Eks 25
25
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú ọrẹ fun mi wá: lọwọ olukuluku enia ti o ba fifunni tinutinu ni ki ẹnyin ki o gbà ọrẹ mi.
3Eyi si li ọrẹ ti ẹnyin o gbà lọwọ wọn; wurà, ati fadakà, ati idẹ;
4Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ, ati irun ewurẹ;
5Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu.
6Oróro fun fitila, olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn;
7Okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya.
8Ki nwọn ki o si ṣe ibi mimọ́ kan fun mi; ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn.
9Gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo fihàn ọ, nipa apẹrẹ agọ́, ati apẹrẹ gbogbo ohunèlo inu rẹ̀, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe e.
10Nwọn o si ṣe apoti igi ṣittimu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀.
11Iwọ o si fi kìki wurà bò o, ninu ati lode ni iwọ o fi bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà sori rẹ̀ yiká.
12Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi wọn si igun mẹrin rẹ̀; oruka meji yio si wà li apa kini rẹ̀, oruka meji yio si wà li apa keji rẹ̀.
13Iwọ o si ṣe ọpá ṣittimu, ki iwọ ki o si fi wurà bò wọn.
14Iwọ o si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, ki a le ma fi wọn gbé apoti na.
15Ọpá wọnni yio si ma wà ninu oruka apoti na: a ki yio si yọ wọn kuro ninu rẹ̀.
16Iwọ o si fi ẹrí ti emi o fi fun ọ sinu apoti nì.
17Iwọ o si fi kìki wurà ṣe itẹ-anu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀.
18Iwọ o si ṣe kerubu wurà meji; ni iṣẹ lilù ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ni ìku itẹ́-ãnu na mejeji.
19Si ṣe kerubu kini ni ìku kan, ati kerubu keji ni ìku keji: lati itẹ́-ãnu ni ki ẹnyin ki o ṣe awọn kerubu na ni ìku rẹ̀ mejeji.
20Awọn kerubu na yio si nà iyẹ́-apa wọn si oke, ki nwọn ki o fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, ki nwọn ki o si kọjusi ara wọn; itẹ́-ãnu na ni ki awọn kerubu na ki o kọjusi.
21Iwọ o si fi itẹ́-ãnu na sori apoti na; ati ninu apoti na ni iwọ o fi ẹri ti emi o fi fun ọ si.
22Nibẹ̀ li emi o ma pade rẹ, emi o si ma bá ọ sọ̀rọ lati oke itẹ́-ãnu wá, lati ãrin awọn kerubu mejeji wá, ti o wà lori apoti ẹrí na, niti ohun gbogbo ti emi o palaṣẹ fun ọ si awọn ọmọ Israeli.
23Iwọ o si ṣe tabili igi ṣittimu kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀.
24Iwọ o si fi kìki wurà bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà si i yiká.
25Iwọ o si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, iwọ o si ṣe igbáti wurà si eti rẹ̀ yiká.
26Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà li ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹrẹrin.
27Li abẹ igbáti na li oruka wọnni yio wà, fun ibi ọpá lati ma fi rù tabili na.
28Iwọ o si ṣe ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi wurà bò wọn, ki a le ma fi wọn rù tabili na.
29Iwọ o si ṣe awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, ati awo rẹ̀, lati ma fi dà: kìki wurà ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn.
30Iwọ o si ma gbé àkara ifihàn kalẹ lori tabili na niwaju mi nigbagbogbo.
31Iwọ o si fi kìki wurà ṣe ọpá-fitila kan: iṣẹlilù li a o fi ṣe ọpá-fitila na, ipilẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀; ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn o jẹ́:
32Ẹka mẹfa ni yio yọ ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha keji:
33Ago mẹta ni ki a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi ati itanna li ẹka kan; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka ekeji, pẹlu irudi ati itanna: bẹ̃li ẹka mẹfẹ̃fa ti o yọ lara ọpá-fitila na.
34Ati ninu ọpá-fitila na li ago mẹrin yio wà ti a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi wọn ati itanna wọn.
35Irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, gẹgẹ bi ẹka rẹ̀ mẹfẹfa ti o ti ara ọpá-fitila na yọ jade.
36Irudi wọn ati ẹka wọn ki o ri bakanna: ki gbogbo rẹ̀ ki o jẹ́ lilù kìki wurà kan.
37Iwọ o si ṣe fitila rẹ̀ na, meje: ki nwọn ki o si fi fitila wọnni sori rẹ̀, ki nwọn ki o le ma ṣe imọlẹ si iwaju rẹ̀.
38Ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, kìki wurà ni ki o jẹ́.
39Talenti kan kìki wurà ni ki o fi ṣe e, pẹlu gbogbo ohunèlo wọnyi.
40Si kiyesi i, ki iwọ ki o ṣe wọn gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, ti a fihàn ọ lori oke.
Currently Selected:
Eks 25: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.