II. Kor 4
4
Ìṣúra ti Ẹ̀mí Ninu ìkòkò Amọ̀
1NITORINA bi awa ti ni iṣẹ-iranṣẹ yi, gẹgẹ bi a ti ri ãnu gbà, ãrẹ̀ kò mu wa;
2Ṣugbọn awa ti kọ̀ gbogbo ohun ìkọkọ ti o ni itiju silẹ, awa kò rìn li ẹ̀tan, bẹ̃li awa kò fi ọwọ́ ẹ̀tan mu ọ̀rọ Ọlọrun; ṣugbọn nipa fifi otitọ hàn, awa nfi ara wa le ẹri-ọkàn olukuluku enia lọwọ niwaju Ọlọrun.
3Ṣugbọn bi ihinrere wa ba si farasin, o farasin fun awọn ti o nù:
4Ninu awọn ẹniti ọlọrun aiye yi ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ́ di afọju, ki imọlẹ ihinrere Kristi ti o logo, ẹniti iṣe aworan Ọlọrun, ki o máṣe mọlẹ ninu wọn.
5Nitori awa kò wãsu awa tikarawa, bikoṣe Kristi Jesu Oluwa; awa tikarawa si jẹ ẹrú nyin nitori Jesu.
6Nitori Ọlọrun, ẹniti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu òkunkun jade, on li o ti nmọlẹ li ọkàn wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ ogo Ọlọrun li oju Jesu Kristi.
7Ṣugbọn awa ni iṣura yi ninu ohun èlo amọ̀, ki ọlá nla agbara na ki o le ṣe ti Ọlọrun, ki o má ti ọdọ wa wá.
8A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara kò ní wa: a ndãmú wa, ṣugbọn a kò sọ ireti nù.
9A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a kò kọ̀ wa silẹ; a nrẹ̀ wa silẹ, ṣugbọn a kò si pa wa run;
10Nigbagbogbo awa nru ikú Jesu Oluwa kiri li ara wa, ki a le fi ìye Jesu hàn pẹlu li ara wa.
11Nitoripe nigbagbogbo li a nfi awa ti o wà lãyè fun ikú nitori Jesu, ki a le fi ìye Jesu hàn ninu ara kikú wa pẹlu.
12Bẹ̃ni ikú nṣiṣẹ ninu wa, ṣugbọn ìye ninu nyin.
13Awa li ẹmí igbagbọ́ kanna, gẹgẹ bi a ti kọ́ ọ pe, emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: awa pẹlu gbagbọ́, nitorina li awa si ṣe nsọ;
14Awa mọ̀ pe, ẹniti o jí Jesu Oluwa dide yio si jí wa dide pẹlu nipa Jesu, yio si mu wa wá iwaju rẹ̀ pẹlu nyin.
15Nitoripe tinyin li ohun gbogbo, ki ọpọ̀ ore-ọfẹ nipa awọn pipọ le mu ki ọpẹ di pipọ fun ogo Ọlọrun.
Ìgbé-Ayé Nípa Igbagbọ
16Nitori eyi ni ãrẹ̀ kò ṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ́.
17Nitori ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun iṣẹ́ju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ̀ rekọja fun wa.
18Niwọn bi a kò ti wò ohun ti a nri, bikoṣe ohun ti a kò ri: nitori ohun ti a nri ni ti igba isisiyi; ṣugbọn ohun ti a kò ri ni ti aiyeraiye.
Currently Selected:
II. Kor 4: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: