YouVersion Logo
Search Icon

Iṣe Apo 3

3
A Wo Arọ Kan Sàn Lẹ́nu Ọ̀nà Tẹmpili
1NJẸ Peteru on Johanu jumọ ngòke lọ si tẹmpili ni wakati adura, ti iṣe wakati kẹsan ọjọ.
2Nwọn si gbé ọkunrin kan ti o yarọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti nwọn ima gbé kalẹ li ojojumọ́ li ẹnu-ọna tẹmpili ti a npè ni Daradara, lati mã ṣagbe lọwọ awọn ti nwọ̀ inu tẹmpili lọ;
3Nigbati o ri Peteru on Johanu bi nwọn ti fẹ wọ̀ inu tẹmpili, o ṣagbe.
4Peteru si tẹjumọ́ ọ, pẹlu Johanu, o ni, Wò wa.
5O si fiyesi wọn, o nreti ati ri nkan gbà lọwọ wọn.
6Peteru wipe, Fadakà ati wura emi kò ni; ṣugbọn ohun ti mo ni eyini ni mo fifun ọ: Li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, dide ki o si mã rin.
7O si fà a li ọwọ́ ọtún, o si gbé e dide: li ojukanna ẹsẹ rẹ̀ ati egungun kokosẹ rẹ̀ si mokun.
8O si nfò soke, o duro, o si bẹrẹ si rin, o si ba wọn wọ̀ inu tẹmpili lọ, o nrìn, o si nfò, o si nyìn Ọlọrun.
9Gbogbo enia si ri i, o nrìn, o si nyìn Ọlọrun:
10Nwọn si mọ̀ pe on li o ti joko nṣagbe li ẹnu-ọ̀nà Daradara ti tẹmpili: hà si ṣe wọn, ẹnu si yà wọn gidigidi si ohun ti o ṣe lara rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ tí Peteru Sọ ní Ìloro Solomoni
11Bi arọ ti a mu larada si ti di Peteru on Johanu mu, gbogbo enia jumọ sure jọ tọ̀ wọn lọ ni iloro ti a npè ni ti Solomoni, ẹnu yà wọn gidigidi.
12Nigbati Peteru si ri i, o dahùn wi fun awọn enia pe, Ẹnyin enia Israeli, ẽṣe ti ha fi nṣe nyin si eyi? tabi ẽṣe ti ẹnyin fi tẹjumọ́ wa, bi ẹnipe agbara tabi iwa-mimọ́ wa li awa fi ṣe ti ọkunrin yi fi nrin?
13Ọlọrun Abrahamu, ati ti Isaaki, ati ti Jakọbu, Ọlọrun awọn baba wa, on li o ti yìn Jesu Ọmọ rẹ̀ logo; ẹniti ẹnyin ti fi le wọn lọwọ, ti ẹnyin si sẹ́ niwaju Pilatu, nigbati o ti pinnu rẹ̀ lati da a silẹ.
14Ṣugbọn ẹnyin sẹ́ Ẹni-Mimọ́ ati Olõtọ nì, ẹnyin si bere ki a fi apania fun nyin;
15Ẹnyin si pa Olupilẹṣẹ ìye, ẹniti Ọlọrun si ti ji dide kuro ninu okú; ẹlẹri eyiti awa nṣe.
16Ati orukọ rẹ̀, nipa igbagbọ́ ninu orukọ rẹ̀, on li o mu ọkunrin yi lara le, ẹniti ẹnyin ri ti ẹ si mọ̀: ati igbagbọ́ nipa rẹ̀ li o fun u ni dida ara ṣáṣa yi li oju gbogbo nyin.
17Njẹ nisisiyi, ará, mo mọ̀ pe, nipa aimọ̀ li ẹnyin fi ṣe e, gẹgẹ bi awọn olori nyin pẹlu ti ṣe.
18Ṣugbọn ohun ti Ọlọrun ti sọ tẹlẹ lati ẹnu gbogbo awọn woli wá pe, Kristi rẹ̀ yio jìya, on li o muṣẹ bẹ̃.
19Nitorina ẹ ronupiwada, ki ẹ si tun yipada, ki a le pa ẹ̀ṣẹ nyin rẹ́, ki akoko itura ba le ti iwaju Oluwa wá,
20Ati ki o ba le rán Kristi, ti a ti yàn fun nyin, aní Jesu;
21Ẹniti ọrun kò le ṣaima gbà titi di igba imupadà ohun gbogbo, ti Ọlọrun ti sọ lati ẹnu awọn woli rẹ̀ mimọ́ ti nwọn ti mbẹ nigbati aiye ti ṣẹ̀.
22Mose sa wipe, Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé woli kan dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ẹnyin o ma gbọ́ tirẹ̀ li ohun gbogbo ti yio ma sọ fun nyin.
23Yio si ṣe, olukuluku ọkàn ti kò ba gbọ ti woli na, on li a o parun patapata kuro ninu awọn enia.
24Ani gbogbo awọn woli lati Samueli wá, ati awọn ti o tẹle e, iye awọn ti o ti sọrọ, nwọn sọ ti ọjọ wọnyi pẹlu.
25Ẹnyin li ọmọ awọn woli, ati ti majẹmu tí Ọlọrun ti ba awọn baba nyin dá nigbati o wi fun Abrahamu pe, Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a ti fi ibukun fun gbogbo idile aiye.
26Nigbati Ọlọrun jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dide, o kọ́ rán a si nyin lati busi i fun nyin, nipa yiyi olukuluku nyin pada kuro ninu iwa buburu rẹ̀.

Currently Selected:

Iṣe Apo 3: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Video for Iṣe Apo 3