Heb 6
6
1NITORINA ki a fi ipilẹṣẹ ẹkọ́ Kristi silẹ, ki a lọ si pipé; li aitún fi ipilẹ ironupiwada kuro ninu okú iṣẹ lelẹ, ati ti igbagbọ́ sipa ti Ọlọrun,
2Ati ti ẹkọ́ ti iwẹnu, ati ti igbọwọle-ni, ati ti ajinde okú, ati ti idajọ ainipẹkun.
3Eyi li awa ó si ṣe, bi Ọlọrun fẹ.
4Nitori awọn ti a ti là loju lẹ̃kan, ti nwọn si ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, ti nwọn si ti di alabapin Ẹmí Mimọ́,
5Ti nwọn si ti tọ́ ọ̀rọ rere Ọlọrun wò, ati agbara aiye ti mbọ̀,
6Ti nwọn si ti ṣubu kuro, ko le ṣe iṣe lati sọ wọn di ọtun si ironupiwada, nitori nwọn tún kàn Ọmọ Ọlọrun mọ agbelebu si ara wọn li ọtun, nwọn si dojutì i ni gbangba.
7Nitori ilẹ ti o fi omi ojò ti nrọ̀ sori rẹ̀ nigbagbogbo mu, ti o si nhù ewebẹ ti o dara fun awọn ti a nti itori wọn ro o pẹlu, ngbà ibukún lọwọ Ọlọrun.
8Ṣugbọn eyiti o nhù ẹgún ati oṣuṣu, a kọ̀ ọ, kò si jìna si egún; opin eyiti yio jẹ fun ijona.
9Ṣugbọn, olufẹ, awa ni igbagbọ ohun ti o dara jù bẹ̃ lọ niti nyin, ati ohun ti o faramọ igbala, bi awa tilẹ nsọ bayi.
10Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn enia mimọ́, ti ẹ si nṣe.
11Awa si fẹ ki olukuluku nyin ki o mã fi irú aisimi kanna hàn, fun ẹ̀kún ireti titi de opin:
12Ki ẹ máṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti nwọn ti ipa igbagbọ́ ati sũru jogún awọn ileri.
Ìlérí Ọlọrun Tí Ó Dájú
13Nitori nigbati Ọlọrun ṣe ileri fun Abrahamu, bi kò ti ri ẹniti o pọju on lati fi bura, o fi ara rẹ̀ bura, wipe,
14Nitõtọ ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bibisi emi o mu ọ bisi i.
15Bẹna si ni, lẹhin igbati o fi sũru duro, o ri ileri na gbà.
16Nitori enia a mã fi ẹniti o pọjù wọn bura: ibura na a si fi opin si gbogbo ijiyan wọn fun ifẹsẹ mulẹ ọ̀rọ.
17Ninu eyiti bi Ọlọrun ti nfẹ gidigidi lati fi aileyipada ìmọ rẹ̀ han fun awọn ajogún ileri, o fi ibura sãrin wọn.
18Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti o ti sá sabẹ ãbo le ni ìṣírí ti o daju lati dì ireti ti a gbé kalẹ niwaju wa mu:
19Eyiti awa ni bi idakọ̀ro ọkàn, ireti ti o daju ti o si duro ṣinṣin, ti o si wọ̀ inu ile lọ lẹhin aṣọ ikele;
20Nibiti aṣaju wa ti wọ̀ lọ fun wa, ani Jesu, ti a fi jẹ Olori Alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.
Currently Selected:
Heb 6: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.