YouVersion Logo
Search Icon

Gẹn 41

41
Josẹfu Túmọ̀ Àlá Ọba
1O SI ṣe li opin ọdún meji ṣanṣan, ni Farao lá alá: si kiyesi i, o duro li ẹba odo.
2Si kiyesi i abo-malu meje, ti o dara ni wiwò, ti o sanra, jade lati inu odò na wá: nwọn si njẹ ninu ẽsu-odò.
3Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o buru ni wiwò, ti o si rù, jade lẹhin wọn lati inu odò na wá; nwọn si duro tì awọn abo-malu nì ni bèbe odò na.
4Awọn abo-malu ti o buru ni wiwò ti o si rù si mú awọn abo-malu meje ti o dara ni wiwò ti o si sanra wọnni jẹ. Bẹ̃ni Farao jí.
5O si sùn, o si lá alá lẹrinkeji: si kiyesi i, ṣiri ọkà meje yọ lara igi ọkà kan, ti o kún ti o si dara.
6Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje ti o fori, ti afẹfẹ íla-õrùn rẹ̀ dànu si rú jade lẹhin wọn.
7Ṣiri meje ti o fori si mú ṣiri meje daradara ti o kún nì jẹ. Farao si jí, si kiyesi i, alá ni.
8O si ṣe li owurọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò lelẹ; o si ranṣẹ o si pè gbogbo awọn amoye Egipti, ati gbogbo awọn ọ̀mọran ibẹ̀ wá: Farao si rọ́ alá rẹ̀ fun wọn: ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o le tumọ wọn fun Farao.
9Nigbana li olori agbọti wi fun Farao pe, Emi ranti ẹ̀ṣẹ mi loni:
10Farao binu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si fi mi sinu túbu ni ile-túbu olori ẹṣọ́, emi ati olori alasè:
11Awa si lá alá li oru kanna, emi ati on; awa lá alá olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀.
12Ọdọmọkunrin kan ara Heberu, ọmọ-ọdọ olori ẹṣọ́, si wà nibẹ̀ pẹlu wa; awa si rọ́ wọn fun u, o si tumọ̀ alá wa fun wa, o tumọ̀ fun olukuluku gẹgẹ bi alá tirẹ̀.
13O si ṣe bi o ti tumọ̀ fun wa, bẹ̃li o si ri; emi li o mú pada si ipò iṣẹ mi, on li o si sorọ̀.
14Nigbana ni Farao ranṣẹ o si pè Josefu, nwọn si yara mú u jade kuro ninu ihò-túbu; o si fari rẹ̀, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si tọ̀ Farao wá.
15Farao sí wi fun Josefu pe, Emi lá alá, kò si si ẹnikan ti o le tumọ̀ rẹ̀: emi si gburó rẹ pe, bi iwọ ba gbọ́ alá, iwọ le tumọ̀ rẹ̀.
16Josefu si da Farao li ohùn pe, Ki iṣe emi: Ọlọrun ni yio fi idahùn alafia fun Farao.
17Farao si wi fun Josefu pe, Li oju-alá mi, kiyesi i, emi duro lori bèbe odò.
18Si kiyesi i, abo-malu meje ti o sanra, ti o si dara lati wò, jade lati inu odò na wa; nwọn si njẹ ni ẽsu-odò:
19Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o joro, ti o burujù ni wiwò, ti o si rù, jade soke lẹhin wọn, nwọn buru tobẹ̃ ti emi kò ri irú wọn rí ni ilẹ Egipti.
20Awọn abo-malu ti o rù, ti nwọn si buru ni wiwò, nwọn mú awọn abo-malu meje sisanra iṣaju wọnni jẹ:
21Nigbati nwọn si jẹ wọn tán, a kò le mọ̀ pe, nwọn ti jẹ wọn: nwọn si buru ni wiwò sibẹ̀ gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Bẹ̃ni mo jí.
22Mo si ri li oju-alá mi, si kiyesi i, ṣiri ọkà meje jade lara igi ọkà kan, o kún o si dara:
23Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje rirẹ̀, ti o si fori, ati ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu, o rú jade lẹhin wọn:
24Awọn ṣiri ti o fori si mú awọn ṣiri rere meje nì jẹ; mo si rọ́ ọ fun awọn amoye; ṣugbọn kò sí ẹniti o le sọ ọ fun mi.
25Josefu si wi fun Farao pe, Ọkan li alá Farao: Ọlọrun ti fi ohun ti on mbọ̀wá iṣe hàn fun Farao.
26Awọn abo-malu daradara meje nì, ọdún meje ni: ati ṣiri daradara meje nì, ọdún meje ni: ọkan li alá na.
27Ati awọn abo-malu meje nì ti o rù ti o si buru ni wiwò ti nwọn jade soke lẹhin wọn, ọdún meje ni; ati ṣiri ọkà meje ti o fori nì, ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu nì, ọdún meje ìyan ni yio jasi.
28Eyi li ohun ti mo ti wi fun Farao pe, ohun ti Ọlọrun mbọ̀wá iṣe, o ti fihàn fun Farao.
