I. Sam 7
7
1AWỌN ọkunrin Kirjatjearimu wá, nwọn gbe apoti Oluwa na, nwọn si mu u wá si ile Abinadabu ti o wà lori oke, nwọn si ya Eleasari ọmọ rẹ̀ si mimọ́ lati ma tọju apoti Oluwa.
2O si ṣe, lati igba ti apoti Oluwa fi wà ni Kirjatjearimu, ọjọ na pẹ́; o si jẹ ogun ọdun: gbogbo ile Israeli si pohunrere ẹkun si Oluwa.
3Samueli si sọ fun gbogbo ile Israeli, wipe, Bi ẹnyin ba fi gbogbo ọkàn nyin yipada si Oluwa, ẹ mu ajeji ọlọrun wọnni, ati Aṣtaroti kuro larin nyin, ki ẹnyin ki o si pese ọkàn nyin silẹ fun Oluwa, ki ẹ si ma sin on nikanṣoṣo: yio si gbà nyin lọwọ́ Filistini.
4Awọn ọmọ Israeli si mu Baalimu ati Aṣtaroti kuro, nwọn si sìn Oluwa nikan.
5Samueli si wipe, Pe gbogbo Israeli jọ si Mispe, emi o si bẹbẹ si Oluwa fun nyin,
6Nwọn si pejọ si Mispe, nwọn pọn omi, nwọn si tú u silẹ niwaju Oluwa, nwọn gbawẹ li ọjọ na, nwọn si wi nibẹ pe, Awa ti dẹṣẹ si Oluwa. Samueli si ṣe idajọ awọn ọmọ Israeli ni Mispe.
7Awọn Filistini si gbọ́ pe, awọn ọmọ Israeli pejọ si Mispe, awọn ijoye Filistini si goke tọ Israeli lọ. Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, nwọn bẹ̀ru awọn Filistini.
8Awọn ọmọ Israeli si wi fun Samueli pe, Máṣe dakẹ ati ma ke pe Oluwa Ọlọrun wa fun wa, yio si gbà wa lọwọ́ awọn Filistini.
9Samueli mu ọdọ-agutan kan ti nmu ọmu, o si fi i ru ọtọtọ ẹbọ sisun si Oluwa: Samueli si ke pe Oluwa fun Israeli; Oluwa si gbọ́ ọ.
10Bi Samueli ti nru ẹbọ sisun na lọwọ́, awọn Filistini si sunmọ Israeli lati ba wọn jà: ṣugbọn Oluwa sán ãrá nla li ọjọ na sori awọn Filistini, o si damu wọn, o si pa wọn niwaju Israeli.
11Awọn ọkunrin Israeli si jade kuro ni Mispe, nwọn si le awọn Filistini, nwọn si npa wọn titi nwọn fi de abẹ Betkari.
12Samueli si mu okuta kan, o si gbe e kalẹ lagbedemeji Mispe ati Seni, o si pe orukọ rẹ̀ ni Ebeneseri, wipe: Titi de ihin li Oluwa ràn wa lọwọ́.
13Bẹ̃li a tẹ ori awọn Filistini ba, nwọn kò si tun wá si agbegbe Israeli mọ: ọwọ́ Oluwa si wà ni ibi si awọn Filistini, ni gbogbo ọjọ Samueli.
14Ilu wọnni eyi ti awọn Filistini ti gbà lọwọ Israeli ni nwọn si fi fun Israeli, lati Ekroni wá titi o fi de Gati; ati agbegbe rẹ̀, ni Israeli gbà silẹ lọwọ́ awọn Filistini. Irẹpọ si wà larin Israeli ati awọn Amori.
15Samueli ṣe idajọ Israeli ni gbogbo ọjọ rẹ̀.
16Lati ọdun de ọdun li on ima lọ yika Beteli, ati Gilgali, ati Mispe, on si ṣe idajọ Israeli ni gbogbo ibẹ wọnni.
17On a si ma yipada si Rama: nibẹ ni ile rẹ̀ gbe wà; nibẹ na li on si ṣe idajọ Israeli, o si tẹ pẹpẹ nibẹ fun Oluwa.
Currently Selected:
I. Sam 7: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.