Eks 30
30
1IWỌ o si ṣe pẹpẹ kan lati ma jó turari lori rẹ̀: igi ṣittimu ni ki iwọ ki o fi ṣe e.
2Igbọnwọ kan ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀; ìha mẹrin ọgbọgba ni ki o jẹ́: igbọnwọ meji si ni giga rẹ̀: iwo rẹ̀ yio si wà lara rẹ̀.
3Iwọ o si fi kìki wurà bò o, oke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀; iwọ o si ṣe igbáti wurà yi i ká.
4Ati oruka wurà meji ni ki iwọ ki o ṣe nisalẹ igbáti rẹ̀, ni ìha igun rẹ̀ meji, li ẹgbẹ rẹ̀ mejeji ni ki iwọ ki o ṣe e si; nwọn o si jasi ipò fun ọpá wọnni, lati ma fi gbé e.
5Iwọ o si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, iwọ o si fi wurà bò wọn.
6Iwọ o si gbé e kà iwaju aṣọ-ikele nì ti o wà lẹba apoti ẹrí, niwaju itẹ́-ãnu ti o wà lori apoti ẹrí nì, nibiti emi o ma bá ọ pade.
7Aaroni yio si ma jó turari didùn lori rẹ̀; li orowurọ̀, nigbati o ba tun fitila wọnni ṣe, on o si ma jó o lori rẹ̀.
8Nigbati Aaroni ba si tàn fitila wọnni li aṣalẹ, yio si ma jó turari lori rẹ̀, turari titilai niwaju OLUWA lati irandiran nyin.
9Ẹnyin kò gbọdọ mú ajeji turari wá sori rẹ̀, tabi ẹbọ sisun, tabi ẹbọ onjẹ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ dà ẹbọ ohun mimu sori rẹ̀.
10Aaroni yio si ma fi ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ ètutu ṣètutu lori iwo rẹ̀ lẹ̃kan li ọdún: yio ṣètutu lori rẹ̀ lẹ̃kan li ọdun lati irandiran nyin: mimọ́ julọ ni si OLUWA.
11OLUWA si sọ fun Mose pe,
12Nigbati iwọ ba kà iye awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi ẹgbẹ wọn, nigbana li olukuluku ọkunrin yio mú irapada ọkàn rẹ̀ fun OLUWA wá, nigbati iwọ ba kà iye wọn; ki ajakalẹ-àrun ki o máṣe si ninu wọn, nigbati iwọ ba nkà iye wọn.
13Eyi ni nwọn o múwa, olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, àbọ ṣekeli, ani ṣekeli ibi mimọ́: (ogún gera ni ṣekeli kan:) àbọ ṣekeli li ọrẹ fun OLUWA.
14Olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, ni yio fi ọrẹ fun OLUWA.
15Olowo ki o san jù bẹ̃ lọ, bẹ̃li awọn talaka kò si gbọdọ di li àbọ ṣekeli, nigbati nwọn ba mú ọrẹ wá fun OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin.
16Iwọ o si gbà owo ètutu na lọwọ awọn ọmọ Israeli, iwọ o si fi i lelẹ fun ìsin agọ́ ajọ; ki o le ma ṣe iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin.
17OLUWA si sọ fun Mose pe,
18Iwọ o si ṣe agbada idẹ kan, ati ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fun wiwẹ̀: iwọ o si gbẹ́ e kà agbedemeji agọ́ ajọ, ati pẹpẹ nì, iwọ o si pọn omi sinu rẹ̀.
19Nitori Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn nibẹ̀:
20Nigbati nwọn ba nwọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, nwọn o fi omi wẹ̀ ki nwọn ki o má ba kú: tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ nì lati ṣe ìsin, lati ru ẹbọ sisun ti a fi iná ṣe si OLUWA:
21Nwọn o si wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn, ki nwọn ki o má ba kú: yio si di ìlana fun wọn lailai, fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lati irandiran wọn.
22OLUWA si sọ fun Mose pe,
23Iwọ mú ãyo olõrùn si ọdọ rẹ, pẹlu ojia sísan ẹdẹgbẹta ṣekeli, ati kinnamoni didùn idameji bẹ̃, ani ãdọtalerugba ṣekeli, ati kalamu didùn ãdọtalerugba ṣekeli,
24Ati kassia ẹdẹgbẹta ṣekeli, ṣekeli ibi mimọ́, ati hini oróro olifi kan:
25Iwọ o si ṣe e li oróro mimọ́ ikunra, ti a fi ọgbọ́n alapòlu pò: yio si jẹ́ oróro mimọ́ itasori.
26Iwọ o si ta ninu rẹ̀ sara agọ́ ajọ, ati apoti ẹrí nì,
27Ati tabili ati ohunèlo rẹ̀ gbogbo, ati ọpáfitila ati ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari,
28Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀.
29Iwọ o si yà wọn simimọ́, ki nwọn ki o le ṣe mimọ́ julọ: ohunkohun ti o ba fọwọkàn wọn yio di mimọ́.
30Iwọ o si ta òróró sí Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si yà wọn si mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe alufa fun mi.
31Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Eyi ni yio ma ṣe oróro mimọ́ itasori fun mi lati irandiran nyin.
32A ko gbọdọ dà a si ara enia, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe irú rẹ̀, ni ìwọn pipò rẹ̀: mimọ́ ni, yio si ma ṣe mimọ́ fun nyin.
33Ẹnikẹni ti o ba pò bi irú rẹ̀, tabi ẹnikẹni ti o ba fi sara alejò ninu rẹ̀, on li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
34OLUWA si wi fun Mose pe, Mú olõrùn didùn sọdọ rẹ, stakte, ati onika, ati galbanumu; olõrùn didùn wọnyi, pẹlu turari daradara: òṣuwọn kan na li olukuluku;
35Iwọ o si ṣe e ni turari, apòlu nipa ọgbọ́n-ọnà alapòlu, ti a fi iyọ̀ si, ti o dara ti o si mọ́.
36Iwọ o si gún diẹ ninu rẹ̀ kunna, iwọ o si fi i siwaju ẹrí ninu rẹ̀ ninu agọ́ ajọ, nibiti emi o gbé ma bá ọ pade: yio ṣe mimọ́ julọ fun nyin.
37Ati ti turari ti iwọ o ṣe, ẹnyin kò gbọdọ ṣe e fun ara nyin ni ìwọn pipò rẹ̀: yio si ṣe mimọ́ fun ọ si OLUWA.
38Ẹnikẹni ti o ba ṣe irú rẹ̀, lati ma gbõrùn rẹ̀, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
Currently Selected:
Eks 30: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.