II. Kor 3
3
Òjíṣẹ́ Majẹmu Titun
1AWA ha tún bẹ̀rẹ lati mã yìn ara wa bi? tabi awa ha nfẹ iwe iyìn sọdọ nyin, tabi lati ọdọ nyin bi awọn ẹlomiran?
2Ẹnyin ni iwe wa, ti a ti kọ si wa li ọkàn, ti gbogbo enia ti mọ̀, ti nwọn sì ti kà:
3Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, kì iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun alãye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran.
4Irú igbẹkẹle yi li awa si ni nipa Kristi sọdọ Ọlọrun:
5Kì iṣe pe awa to fun ara wa lati ṣirò ohunkohun bi ẹnipe lati ọdọ awa tikarawa; ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun ni tito wa;
6Ẹniti o mu wa tó bi iranṣẹ majẹmu titun; kì iṣe ti iwe, bikoṣe ti ẹmí: nitori iwe a mã pani, ṣugbọn ẹmí a mã sọni di ãye.
7Ṣugbọn bi iṣẹ-iranṣẹ ti ikú, ti a ti kọ ti a si ti gbẹ́ si ara okuta, ba jẹ ologo, tobẹ̃ ti awọn ọmọ Israeli kò le tẹjumọ ati wò oju Mose, nitori ogo oju rẹ̀ (ogo nkọja lọ),
8Yio ha ti ri ti iṣẹ-iranṣẹ ti ẹmí kì yio kuku jẹ ogo jù?
9Nitoripe bi iṣẹ-iranṣẹ idalẹbi ba jẹ ologo, melomelo ni iṣẹ-iranṣẹ ododo yio rekọja li ogo.
10Nitori eyi ti a tilẹ ṣe logo, kò li ogo mọ́ nitori eyi, nipasẹ ogo ti o tayọ.
11Nitoripe bi eyi ti nkọja lọ ba li ogo, melomelo li eyi ti o duro li ogo.
12Njẹ nitorina bi a ti ni irú ireti bi eyi, awa nfi igboiya pupọ sọ̀rọ.
13Kì si iṣe bi Mose, ẹniti o fi iboju bo oju rẹ̀, ki awọn ọmọ Israeli má ba le tẹjumọ wo opin eyi ti nkọja lọ.
14Ṣugbọn oju-inu wọn fọ́: nitoripe titi fi di oni oloni ní kika majẹmu lailai, iboju na wà laiká soke; iboju ti a ti mu kuro ninu Kristi.
15Ṣugbọn titi di oni oloni, nigbakugba ti a ba nkà Mose, iboju na mbẹ li ọkàn wọn.
16Ṣugbọn nigbati on o ba yipada si Oluwa, a o mu iboju na kuro.
17Njẹ Oluwa li Ẹmí na: nibiti Ẹmí Oluwa ba si wà, nibẹ̀ li omnira gbé wà.
18Ṣugbọn gbogbo wa nwò ogo Oluwa laisi iboju bi ẹnipe ninu awojiji, a si npawada si aworan kanna lati ogo de ogo, ani bi lati ọdọ Oluwa ti iṣe Ẹmí.
Currently Selected:
II. Kor 3: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: