Gal 2
2
Àwọn Aposteli Yòókù Gba Paulu Bí Aposteli
1LẸHIN ọdún mẹrinla, nigbana ni mo tún gòke lọ si Jerusalemu pẹlu Barnaba, mo si mu Titu lọ pẹlu mi.
2Mo si gòke lọ nipa ifihan, mo si gbe ihinrere na kalẹ niwaju wọn ti mo nwasu larin awọn Keferi, ṣugbọn nikọ̀kọ fun awọn ti o jẹ ẹni-nla, ki emi kì o má ba sáre, tabi ki o má ba jẹ pe mo ti sáre lasan.
3Ṣugbọn a kò fi agbara mu Titu ti o wà pẹlu mi, ẹniti iṣe ara Hellene, lati kọla:
4Ati nitori awọn eke arakunrin ti a yọ́ mu wọ̀ inu wa wá, awọn ẹniti o yọ́ wa iṣe amí lati ri omnira wa, ti awa ni ninu Kristi Jesu, ki nwọn ki o le mu wa wá sinu ìde:
5Awọn ẹniti awa kò si fi àye fun lati dari wa fun wakati kan; ki otitọ ìhinrere ki o le mã wà titi pẹlu nyin.
6Ṣugbọn niti awọn ti o dabi ẹni nla, ohunkohun ti o wù ki nwọn jasi, kò jẹ nkankan fun mi: Ọlọrun kò ṣe ojuṣãju ẹnikẹni: ani awọn ti o dabi ẹni-nla, kò kọ́ mi ni nkankan.
7Ṣugbọn kàkà bẹ̃, nigbati nwọn ri pe a ti fi ihinrere ti awọn alaikọla le mi lọwọ, bi a ti fi ihinrere ti awọn onila le Peteru lọwọ;
8(Nitori ẹniti o ṣiṣẹ ninu Peteru si iṣẹ Aposteli ti ikọla, on kanna li o ṣiṣẹ ninu mi fun awọn Keferi pẹlu),
9Ati nigbati Jakọbu, ati Kefa, ati Johanu, awọn ẹniti o dabi ọwọ̀n, woye ore-ọfẹ ti a fifun mi, nwọn si fi ọwọ́ ọtún ìdapọ fun emi ati Barnaba, pe ki awa ki o mã lọ sọdọ awọn Keferi, ati awọn sọdọ awọn onila.
10Kìki nwọn fẹ ki a mã ranti awọn talakà, ohun kanna gan ti mo nfi titaratitara ṣe pẹlu.
Paulu Bá Peteru Wí ní Antioku
11Ṣugbọn nigbati Peteru wá si Antioku, mo ta kò o li oju ara rẹ̀, nitoriti o jẹ ẹniti a ba bawi.
12Nitoripe ki awọn kan ti o ti ọdọ Jakọbu wá to de, o ti mba awọn Keferi jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn de, o fà sẹhin, o si yà ara rẹ̀ si apakan, o mbẹ̀ru awọn ti iṣe onila.
13Awọn Ju ti o kù si jùmọ ṣe agabagebe bẹ̃ gẹgẹ pẹlu rẹ̀; tobẹ̃ ti nwọn si fi agabagebe wọn fà Barnaba tikararẹ lọ.
14Ṣugbọn nigbati mo ri pe nwọn kò rìn dẽdẽ gẹgẹ bi otitọ ihinrere, mo wi fun Peteru niwaju gbogbo wọn pe, Bi iwọ, ti iṣe Ju, ba nrìn gẹgẹ bi ìwa awọn Keferi, laiṣe bi awọn Ju, ẽṣe ti iwọ fi nfi agbara mu awọn Keferi lati mã rìn bi awọn Ju?
Igbagbọ Ni Ọ̀nà Ìgbàlà fún Gbogbo Eniyan
15Awa ti iṣe Ju nipa ẹda, ti kì si iṣe ẹlẹṣẹ ti awọn Keferi,
16Ti a mọ̀ pe a ko da ẹnikẹni lare nipa iṣẹ ofin, bikoṣe nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, ani awa na gbà Jesu Kristi gbọ́, ki a ba le da wa lare nipa igbagbọ́ ti Kristi, kì si iṣe nipa iṣẹ ofin: nitoripe nipa iṣẹ ofin kò si enia kan ti a o dalare.
17Ṣugbọn nigbati awa ba nwá ọ̀na lati ri idalare nipa Kristi, bi a ba si ri awa tikarawa li ẹlẹṣẹ, njẹ́ Kristi ha nṣe iranṣẹ ẹ̀ṣẹ bi? Ki a má ri.
18Nitoripe bi mo ba si tun gbe ohun wọnni ti mo ti wó palẹ ró, mo fi ara mi han bi arufin.
19Nitoripe nipa ofin mo ti di oku si ofin, ki emi ki o le wà lãye si Ọlọrun.
20A ti kàn mi mọ agbelebu pẹlu Kristi: ṣugbọn mo wà lãye, sibẹ ki iṣe emi mọ́, ṣugbọn Kristi wà lãye ninu mi: wiwà ti mo si wà lãye ninu ara, mo wa lãye ninu igbagbọ Ọmọ Ọlọrun, ẹniti o fẹ mi, ti o si fi on tikararẹ̀ fun mi.
21Emi kò sọ ore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitoripe bi ododo ba ti ipa ofin wá, njẹ Kristi kú lasan.
Currently Selected:
Gal 2: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.