I. Sam 26
26
Dafidi dá ẹ̀mí Saulu sí lẹẹkeji
1AWỌN ara Sifi si tọ̀ Saulu wá si Gibea, nwọn wipe, Ṣe Dafidi fi ara rẹ̀ pamọ nibi oke Hakila, eyi ti o wà niwaju Jeṣimoni?
2Saulu si dide o si sọkalẹ lọ si ijù Sifi, ẹgbẹ̀dogun àṣayàn enia ni Israeli si pẹlu rẹ̀ lati wá Dafidi ni iju Sifi.
3Saulu si pagọ rẹ̀ ni ibi oke Hakila ti o wà niwaju Jeṣimoni li oju ọ̀na. Dafidi si joko ni ibi iju na, o si ri pe Saulu ntẹle on ni iju na.
4Dafidi si ran amí jade, o si mọ̀ nitõtọ pe Saulu mbọ̀.
5Dafidi si dide, o si wá si ibi ti Saulu pagọ si: Dafidi si ri ibi ti Saulu gbe dubulẹ si, ati Abneri ọmọ Neri, olori ogun rẹ̀: Saulu si dubulẹ larin awọn kẹ̀kẹ́, awọn enia na si pagọ wọn yi i ka.
6Dafidi si dahun, o si wi fun Ahimeleki ọkan ninu awọn ọmọ Heti, ati fun Abiṣai ọmọ Seruia arákùnrin Joabu, pe, Tani o ba mi sọkalẹ lọ sọdọ Saulu ni ibudo? Abiṣai si wipe, emi o ba ọ sọkalẹ lọ.
7Bẹ̃ni Dafidi ati Abiṣai si tọ awọn enia na wá li oru: si wõ, Saulu dubulẹ o si nsun larin kẹkẹ, a si fi ọ̀kọ rẹ̀ gunlẹ ni ibi timtim rẹ̀: Abneri ati awọn enia na si dubulẹ yi i ka.
8Abiṣai si wi fun Dafidi pe, Ọlọrun ti fi ọta rẹ le ọ lọwọ loni: njẹ, emi bẹ ọ, sa jẹ ki emi ki o fi ọ̀kọ gun u mọlẹ lẹ̃kan, emi ki yio gun u lẹ̃meji.
9Dafidi si wi fun Abiṣai pe, Máṣe pa a: nitoripe tani le nawọ́ rẹ̀ si ẹni-ami-ororo Oluwa ki o si wà laijẹbi?
10Dafidi si wipe, bi Oluwa ti mbẹ Oluwa yio pa a, tabi ọjọ rẹ̀ yio si pe ti yio kú, tabi on o sọkalẹ lọ si ibi ijà, a si ṣegbe nibẹ.
11Oluwa má jẹ ki emi nà ọwọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa: njẹ, emi bẹ ọ, mu ọ̀kọ na ti mbẹ nibi timtim rẹ̀, ati igo omi ki a si ma lọ.
12Dafidi si mu ọ̀kọ na, ati igo omi na kuro nibi timtim Saulu: nwọn si ba ti wọn lọ, kò si si ẹnikan ti o ri i, tabi ti o mọ̀; kò si si ẹnikan ti o ji; gbogbo wọn si sùn; nitoripe orun àjika lati ọdọ Oluwa wá ti ṣubu lù wọn.
13Dafidi si rekọja si iha keji, o si duro lori oke kan ti o jina rere; afo nla kan si wà lagbedemeji wọn:
14Dafidi si kọ si awọn enia na, ati si Abneri ọmọ Neri wipe, Iwọ kò dahun, Abneri? Nigbana ni Abneri si dahun wipe, Iwọ tani npe ọba?
15Dafidi si wi fun Abneri pe, Alagbara ọkunrin ki iwọ nṣe ndan? tali o si dabi iwọ ni Israeli? njẹ ẽṣe ti iwọ ko tọju ọba oluwa rẹ? nitori ẹnikan ninu awọn enia na ti wọle wá lati pa ọba oluwa rẹ.
16Nkan ti iwọ ṣe yi kò dara. Bi Oluwa ti mbẹ, o tọ ki ẹnyin ki o kú, nitoripe ẹnyin ko pa oluwa nyin mọ, ẹni-àmi-ororo Oluwa. Njẹ si wo ibiti ọ̀kọ ọba gbe wà, ati igò omi ti o ti wà nibi timtim rẹ̀.
17Saulu si mọ̀ ohùn Dafidi, o si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Dafidi si wipe, Ohùn mi ni, oluwa mi, ọba.
18On si wipe, Nitori kini oluwa mi ṣe nlepa iranṣẹ rẹ? kili emi ṣe? tabi ìwa buburu wo li o wà li ọwọ́ mi.
19Njẹ emi bẹ ọ ọba, oluwa mi, gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹ rẹ. Bi Oluwa ba ti ru iwọ soke si mi, jẹ ki on ki o gbà ẹbọ; ṣugbọn bi o ba si ṣepe ọmọ enia ni, ifibu ni ki nwọn ki o jasi niwaju Oluwa; nitori nwọn le mi jade loni ki emi má gbe inu ilẹ ini Oluwa, wipe, Lọ, sin awọn ọlọrun miran.
20Njẹ máṣe jẹ ki ẹjẹ mi ki o ṣàn silẹ niwaju Oluwa: nitori ọba Israeli jade lati wá itapin bi ẹni ndọdẹ aparo lori oke-nla.
21Saulu si wipe, Emi ti dẹṣẹ: yipada, Dafidi ọmọ mi: nitoripe emi kì yio wá ibi rẹ mọ, nitoriti ẹmi mi sa ti ṣe iyebiye li oju rẹ loni: wõ, emi ti nhuwa wère mo si ti ṣina jọjọ.
22Dafidi si dahun, o si wipe, Wo ọ̀kọ̀ ọba! ki o si jẹ ki ọkan ninu awọn ọmọkunrin rekọja wá gbà a.
23Ki Oluwa ki o san a fun olukuluku ododo rẹ̀ ati otitọ rẹ̀: nitoripe Oluwa ti fi ọ le mi lọwọ loni, ṣugbọn emi ko fẹ nawọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa.
24Si wõ, gẹgẹ bi ẹmi rẹ ti tobi loni loju mi, bẹni ki ẹmi mi ki o tobi loju Oluwa, ki o si gbà mi lọwọ ibi gbogbo.
25Saulu si wi fun Dafidi pe, Alabukunfun ni iwọ, Dafidi ọmọ mi: nitõtọ iwọ o si ṣe nkan nla, nitotọ iwọ o si bori. Dafidi si ba ọ̀na rẹ̀ lọ, Saulu si yipada si ibugbe rẹ̀.
Currently Selected:
I. Sam 26: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: