Heb 13
13
Ìsìn Tí Ó Wu Ọlọrun
1KI ifẹ ará ki o wà titi.
2Ẹ máṣe gbagbé lati mã ṣe alejò; nitoripe nipa bẹ̃ li awọn ẹlomiran ṣe awọn angẹli li alejò laimọ̀.
3Ẹ mã ranti awọn onde bi ẹniti a dè pẹlu wọn, ati awọn ti a npọn loju bi ẹnyin tikaranyin pẹlu ti mbẹ ninu ara.
4Ki igbéyawo ki o li ọla larin gbogbo enia, ki akete si jẹ alailẽri: nitori awọn àgbere ati awọn panṣaga li Ọlọrun yio dá lẹjọ.
5Ki ọkàn nyin ki o máṣe fa si ifẹ owo, ki ohun ti ẹ ni ki o to nyin; nitori on tikalarẹ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ.
6Nitorina ni awa ṣe nfi igboiya wipe, Oluwa li oluranlọwọ mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi?
7Ẹ mã ranti awọn ti nwọn jẹ olori nyin, ti nwọn ti sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun nyin; ki ẹ mã ro opin ìwa-aiye wọn, ki ẹ si mã ṣe afarawe igbagbọ́ wọn.
8Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai.
9Ẹ máṣe jẹ ki a fi onirũru ati ẹkọ́ àjeji gbá nyin kiri. Nitori o dara ki a mu nyin li ọkàn le nipa ore-ọfẹ, kì iṣe nipa onjẹ, ninu eyiti awọn ti o ti nrìn ninu wọn kò li ère.
10Awa ni pẹpẹ kan, ninu eyi ti awọn ti nsìn agọ́ kò li agbara lati mã jẹ.
11Nitoripe ara awọn ẹran wọnni, ẹ̀jẹ eyiti olori alufa mu wá si ibi mimọ́ nitori ẹ̀ṣẹ, a sun wọn lẹhin ibudo.
12Nitorina Jesu pẹlu, ki o le fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ sọ awọn enia di mimọ́, o jìya lẹhin bode.
13Nitorina ẹ jẹ ki a jade tọ̀ ọ lọ lẹhin ibudo, ki a mã rù ẹ̀gan rẹ̀.
14Nitoripe awa kò ni ilu ti o wà titi nihin, ṣugbọn awa nwá eyiti mbọ̀.
15Njẹ nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ ki a mã ru ẹbọ iyìn si Ọlọrun nigbagbogbo, eyini ni eso ète wa, ti njẹwọ orukọ rẹ̀.
16Ṣugbọn ati mã ṣõre on ati mã pinfunni ẹ máṣe gbagbé: nitori irú ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ.
17Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin.
18Ẹ mã gbadura fun wa: nitori awa gbagbọ pe awa ni ẹri-ọkàn rere, a si nfẹ lati mã wà lododo ninu ohun gbogbo.
19Ṣugbọn emi mbẹ̀ nyin gidigidi si i lati mã ṣe eyi, ki a ba le tète fi mi fun nyin pada.
Ìdágbére
20Njẹ Ọlọrun alafia, ẹniti o tun mu oluṣọ-agutan nla ti awọn agutan, ti inu okú wá, nipa ẹ̀jẹ majẹmu aiyeraiye, ani Oluwa wa Jesu,
21Ki o mu nyin pé ninu iṣẹ rere gbogbo lati ṣe ifẹ rẹ̀, ki o mã ṣiṣẹ ohun ti iṣe itẹwọgba niwaju rẹ̀ ninu wa nipasẹ Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.
22Emi si mbẹ nyin, ará, ẹ gbà ọ̀rọ iyanju mi; nitori iwe kukuru ni mo kọ si nyin.
23Ẹ mọ̀ pé a dá Timotiu arakunrin wa silẹ; bi o ba tete de, emi pẹlu rẹ̀ yio ri nyin.
24Ẹ kí gbogbo awọn ti nṣe olori nyin, ati gbogbo awọn enia mimọ́. Awọn ti o ti Itali wá kí nyin.
25Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.
Currently Selected:
Heb 13: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.