Gẹn 38
38
Juda ati Tamari
1O SI ṣe li akokò na, ni Judah sọkalẹ lọ kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, o si yà sọdọ ara Adullamu kan, orukọ ẹniti ijẹ́ Hira.
2Judah si ri ọmọbinrin ara Kenaani kan nibẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Ṣua; o si mú u, o si wọle tọ̀ ọ.
3O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Eri.
4O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Onani.
5O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣela: o wà ni Kesibu, nigbati o bí i.
6Judah si fẹ́ aya fun Eri akọ́bi rẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Tamari.
7Eri akọ́bi Judah si ṣe enia buburu li oju OLUWA; OLUWA si pa a.
8Judah si wi fun Onani pe, Wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ lọ, ki o si ṣú u li opó, ki o si bimọ si ipò arakunrin rẹ.
9Onani si mọ̀ pe, irú-ọmọ ki yio ṣe tirẹ̀; o si ṣe bi o ti wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ̀ lọ, o si dà a silẹ, ki o má ba fi irú-ọmọ fun arakunrin rẹ̀.
10Ohun ti o si ṣe buru loju OLUWA, nitori na li OLUWA pa a pẹlu.
11Nigbana ni Judah wi fun Tamari aya ọmọ rẹ̀ pe, Joko li opó ni ile baba rẹ, titi Ṣela ọmọ mi o fi dàgba: nitori o wipe, Ki on má ba kú pẹlu, bi awọn arakunrin rẹ̀. Tamari si lọ, o si joko ni ile baba rẹ̀.
12Nigbati ọjọ́ si npẹ́, ọmọbinrin Ṣua, aya Juda kú; Judah si gbipẹ̀, o si tọ̀ awọn olurẹrun agutan rẹ̀, lọ si Timnati, on ati Hira ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu.
13A si wi fun Tamari pe, Kiyesi i, baba ọkọ rẹ lọ si Timnati lati rẹrun agutan rẹ̀.
14O si bọ́ aṣọ opó rẹ̀ kuro li ara rẹ̀, o si fi iboju bò ara rẹ̀, o si roṣọ, o si joko li ẹnubode Enaimu, ti o wà li ọ̀na Timnati; nitoriti o ri pe Ṣela dàgba, a kò si fi on fun u li aya.
15Nigbati Judah ri i, o fi i pè panṣaga; nitori o boju rẹ̀.
16O si yà tọ̀ ọ li ẹba ọ̀na, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, wá na, jẹ ki emi ki o wọle tọ̀ ọ; (on kò sa mọ̀ pe aya ọmọ on ni iṣe.) On si wipe Kini iwọ o fi fun mi, ki iwọ ki o le wọle tọ̀ mi?
17O si wipe, emi o rán ọmọ ewurẹ kan si ọ lati inu agbo wá. On si wipe, iwọ ki o fi ògo fun mi titi iwọ o fi rán a wá?
18O si bi i pe, Ògo kili emi o fi fun ọ? on si wipe, Èdidi rẹ, ati okùn rẹ, ati ọpá rẹ ti o wà li ọwọ́ rẹ; o si fi wọn fun u, o si wọle tọ̀ ọ lọ, on si ti ipa ọdọ rẹ̀ yún.
19On si dide, o ba tirẹ̀ lọ, o si bọ́ iboju rẹ̀ lelẹ kuro lara rẹ̀, o si mú aṣọ opó rẹ̀ ró.
20Judah si rán ọmọ ewurẹ na lati ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu na lọ, lati gbà ògo nì wá lọwọ obinrin na: ṣugbọn on kò ri i.
21Nigbana li o bère lọwọ awọn ọkunrin ibẹ̀ na pe, Nibo ni panṣaga nì ngbé, ti o wà ni Enaimu li ẹba ọ̀na? Nwọn si wipe, Panṣaga kan kò sí nihin.
22O si pada tọ̀ Judah lọ, o si wipe, Emi kò ri i; ati pẹlu awọn ọkunrin ara ibẹ̀ na wipe, Kò sí panṣaga kan nibẹ̀.
23Judah si wipe, Jẹ ki o ma mú u fun ara rẹ̀, ki oju ki o má tì wa: kiyesi i, emi rán ọmọ ewurẹ yi, iwọ kò si ri i.
24O si ṣe niwọ̀n oṣù mẹta lẹhin rẹ̀, ni a wi fun Judah pe, Tamari aya ọmọ rẹ ṣe àgbere; si kiyesi i pẹlu, o fi àgbere loyun. Judah si wipe, Mú u jade wá, ki a si dána sun u.
25Nigbati a si mú u jade, o ranṣẹ si baba ọkọ rẹ̀ pe, ọkunrin ti o ní nkan wọnyi li emi yún fun: o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mọ̀ wọn, ti tani nkan wọnyi, èdidi, ati okùn, ati ọpá.
26Judah si jẹwọ, o si wipe, O ṣe olododo jù mi lọ; nitori ti emi kò fi i fun Ṣela ọmọ mi. On kò si mọ̀ ọ mọ́ lai.
27O si ṣe li akokò ti o nrọbí, si kiyesi i, ìbejì wà ni inu rẹ̀.
28O si ṣe nigbati o nrọbí, ti ọkan yọ ọwọ́ jade: iyãgba si mú okùn ododó o so mọ́ ọ li ọwọ́, o wipe, Eyi li o kọ jade.
29O si ṣe, bi o ti fà ọwọ́ rẹ̀ pada, si kiyesi i, aburo rẹ̀ jade: o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yà? yiyà yi wà li ara rẹ, nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Peresi:
30Nikẹhin li arakunrin rẹ̀ jade, ti o li okùn ododó li ọwọ́ rẹ̀: a si sọ orukọ rẹ̀ ni Sera.
Currently Selected:
Gẹn 38: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.