I. Sam 27
27
Dafidi láàrin àwọn Ará Filistia
1DAFIDI si wi li ọkàn ara rẹ̀ pe, njẹ ni ijọ kan l'emi o ti ọwọ́ Saulu ṣegbe, ko si si ohun ti o yẹ mi jù ki emi ki o yara sa asala lọ si ilẹ awọn Filistini: yio su Saulu lati ma tun wá mi kiri ni gbogbo agbegbe Israeli: emi a si bọ li ọwọ́ rẹ̀.
2Dafidi si dide, o si rekọja, on ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti o mbẹ lọdọ rẹ̀ si Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati.
3Dafidi si ba Akiṣi joko ni Gati, on, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, olukuluku wọn ti on ti ara ile rẹ̀; Dafidi pẹlu awọn aya rẹ̀ mejeji, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili ara Karmeli aya Nabali.
4A si sọ fun Saulu pe, Dafidi sa lọ si Gati: on ko si tun wá a kiri mọ.
5Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Bi o ba jẹ pe emi ri ore ọfẹ loju rẹ, jẹ ki wọn ki o fun mi ni ibi kan ninu awọn ileto wọnni; emi o ma gbe ibẹ: ẽṣe ti iranṣẹ rẹ yio si ma ba ọ gbe ni ilu ọba?
6Akiṣi si fi Siklagi fun u ni ijọ na; nitorina ni Siklagi fi di ti awọn ọba Juda titi o fi di oni yi.
7Iye ọjọ ti Dafidi fi joko ni ilu awọn Filistini si jẹ ọdun kan ati oṣu mẹrin.
8Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ, nwọn si gbe ogun ti awọn ara Geṣuri, ati awọn ara Gesra, ati awọn ara Amaleki: awọn wọnyi li o si ti ngbe ni ilẹ, na nigba atijọ, bi iwọ ti nlọ si Ṣuri titi o fi de ilẹ Egipti.
9Dafidi si kọlu ilẹ na, ko si fi ọkunrin tabi obinrin silẹ lãye, o si ko agùtan, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ, ati aṣọ, o si yipada o si tọ Akisi wá.
10Akiṣi si bi i pe, Nibo li ẹnyin gbe rìn si loni? Dafidi si dahun pe, Siha gusu ti Juda ni, ati siha gusun ti Jerameeli, ati siha gusu ti awọn ara Keni:
11Dafidi kò si da ọkunrin tabi obinrin si lãye, lati mu ihin wá si Gati, wipe, Ki nwọn ki o má ba sọ ọ̀rọ wa nibẹ, pe, Bayi ni Dafidi ṣe, ati bẹ̃ni iṣe rẹ̀ yio si ri ni gbogbo ọjọ ti yio fi joko ni ilu awọn Filistini.
12Akiṣi si gba ti Dafidi gbọ́, wipe, On ti mu ki Israeli ati awọn enia rẹ̀ korira rẹ̀ patapata, yio si jẹ iranṣẹ mi titi lai.
Currently Selected:
I. Sam 27: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: