.
11Saulu si sọ ẹṣín ti o wà lọwọ rẹ̀ na; o si wipe, Emi o pa Dafidi li apa mọ́ ogiri. Dafidi si yẹra kuro niwaju rẹ lẹ̃meji.
12Saulu si bẹ̀ru Dafidi, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa kọ̀ Saulu.
13Nitorina Saulu si mu u kuro lọdọ rẹ̀, o si fi i jẹ olori ogun ẹgbẹrun kan, o si nlọ, o si mbọ̀ niwaju awọn enia na.
14Dafidi si ṣe ọlọgbọ́n ni gbogbo iṣe rẹ̀; Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
15Nigbati Saulu ri pe, o nhuwa ọgbọ́n gidigidi, o si mbẹ̀ru rẹ̀.
16Gbogbo Israeli ati Juda si fẹ Dafidi, nitoripe a ma lọ a si ma bọ̀ niwaju wọn.
Dafidi fẹ́ Ọmọbinrin Saulu
17Saulu si wi fun Dafidi pe, Wo Merabu ọmọbinrin mi, eyi agbà, on li emi o fi fun ọ li aya: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alagbara fun mi, ki o si ma ja ija Oluwa. Nitoriti Saulu ti wi bayi pe, Màṣe jẹ ki ọwọ́ mi ki o wà li ara rẹ̀; ṣugbọn jẹ ki ọwọ́ awọn Filistini ki o wà li ara rẹ̀.
18Dafidi si wi fun Saulu pe, Tali emi, ati ki li ẹmi mi, tabi idile baba mi ni Israeli, ti emi o fi wa di ana ọba.
19O si ṣe, li akoko ti a ba fi Merabu ọmọbinrin Saulu fun Dafidi, li a si fi i fun Adrieli ara Meholati li aya.
20Mikali ọmọbinrin Saulu si fẹran Dafidi, nwọn si wi fun Saulu: nkan na si tọ li oju rẹ̀.
21Saulu si wipe, Emi o fi i fun u, yio si jẹ idẹkùn fun u, ọwọ́ awọn Filistini yio si wà li ara rẹ̀. Saulu si wi fun Dafidi pe, Iwọ o wà di ana mi loni, ninu mejeji.
22Saulu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ lọ ba Dafidi sọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ pe, Kiyesi i, inu ọba dùn si ọ jọjọ, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ li o si fẹ ọ, njẹ nitorina jẹ ana ọba.
23Awọn iranṣẹ Saulu si sọ̀rọ wọnni li eti Dafidi. Dafidi si wipe, O ha ṣe nkan ti o fẹrẹ loju nyin lati jẹ ana ọba? Talaka li emi ati ẹni ti a kò kà si.
24Awọn iranṣẹ Saulu si wa irò fun u, pe, Ọrọ bayi ni Dafidi sọ.
25Saulu si wipe, Bayi li ẹnyin o sọ fun Dafidi, ọba kò sa fẹ ohun-ana kan bikoṣe ọgọrun ẹfa abẹ Filistini, ati lati gbẹsan lara awọn ọta ọba; ṣugbọn Saulu rò ikú Dafidi lati ọwọ́ awọn Filistini wá.
26Nigbati awọn iranṣẹ rẹ̀ si sọ̀rọ wọnyi fun Dafidi, ohun na si dara li oju Dafidi lati di ana ọba: ọjọ kò si iti pe.
27Dafidi si dide, o lọ, on ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, o si pa igba ọmọkunrin ninu awọn Filistini; Dafidi si mu ẹfa abẹ wọn wá, nwọn si kà wọn pe fun ọba, ki on ki o le jẹ ana ọba. Saulu si fi Mikali ọmọ rẹ obinrin fun u li aya.
28Saulu si ri o si mọ̀ pe, Oluwa wà pẹlu Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu si fẹ ẹ.
29Saulu si bẹ̀ru Dafidi siwaju ati siwaju: Saulu si wa di ọtá Dafidi titi.
30Awọn ọmọ-alade Filistini si jade lọ: o si ṣe, lẹhin igbati nwọn lọ, Dafidi si huwa ọlọgbọ́n ju gbogbo awọn iranṣẹ Saulu lọ; orukọ rẹ̀ si ni iyìn jọjọ.

Currently Selected:

I. Sam 18: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in