I. Tes 3
3
1NITORINA nigbati ara wa kò gba a mọ́, awa rò pe o dara ki a fi awa nikan sẹhin ni Ateni;
2Awa si rán Timotiu, arakunrin wa, ati iranṣẹ Ọlọrun ninu ihinrere Kristi, lati fi ẹsẹ nyin mulẹ, ati lati tù nyin ninu niti igbagbọ́ nyin:
3Ki a máṣe mu ẹnikẹni yẹsẹ nipa wahalà wọnyi: nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ pe a ti yàn wa sinu rẹ̀.
4Nitori nitõtọ nigbati awa wà lọdọ nyin, a ti nsọ fun nyin tẹlẹ pe, awa ó ri wahalà; gẹgẹ bi o si ti ṣẹ, ti ẹnyin si mọ̀.
5Nitori eyi, nigbati ara mi kò gba a mọ́, mo si ranṣẹ ki emi ki o le mọ igbagbọ́ nyin ki oludanwò nì má bã ti dan nyin wo lọnakọna, ki lãlã wa si jẹ asan.
6Ṣugbọn nisisiyi ti Timotiu ti ti ọdọ nyin wá sọdọ wa, ti o si ti mu ihinrere ti igbagbọ́ ati ifẹ nyin wá fun wa, ati pe ẹnyin nṣe iranti wa ni rere nigbagbogbo, ẹnyin si nfẹ gidigidi lati ri wa, bi awa pẹlu si ti nfẹ lati ri nyin:
7Nitori eyi, ará, awa ni itunu lori nyin ninu gbogbo wahalà ati ipọnju wa nitori igbagbọ́ nyin:
8Nitori awa yè nisisiyi, bi ẹnyin ba duro ṣinṣin ninu Oluwa.
9Nitori ọpẹ́ kili awa le tún ma dá lọwọ Ọlọrun nitori nyin, fun gbogbo ayọ̀ ti awa nyọ̀ nitori nyin niwaju Ọlọrun wa;
10Li ọsán ati li oru li awa ngbadura gidigidi pe, ki awa ki o le ri oju nyin, ki a si ṣe aṣepé eyiti o kù ninu igbagbọ́ nyin?
11Njẹ ki Ọlọrun ati Baba wa tikararẹ, ati Jesu Kristi Oluwa wa, ṣe amọ̀na wa sọdọ nyin.
12Ki Oluwa si mã mu nyin bisi i, ki ẹ si mã pọ̀ ninu ifẹ si ọmọnikeji nyin, ati si gbogbo enia, gẹgẹ bi awa ti nṣe si nyin:
13Ki o ba le fi ọkàn nyin balẹ li ailabukù ninu ìwa mimọ́ niwaju Ọlọrun ati Baba wa, nigba atiwá Jesu Kristi Oluwa wa pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀.
Currently Selected:
I. Tes 3: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.