Gẹn 33
33
Jakọbu Pàdé Esau
1JAKOBU si gbé oju rẹ̀ soke, o si wò, si kiyesi i, Esau dé, ati irinwo ọkunrin pẹlu rẹ̀. On si pín awọn ọmọ fun Lea, ati fun Rakeli, ati fun awọn iranṣẹbinrin mejeji.
2O si tì awọn iranṣẹbinrin ati awọn ọmọ wọn ṣaju, ati Lea ati awọn ọmọ rẹ̀ tẹle wọn, ati Rakeli ati Josefu kẹhin.
3On si kọja lọ siwaju wọn, o si wolẹ li ẹrinmeje titi o fi dé ọdọ arakunrin rẹ̀.
4Esau si sure lati pade rẹ̀, o si gbá a mú, o si rọmọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: nwọn si sọkun.
5O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri awọn obinrin ati awọn ọmọ; o si bi i pe, Tani wọnyi pẹlu rẹ? On si wipe, Awọn ọmọ ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ fun iranṣẹ rẹ ni.
6Nigbana li awọn iranṣẹbinrin sunmọ ọdọ rẹ̀, awọn ati awọn ọmọ wọn, nwọn si tẹriba.
7Ati Lea pẹlu ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba: nikẹhin ni Josefu ati Rakeli si sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba.
8O si wipe, Kini iwọ fi ọwọ́ ti mo pade ni pè? On si wipe, Lati fi ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi ni.
9Esau si wipe, Emi ní tó, arakunrin mi; pa eyiti o ní mọ́ fun ara rẹ.
10Jakobu si wipe, Bẹ̃kọ, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi, njẹ gbà ọrẹ mi lọwọ mi: nitori ti emi sa ri oju rẹ bi ẹnipe emi ri oju Ọlọrun, ti inu rẹ si dùn si mi;
11Emi bẹ̀ ọ, gbà ẹ̀bun mi ti a mú fun ọ wá; nitori ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ ba mi ṣe, ati pe, nitori ti mo ní tó. O si rọ̀ ọ, on si gbà a.
12O si wipe, Jẹ ki a bọ́ si ọ̀na ìrin wa, ki a si ma lọ, emi o si ṣaju rẹ.
13Ṣugbọn on wi fun u pe, oluwa mi mọ̀ pe awọn ọmọ kò lera, ati awọn agbo-ẹran, ati ọwọ́-malu ati awọn ọmọ wọn wà pẹlu mi: bi enia ba si dà wọn li àdaju li ọjọ́ kan, gbogbo agbo ni yio kú.
14Emi bẹ̀ ọ, ki oluwa mi ki o ma kọja nṣó niwaju iranṣẹ rẹ̀: emi o si ma fà wá pẹlẹ, gẹgẹ bi awọn ẹran ti o saju mi, ati bi ara awọn ọmọ ti le gbà, titi emi o fi dé ọdọ oluwa mi ni Seiri.
15Esau si wipe, Njẹ ki emi ki o fi enia diẹ silẹ pẹlu rẹ ninu awọn enia ti o pẹlu mi. On si wipe, Nibo li eyini jasi, ki emi ki o sa ri õre-ọfẹ li oju oluwa mi.
16Esau si pada li ọjọ́ na li ọ̀na rẹ̀ lọ si Seiri.
17Jakobu si rìn lọ si Sukkotu, o si kọ́ ile fun ara rẹ̀, o si pa agọ́ fun awọn ẹran rẹ̀: nitorina li a ṣe sọ orukọ ibẹ̀ na ni Sukkotu.
18Jakobu si wá li alafia, si ilu Ṣekemu ti o wà ni ilẹ Kenaani, nigbati o ti Padan-aramu dé: o si pa agọ́ rẹ̀ niwaju ilu na.
19O si rà oko biri kan, nibiti o gbé ti pa agọ́ rẹ̀ lọwọ awọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu, li ọgọrun owo fadaka.
20O si tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ̀, o si sọ orukọ rẹ̀ ni El-Elohe-Israeli.
Currently Selected:
Gẹn 33: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.