Isa 15
15
OLUWA yóo Pa Moabu Run
1ỌRỌ-imọ̀ niti Moabu. Nitori li oru li a sọ Ari ti Moabu di ahoro, a si mu u dakẹ; nitori li oru li a sọ Kiri ti Moabu di ahoro, a si mu u dakẹ;
2On ti goke lọ si Bajiti, ati si Diboni, ibi giga wọnni, lati sọkun: Moabu yio hu lori Nebo, ati lori Medeba: gbogbo ori wọn ni yio pá, irungbọ̀n olukulùku li a o fá.
3Ni igboro ni wọn o da aṣọ-ọ̀fọ bò ara wọn: lori okè ilé wọn, ati ni igboro wọn, olukuluku yio hu, yio si ma sọkun pẹ̀rẹpẹ̀rẹ.
4Heṣboni yio si kigbe, ati Eleale: a o si gbọ́ ohùn wọn titi dé Jahasi: nitorina ni awọn ọmọ-ogun Moabu ti o hamọra yio kigbe soke; ọkàn rẹ̀ yio bajẹ fun ara rẹ̀.
5Ọkàn mi kigbe soke fun Moabu; awọn ìsánsá rẹ̀ sá de Soari, abo-malũ ọlọdun mẹta: ni gigun oke Luhiti tẹkúntẹkún ni nwọn o ma fi gùn u lọ; niti ọ̀na Horonaimu nwọn o gbe ohùn iparun soke.
6Nitori awọn omi Nimrimu yio di ahoro: nitori koriko nrọgbẹ, eweko nkú lọ, ohun tutù kan kò si.
7Nitorina ọ̀pọ eyi ti nwọn ti ni, ati eyi ti nwọn ti kojọ, ni nwọn o gbe kọja odò willo.
8Nitori igbe na ti yi agbegbè Moabu ka; igbe na si de Eglaimu, ati igbe na de Beerelimu.
9Nitori odò Dimoni yio kún fun ẹ̀jẹ: nitori emi o fi ibi miran sori Dimoni, emi o mu kiniun wá sori ẹniti ó sálà kuro ni Moabu, ati lori awọn ti o kù ni ilẹ na.
Currently Selected:
Isa 15: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.