Gẹn 18
18
Ọlọrun Ṣèlérí Ọmọkunrin Kan fún Abrahamu
1OLUWA si farahàn a ni igbo Mamre: on si joko li ẹnu-ọ̀na agọ́ ni imõru ọjọ́:
2O si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, ọkunrin mẹta duro li ẹba ọdọ rẹ̀: nigbati o si ri wọn, o sure lati ẹnu-ọ̀na agọ́ lọ ipade wọn, o si tẹriba silẹ.
3O si wipe, OLUWA mi, njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, emi bẹ̀ ọ, máṣe kọja lọ kuro lọdọ ọmọ-ọdọ rẹ:
4Jẹ ki a mu omi diẹ wá nisisiyi, ki ẹnyin ki o si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ki ẹnyin ki o si simi labẹ igi:
5Emi o si mu onjẹ diẹ wá, ki ẹnyin si fi ọkàn nyin balẹ; lẹhin eyini ki ẹnyin ma kọja lọ: njẹ nitorina li ẹnyin ṣe tọ̀ ọmọ-ọdọ nyin wá. Nwọn si wipe, Ṣe bẹ̃ bi iwọ ti wi.
6Abrahamu si yara tọ̀ Sara lọ ninu agọ́, o wipe, Yara mu òṣuwọn iyẹfun daradara mẹta, ki o pò o, ki o si dín akara.
7Abrahamu si sure lọ sinu agbo, o si mu ẹgbọrọ-malu kan ti o rọ̀ ti o dara, o fi fun ọmọkunrin kan; on si yara lati sè e.
8O si mu orí-amọ́, ati wàra, ati ẹgbọrọ malu ti o sè, o si gbé e kalẹ niwaju wọn: on si duro tì wọn li abẹ igi na, nwọn si jẹ ẹ.
9Nwọn si bi i pe, nibo ni Sara aya rẹ wà? o si wipe, wò o ninu agọ́.
10O si wipe, Emi o si tun pada tọ̀ ọ wá nitõtọ ni iwoyi amọ́dun; si kiyesi i, Sara aya rẹ yio li ọmọkunrin kan. Sara si gbọ́ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ti o wà lẹhin ọkunrin na.
11Njẹ Abrahamu on Sara gbó, nwọn si pọ̀ li ọjọ́; o si dẹkun ati ma ri fun Sara bi ìwa obinrin.
12Nitorina Sara rẹrin ninu ara rẹ̀ wipe, Lẹhin igbati mo di ogbologbo tan, emi o ha li ayọ̀, ti oluwa mi si di ogbologbo pẹlu?
13OLUWA si wi fun Abrahamu pe, Nitori kini Sara ṣe nrẹrin wipe, Emi o ha bímọ nitõtọ, ẹniti o ti gbó tán?
14Ohun kan ha ṣoro fun OLUWA? li akoko ti a dá emi o pada tọ̀ ọ wa, ni iwoyi amọ́dun, Sara yio si li ọmọkunrin kan.
15Sara si sẹ, wipe, Emi kò rẹrin; nitoriti o bẹ̀ru. On si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn iwọ rẹrin.
Abrahamu Bẹ̀bẹ̀ fún Sodomu
16Awọn ọkunrin na si dide kuro nibẹ̀, nwọn kọju sihà Sodomu: Abrahamu si ba wọn lọ lati sìn wọn de ọ̀na.
17OLUWA si wipe, Emi o ha pa ohun ti emi o ṣe mọ́ fun Abrahamu:
18Nitori pe, Abrahamu yio sa di orilẹ-ède nla ati alagbara, ati gbogbo orilẹ-ède aiye li a o bukun fun nipasẹ rẹ̀?
19Nitoriti mo mọ̀ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ara ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọ̀na OLUWA mọ́ lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u.
20OLUWA si wipe, Nitori ti igbe Sodomu on Gomorra pọ̀, ati nitori ti ẹ̀ṣẹ wọn pàpọju.
21Emi o sọkalẹ lọ nisisiyi, ki nri bi nwọn tilẹ ṣe, gẹgẹ bi okikí igbe rẹ̀, ti o de ọdọ mi; bi bẹ si kọ, emi o mọ̀.
22Awọn ọkunrin na si yi oju wọn pada kuro nibẹ̀, nwọn si lọ si Sodomu: ṣugbọn Abrahamu duro sibẹ̀ niwaju OLUWA.
23Abrahamu si sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Iwọ o ha run olododo pẹlu enia buburu?
24Bọya ãdọta olododo yio wà ninu ilu na: iwọ o ha run u, iwọ ki yio ha dá ibẹ̀ na si nitori ãdọta olododo ti o wà ninu rẹ̀?
25O ha dára, ti iwọ o fi ṣe bi irú eyi, lati run olododo pẹlu enia buburu; ti awọn olododo yio fi dabi awọn enia buburu, o ha dára: Onidajọ gbogbo aiye ki yio ha ṣe eyi ti o tọ́?
26OLUWA si wipe, Bi mo ba ri ãdọta olododo ninu ilu Sodomu, njẹ emi o dá gbogbo ibẹ̀ si nitori wọn.
27Abrahamu si dahùn o si wipe, Wò o nisisiyi, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ, emi ẹniti iṣe erupẹ ati ẽru.
28Bọya marun a dín ninu ãdọta olododo na: iwọ o ha run gbogbo ilu na nitori marun? On si wipe, Bi mo ba ri marunlelogoji nibẹ̀, emi ki yio run u.
29O si tun sọ fun u ẹ̀wẹ, o ni, Bọya, a o ri ogoji nibẹ̀, On si wipe, Emi ki o run u nitori ogoji.
30O si tun wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, emi o si ma wi: bọya a o ri ọgbọ̀n nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u bi mo ba ri ọgbọ̀n nibẹ̀.
31O si wipe, Wò o na, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ: bọya a o ri ogun nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori ogun.
32O si wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, ẹ̃kanṣoṣo yi li emi o si wi mọ. Bọya a o ri mẹwa nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori mẹwa.
33OLUWA si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna bi o ti ba Abrahamu sọ̀rọ tan; Abrahamu si pada lọ si ibujoko rẹ̀.
Currently Selected:
Gẹn 18: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.