Isa 27
27
1LI ọjọ na li Oluwa yio fi idà rẹ̀ mimú ti o tobi, ti o si wuwo bá lefiatani ejò ti nfò wi, ati lefiatani ejò wiwọ́ nì; on o si pa dragoni ti mbẹ li okun.
2Li ọjọ na ẹ kọrin si i, Ajàra ọti-waini pipọ́n.
3Emi Oluwa li o ṣọ ọ: emi o bù omi wọ́n ọ nigbakugba: ki ẹnikẹni má ba bà a jẹ, emi o ṣọ ọ ti oru ti ọsan.
4Irunú kò si ninu mi: tani le doju pantiri ẹlẹgun ati ẹgun kọ mi li ogun jijà? emi iba là wọn kọja, emi iba fi wọn jona pọ̀ ṣọ̀kan.
5Tabi jẹ ki o di agbara mi mu, ki o ba le ba mi lajà; yio si ba mi lajà.
6Yio mu ki awọn ti o ti Jakobu wá ta gbòngbo: Israeli yio tanna yio si rudi, yio si fi eso kún oju gbogbo aiye.
7On ha lù u bi o ti nlu awọn ti o lù u? a ha pa a gẹgẹ bi pipa awọn ti on pa?
8Niwọ̀n-niwọ̀n, nigba itìjade rẹ̀, iwọ o ba a wi: on ṣi ẹfũfu-ile rẹ̀ ni ipò li ọjọ ẹfũfu ilà-õrun.
9Nitorina nipa eyi li a o bò ẹ̀ṣẹ Jakobu mọlẹ: eyi si ni gbogbo eso lati mu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ kuro; nigbati on gbe okuta pẹpẹ kalẹ bi okuta ẹfun ti a lù wẹwẹ, igbó ati ere-õrun kì yio dide duro.
10Nitori ilu-olodi yio di ahoro, a o si kọ̀ ibugbé silẹ, a o si fi i silẹ bi aginju: nibẹ ni ọmọ-malu yio ma jẹ̀, nibẹ ni yio si dubulẹ, yio si jẹ ẹka rẹ̀ run.
11Nigbati ẹka inu rẹ̀ ba rọ, a o ya wọn kuro: awọn obinrin de, nwọn si tẹ̀ iná bọ̀ wọn: nitori alaini oye enia ni nwọn: nitorina ẹniti o dá wọn kì yio ṣãnu fun wọn, ẹniti o si mọ wọn kì yio fi ojurere hàn wọn.
12Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio ja eso kuro ni ibu odò si iṣàn Egipti, a o si ṣà nyin jọ li ọkọkan, ẹnyin ọmọ Israeli.
13Yio si ṣe li ọjọ na, a o fun ipè nla, awọn ti o mura lati ṣegbe ni ilẹ Assiria yio si wá, ati awọn aṣátì ilẹ Egipti, nwọn o si sìn Oluwa ni oke mimọ́ ni Jerusalemu.
Currently Selected:
Isa 27: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.