29Kiyesi i, ọdún meje ọ̀pọ mbọ̀ já gbogbo ilẹ Egipti:
30Lẹhin wọn ọdún meje ìyan si mbọ̀; gbogbo ọ̀pọ nì li a o si gbagbe ni ilẹ Egipti; ìyan na yio si run ilẹ;
31A ki yio si mọ̀ ọ̀pọ na mọ́ ni ilẹ nitori ìyan na ti yio tẹle e, nitori yio mú gidigidi.
32Nitorina li alá na ṣe dìlu ni meji fun Farao; nitoripe lati ọdọ Ọlọrun li a ti fi idi ọ̀ran na mulẹ, Ọlọrun yio si mú u ṣẹ kánkan.
33Njẹ nisisiyi, ki Farao ki o wò amoye ati ọlọgbọ́n ọkunrin kan, ki o si fi i ṣe olori ilẹ Egipti.
34Ki Farao ki o ṣe eyi, ki o si yàn awọn alabojuto si ilẹ yi, ki nwọn ki o si gbà idamarun ni ilẹ Egipti li ọdún meje ọ̀pọ nì.
35Ki nwọn ki o si kó gbogbo onjẹ ọdún meje rere nì ti o dé, ki nwọn ki o si tò ọkà jọ si ọwọ́ Farao, ki nwọn ki o si pa onjẹ mọ́ ni ilu wọnni.
36Onjẹ na ni yio si ṣe isigbẹ fun ilẹ dè ọdún meje ìyan na, ti mbọ̀wá si ilẹ Egipti; ki ilẹ ki o má ba run nitori ìyan na.
Wọ́n fi Josẹfu Jẹ Alákòóso Ilẹ̀ Ijipti
37Ohun na si dara li oju Farao, ati li oju gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.
38Farao si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A ha le ri ẹnikan bi irú eyi, ọkunrin ti Ẹmi Ọlọrun mbẹ ninu rẹ̀?
39Farao si wi fun Josefu pe, Niwọnbi Ọlọrun ti fi gbogbo nkan yi hàn ọ, kò sí ẹniti o ṣe amoye ati ọlọgbọ́n bi iwọ:
40Iwọ ni yio ṣe olori ile mi, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ li a o si ma ṣe akoso awọn enia mi: itẹ́ li emi o fi tobi jù ọ lọ:
41Farao si wi fun Josefu pe, Wò o, emi fi ọ jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti.
42Farao si bọ́ oruka ọwọ́ rẹ̀ kuro, o si fi bọ̀ Josefu li ọwọ́, o si wọ̀ ọ li aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si fi ẹ̀wọn wurà si i li ọrùn;
43O si mu u gùn kẹkẹ́ keji ti o ní; nwọn si nké niwaju rẹ̀ pe, Kabiyesi: o si fi i jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti.
44Farao si wi fun Josefu pe, Emi ni Farao, lẹhin rẹ ẹnikẹni kò gbọdọ gbé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ soke ni gbogbo ilẹ Egipti.
45Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti.
46Josefu si jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nigbati o duro niwaju Farao ọba Egipti. Josefu si jade kuro niwaju Farao, o si là gbogbo ilẹ Egipti já.
47Li ọdún meje ọ̀pọ nì, ilẹ si so eso ni ikunwọ-ikunwọ.
48O si kó gbogbo onjẹ ọdún meje nì jọ, ti o wà ni ilẹ Egipti, o si fi onjẹ na ṣura ni ilu wọnni: onjẹ oko ilu ti o yi i ká, on li o kójọ sinu rẹ̀.
49Josefu si kó ọkà jọ bi iyanrin okun lọ̀pọlọpọ; titi o fi dẹkun ati mã ṣirò; nitori ti kò ní iye.
50A si bí ọmọkunrin meji fun Josefu, ki ọdún ìyan na ki o to dé, ti Asenati bí fun u, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni.
51Josefu si sọ orukọ akọ́bi ni Manasse: wipe, Nitori ti Ọlọrun mu mi gbagbe gbogbo iṣẹ́ mi, ati gbogbo ile baba mi.
52Orukọ ekeji li o si sọ ni Efraimu: nitori Ọlọrun ti mu mi bisi i ni ilẹ ipọnju mi.
53Ọdún meje ọ̀pọ na ti o wà ni ilẹ Egipti si pari.
54Ọdún meje ìyan si bẹ̀rẹ si dé, gẹgẹ bi Josefu ti wi: ìyan na si mú ni ilẹ gbogbo; ṣugbọn ni gbogbo ilẹ Egipti li onjẹ gbé wà.
55Nigbati ìyan mú ni gbogbo ilẹ Egipti, awọn enia kigbe onjẹ tọ̀ Farao: Farao si wi fun gbogbo awọn ara Egipti pe, Ẹ ma tọ̀ Josefu lọ; ohunkohun ti o ba wi fun nyin ki ẹ ṣe.
56Ìyan na si wà lori ilẹ gbogbo: Josefu si ṣí gbogbo ile iṣura silẹ, o si ntà fun awọn ara Egipti; ìyan na si nmú si i ni ilẹ Egipti.
57Ilẹ gbogbo li o si wá si Egipti lati rà onjẹ lọdọ Josefu; nitori ti ìyan na mú gidigidi ni ilẹ gbogbo.

Currently Selected:

Gẹn 41: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in