II. Kor 2
2
1ṢUGBỌN mo ti pinnu eyi ninu emi tikarami pe, emi kì yio tun fi ibinujẹ tọ̀ nyin wá.
2Nitoripe bi emi ba mu inu nyin bajẹ, njẹ tali ẹniti o si nmu inu mi dùn, bikoṣe ẹniti mo ti bà ninu jẹ?
3Emi si kọwe nitori eyi kanna si nyin pe, nigbati mo ba si de, ki emi ki o máṣe ni ibinujẹ lọdọ wọn, nitori awọn ti emi iba mã yọ̀: nitoriti mo ni igbẹkẹle ninu gbogbo nyin, nitori ayọ̀ mi li ayọ̀ fun gbogbo nyin.
4Nitoripe ninu ọ̀pọlọpọ wahalà ati arodun ọkan mi ni mo ti fi ọ̀pọlọpọ omije kọwe si nyin; kì iṣe nitori ki a le bà nyin ninu jẹ, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ ifẹ ti mo ni si nyin lọpọlọpọ rekọja.
Ẹ Dárí Ji Ẹni Tí Ó Ṣe Àìdára
5Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba ti mu ibinujẹ wá, on kò bà mi ni inu jẹ, bikoṣe niwọn diẹ: ki emi ki o máṣe di ẹru l'ẹ̀ru gbogbo nyin.
6Ìya yi ti ọpọlọpọ ti fi jẹ iru enia bẹ̃, o to fun u.
7Kaka bẹ ẹ, ẹnyin iba kuku darijì i, ki ẹ si tù u ninu, lọnakọna ki ọpọlọpọ ibanujẹ má bã bò iru enia bẹ̃ mọlẹ.
8Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ fi ifẹ nyin han daju si oluwarẹ̀.
9Nitori eyi na pẹlu ni mo ti kọwe, ki emi ki o le mọ̀ ẹri nyin, bi ẹnyin ba ṣe eletí ọmọ li ohun gbogbo.
10Ṣugbọn ẹniti ẹnyin ba fi ohunkohun jì fun, emi fi jì pẹlu: nitori ohun ti emi pẹlu ba ti fi jì, bi mo ba ti fi ohunkohun jì, nitori tinyin ni mo ti fi ji niwaju Kristi.
11Ki Satani má bã rẹ́ wa jẹ: nitori awa kò ṣe alaimọ̀ arekereke rẹ̀.
Ọkàn Paulu Balẹ̀ Lẹ́yìn Àníyàn
12Ṣugbọn nigbati mo de Troa lati wãsu ihinrere Kristi, ti ilẹkun si ṣí silẹ fun mi lati ọdọ Oluwa wá,
13Emi kò ni alafia li ọkàn mi, nitoriti emi ko ri Titu arakunrin mi: ṣugbọn nigbati mo ti dagbere fun wọn, mo rekọja lọ si Makedonia.
14Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti nyọ̀ ayọ iṣẹgun lori wa nigbagbogbo ninu Kristi, ti o si nfi õrùn ìmọ rẹ̀ hàn nipa wa nibigbogbo.
15Nitori õrun didùn Kristi li awa jẹ fun Ọlọrun, ninu awọn ti a ngbalà, ati ninu awọn ti o nṣegbé:
16Fun awọn kan, awa jẹ õrun ikú si ikú, ati fun awọn miran õrun iyè. Tali o ha si to fun nkan wọnyi?
17Nitori awa kò dabi awọn ọ̀pọlọpọ, ti mba ọ̀rọ Ọlọrun jẹ́: ṣugbọn bi nipa otitọ inu, ṣugbọn bi lati ọdọ Ọlọrun wá, niwaju Ọlọrun li awa nsọ̀rọ ninu Kristi.
Currently Selected:
II. Kor 2: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: