Iṣe Apo 24
24
Ẹ̀sùn Tí Wọ́n fi Kan Paulu
1LẸHIN ijọ marun Anania olori alufa ni sọkalẹ lọ pẹlu awọn alàgba ati ẹnikan Tertulu agbẹjọrò ẹniti o fi Paulu sùn bãlẹ.
2Nigbati a si ti pè e jade, Tertulu bẹ̀rẹ si ifi i sùn wipe, Bi o ti jẹ pe nipasẹ rẹ li awa njẹ alafia pipọ, ati pe nipasẹ itọju rẹ a nṣe atunṣe fun orilẹ yi.
3Nigbagbogbo, ati nibigbogbo, li awa nfi gbogbo ọpẹ́ tẹwọgbà a, Feliksi ọlọla julọ.
4Ṣugbọn ki emi ki o má bà da ọ duro pẹ titi, mo bẹ̀ ọ ki o fi iyọnu rẹ gbọ́ ọ̀rọ diẹ li ẹnu wa.
5Nitori awa ri ọkunrin yi, o jẹ onijagidi enia, ẹniti o ndá rukerudo silẹ lãrin gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo aiye, ati olori ẹ̀ya awọn Nasarene:
6Ẹniti o gbidanwo lati bà tẹmpili jẹ: ti awa si mu, ti awa fẹ ba ṣe ẹjọ gẹgẹ bi ofin wa.
7Ṣugbọn Lisia olori ogun de, o fi agbara nla gbà a li ọwọ wa:
8O paṣẹ ki awọn olufisùn rẹ̀ wá sọdọ rẹ: lati ọdọ ẹniti iwọ ó le ni oye gbogbo nkan wọnyi, nitori ohun ti awa ṣe fi i sùn nigbati iwọ ba ti wadi ẹjọ rẹ̀.
9Awọn Ju pẹlu si fi ohùn si i, wipe, bẹ̃ni nkan wọnyi ri.
Paulu Sọ Tẹnu Rẹ̀ Níwájú Fẹliksi
10Nigbati bãlẹ ṣapẹrẹ si i pe ki o sọ̀rọ, Paulu si dahùn wipe, Bi mo ti mọ̀ pe lati ọdún melo yi wá, ni iwọ ti ṣe onidajọ orilẹ-ede yi, tayọtayọ ni ng o fi wi ti ẹnu mi.
11Ki o le yé ọ pe, ijejila pére yi ni mo gòke lọ si Jerusalemu lati lọ jọsìn.
12Bẹ̃ni nwọn kò ri mi ni tẹmpili ki emi ki o ma ba ẹnikẹni jiyàn, bẹ̃li emi kò rú awọn enia soke, ibaṣe ninu sinagogu, tabi ni ilu:
13Bẹ̃ni nwọn kò le ladi ohun ti nwọn fi mi sùn si nisisiyi.
14Ṣugbọn eyi ni mo jẹwọ fun ọ, pe bi Ọna ti a npè ni adamọ̀, bẹ̃li emi nsìn Ọlọrun awọn baba wa, emi ngbà nkan gbogbo gbọ́ gẹgẹ bi ofin, ati ti a kọ sinu iwe awọn woli:
15Mo si ni ireti sipa ti Ọlọrun, eyi ti awọn tikarawọn pẹlu jẹwọ, pe ajinde okú mbọ̀, ati ti olõtọ, ati ti alaiṣõtọ.
16Ninu eyi li emi si nṣe idaraya, lati ni ẹri-ọkàn ti kò li ẹ̀ṣẹ sipa ti Ọlọrun, ati si enia nigbagbogbo.
17Ṣugbọn lẹhin ọdún pipọ, mo mu ọrẹ-ãnu fun orilẹ-ède mi wá, ati ọrẹ-ẹbọ.
18Larin wọnyi ni nwọn ri mi ni iwẹnu ni tẹmpili, bẹ̃ni kì iṣe pẹlu awujọ, tabi pẹlu ariwo.
19Ṣugbọn awọn Ju lati Asia wà nibẹ, awọn ti iba wà nihinyi niwaju rẹ, ki nwọn ki o já mi ni koro, bi nwọn ba li ohunkohun si mi.
20Bi kò ṣe bẹ̃, jẹ ki awọn enia wọnyi tikarawọn sọ iṣe buburu ti nwọn ri lọwọ mi, nigbati mo duro niwaju ajọ igbimọ yi,
21Bikoṣe ti gbolohùn kan yi, ti mo ke nigbati mo duro li ãrin wọn, Nitori ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ lọdọ nyin loni yi.
22Nigbati Feliksi gbọ́ nkan wọnyi, oye sa ye e li ayetan nipa Ọna na; o tú wọn ká na, o ni, Nigbati Lisia olori ogun ba sọkalẹ wá, emi o wadi ọ̀ran nyin daju.
23O si paṣẹ fun balogun ọrún kan pe, ki o mã ṣe itọju Paulu, ki o si bùn u làye, ati pe ki o máṣe dá awọn ojulumọ̀ rẹ̀ lẹkun, lati ma ṣe iranṣẹ fun u.
Wọ́n Ti Paulu Mọ́lé
24Ṣugbọn lẹhin ijọ melokan, Feliksi de ti on ti Drusilla obinrin rẹ̀, ti iṣe Ju, o si ranṣẹ pè Paulu, o si gbọ́ ọ̀rọ lọdọ rẹ̀ nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.
25Bi o si ti nsọ asọye nipa ti ododo ati airekọja ati idajọ ti mbọ̀, ẹ̀ru ba Feliksi, o dahùn wipe, Mã lọ nisisiyi na; nigbati mo ba si ni akokò ti o wọ̀, emi o ranṣẹ pè ọ.
26O si nreti pẹlu pe a ba fun on li owo lati ọwọ́ Paulu wá, ki on ki o le da a silẹ: nitorina a si ma ranṣẹ si i nigbakugba, a ma ba a sọ̀rọ.
27Ṣugbọn lẹhin ọdún meji, Porkiu Festu rọpò Feliksi: Feliksi si nfẹ ṣe oju're fun awọn Ju, o fi Paulu silẹ li ondè.
Currently Selected:
Iṣe Apo 24: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.