Isa 34
34
Ọlọrun Yóo Jẹ Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ níyà
1SUNMỌ tosí, ẹnyin orilẹ-ède lati gbọ́, tẹtisilẹ ẹnyin enia, jẹ ki aiye gbọ́, ati ẹ̀kun rẹ̀; aiye ati ohun gbogbo ti o ti inu rẹ̀ jade.
2Nitori ibinu Oluwa mbẹ lara gbogbo orilẹ-ède, ati irúnu rẹ̀ lori gbogbo ogun wọn: o ti pa wọn run patapata, o ti fi wọn fun pipa.
3Awọn ti a pa ninu wọn li a o si jù sode, õrùn wọn yio ti inu okú wọn jade, awọn oke-nla yio si yọ́ nipa ẹ̀jẹ wọn.
4Gbogbo awọn ogun ọrun ni yio di yiyọ́, a o si ká awọn ọrun jọ bi takàda, gbogbo ogun wọn yio si ṣubu lulẹ, bi ewe ti ibọ́ kuro lara àjara, ati bi bibọ́ eso lara igi ọ̀pọtọ́.
5Nitori ti a rẹ́ idà mi li ọrun, kiyesi i, yio sọkalẹ wá sori Idumea, ati sori awọn enia egún mi, fun idajọ.
6Idà Oluwa kun fun ẹ̀jẹ, a mu u sanra fun ọ̀ra, ati fun ẹ̀jẹ ọdọ-agutan ati ewurẹ, fun ọrá erẽ àgbo: nitoriti Oluwa ni irubọ kan ni Bosra, ati ipakupa nla kan ni ilẹ Idumea.
7Ati awọn agbanrere yio bá wọn sọkalẹ wá, ati awọn ẹgbọ̀rọ malu pẹlu awọn akọ malu; ilẹ wọn li a o fi ẹ̀jẹ rin, a o si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ra.
8Nitori ọjọ ẹsan Oluwa ni, ati ọdun isanpadà, nitori ọ̀ran Sioni.
9Odò rẹ̀ li a o si sọ di ọ̀dà, ati ekuru rẹ̀ di imi-õrun, ilẹ rẹ̀ yio si di ọ̀dà ti njona.
10A kì o pa a li oru tabi li ọsan; ẹ̃fin rẹ̀ yio goke lailai: yio dahoro lati iran de iran; kò si ẹnikan ti yio là a kọja lai ati lailai.
11Ṣugbọn ẹiyẹ ofú ati àkala ni yio ni i; ati owiwi ati iwò ni yio ma gbe inu rẹ̀: on o si nà okùn iparun sori rẹ̀, ati okuta ofo.
12Niti awọn ijoye rẹ̀ ẹnikan kì yio si nibẹ ti nwọn o pè wá si ijọba, gbogbo awọn olori rẹ̀ yio si di asan.
13Ẹgún yio si hù jade ninu ãfin rẹ̀ wọnni, ẹgún ọ̀gan ninu ilú olodi rẹ̀: yio jẹ ibugbé awọn dragoni, ati agbalá fun awọn owiwi.
14Awọn ẹran ijù ati awọn ọ̀wawa ni yio pade, ati satire kan yio ma kọ si ekeji rẹ̀; iwin yio ma gbe ibẹ̀ pẹlu, yio si ri ibí isimi fun ara rẹ̀.
15Owiwi yio tẹ́ itẹ́ rẹ̀ sibẹ̀, yio yé, yio si pa, yio si kojọ labẹ ojiji rẹ̀: awọn gúnugú yio pejọ sibẹ pẹlu, olukuluku pẹlu ẹnikeji rẹ̀.
16Ẹ wá a ninu iwe Oluwa, ẹ si kà a: ọkan ninu wọnyi kì yio yẹ̀, kò si ọkan ti yio fẹ́ ekeji rẹ̀ kù: nitori ẹnu mi on li o ti paṣẹ, ẹmi rẹ̀ li o ti ko wọn jọ.
17On ti dì ìbo fun wọn, ọwọ́ rẹ̀ si fi tita okùn pin i fun wọn: nwọn o jogun rẹ̀ lailai, lati iran de iran ni nwọn o ma gbe inu rẹ̀.
Currently Selected:
Isa 34: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.