Est 3
3
Hamani Dìtẹ̀ láti Pa Àwọn Juu Run
1LẸHIN nkan wọnyi ni Ahaswerusi ọba gbe Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi ga, o si gbe e lekè, o si fi ijoko rẹ̀ lekè gbogbo awọn ijoye ti o wà pẹlu rẹ̀.
2Gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, kunlẹ nwọn si wolẹ fun Hamani: nitori ọba ti paṣẹ bẹ̃ nitori rẹ̀. Ṣugbọn Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò si wolẹ fun u.
3Nigbana ni awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, wi fun Mordekai pe, ẽṣe ti iwọ fi nré ofin ọba kọja?
4O si ṣe, nigbati nwọn wi fun u lojojumọ, ti on kò si gbọ́ ti wọn, nwọn sọ fun Hamani, lati wò bi ọ̀ran Mordekai yio ti le ri: nitori on ti wi fun wọn pe, enia Juda ni on.
5Nigbati Hamani si ri pe, Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò wolẹ fun on, nigbana ni Hamani kún fun ibinu.
6O si jẹ abùku loju rẹ̀ lati gbe ọwọ le Mordekai nikan; nitori nwọn ti fi awọn enia Mordekai hàn a: nitorina gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ijọba Ahaswerusi, ni Hamani wá ọ̀na lati parun, ani awọn enia Mordekai.
7Li oṣù kini, eyinì ni oṣù Nisani, li ọdun kejila ijọba Ahaswerusi, nwọn da purimu, eyinì ni, ìbo, niwaju Hamani, lati ọjọ de ọjọ, ati lati oṣù de oṣù lọ ide oṣù kejila, eyinì ni oṣù Adari.
8Hamani si sọ fun Ahaswerusi ọba pe, awọn enia kan fọn kakiri, nwọn si tuka lãrin awọn enia ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ, ofin wọn si yatọ si ti gbogbo enia; bẹ̃ni nwọn kò si pa ofin ọba mọ́; nitorina kò yẹ fun ọba lati da wọn si.
9Bi o ba wù ọba, jẹ ki a kọwe rẹ̀ pe, ki a run wọn: emi o si wọ̀n ẹgbãrun talenti fadaka fun awọn ti a fi iṣẹ na rán, ki nwọn ki o le mu u wá sinu ile iṣura ọba.
10Ọba si bọ́ oruka rẹ̀ kuro li ọwọ rẹ̀, o si fi fun Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi, ọta awọn Ju.
11Ọba si wi fun Hamani pe, a fi fadaka na bùn ọ, ati awọn enia na pẹlu, lati fi wọn ṣe bi o ti dara loju rẹ.
12Nigbana li a pè awọn akọwe ọba ni ọjọ kẹtala, oṣù kini, a si kọwe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti Hamani ti pa li aṣẹ fun awọn bãlẹ ọba, ati fun awọn onidajọ ti o njẹ olori gbogbo ìgberiko, ati fun awọn olori olukuluku enia ìgberiko gbogbo, gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati fun olukuluku enià gẹgẹ bi ède rẹ̀, li orukọ Ahaswerusi ọba li a kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀.
13A si fi iwe na rán awọn òjiṣẹ si gbogbo ìgberiko ọba, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo enia Juda, ati ọ̀dọ ati arugbo, awọn ọmọde, ati awọn obinrin ki o ṣegbe ni ọjọ kan, ani li ọjọ kẹtala, oṣù kejila, ti iṣe oṣù Adari, ati lati kó ohun iní wọn fun ijẹ.
14Ọ̀ran iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo igberiko, lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki nwọn ki o le mura de ọjọ na.
15Awọn ojiṣẹ na jade lọ, nwọn si yara, nitori aṣẹ ọba ni, a si pa aṣẹ na ni Ṣuṣani ãfin. Ati ọba ati Hamani joko lati mu ọti; ṣugbọn ilu Ṣuṣani dãmu.
Currently Selected:
Est 3: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.