Isa 40
40
Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Àwọn Ọmọ Israẹli
1Ẹ tù enia mi ninu, ẹ tù wọn ninu, ni Ọlọrun nyin wi.
2Ẹ sọ ọ̀rọ ìtunu fun Jerusalemu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedẽde rẹ jì: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ́ Oluwa wá fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo.
3Ohùn ẹniti nkigbe ni ijù, ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ṣe opópo titọ́ ni aginjù fun Ọlọrun wa.
4Gbogbo afonifoji ni a o gbe soke, gbogbo òke-nla ati òke kékèké ni a o si rẹ̀ silẹ: wiwọ́ ni a o si ṣe ni titọ́, ati ọ̀na pàlapala ni a o sọ di titẹ́ju:
5A o si fi ogo Oluwa hàn, gbogbo ẹran-ara ni yio jùmọ ri i: nitori ẹnu Oluwa li o sọ ọ.
6Ohùn na wipe, Kigbe. On si wipe, Igbe kini emi o ke? Gbogbo ẹran-ara ni koriko, gbogbo ogo rẹ̀ si dabi ìtànná igbẹ́:
7Koriko nrọ, ìtànná eweko nrẹ̀: nitoripe ẹmi Oluwa ti fẹ́ lù u: dajudaju koriko ni enia.
8Koriko nrọ, ìtànná nrẹ̀: ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun wa yio duro lailai.
9Iwọ onihinrere Sioni, gùn òke giga lọ: Iwọ onihin-rere Jerusalemu, gbé ohùn rẹ soke pẹlu agbara; gbé e soke, má bẹ̀ru; wi fun awọn ilu Juda pe, Ẹ wò Ọlọrun nyin!
10Kiyesi i, Oluwa Jehofah yio wá ninu agbara, apá rẹ̀ yio ṣe akoso fun u: kiyesi i, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ si mbẹ niwaju rẹ̀.
11On o bọ́ ọwọ-ẹran rẹ̀ bi oluṣọ-agùtan: yio si fi apá rẹ̀ ko awọn ọdọ-agùtan, yio si kó wọn si aiya rẹ̀, yio si rọra dà awọn ti o loyun.
OLUWA Kò Ní Àfijọ
12Tali o ti wọ̀n omi ni kòto-ọwọ́ rẹ̀, ti o si ti fi ika wọ̀n ọrun, ti o si ti kó erùpẹ aiye jọ sinu òṣuwọn, ti o si fi ìwọn wọ̀n awọn oke-nla, ati awọn oke kékèké ninu òṣuwọn?
13Tali o ti tọ́ Ẹmi Oluwa, tabi ti iṣe igbimọ̀ rẹ̀ ti o kọ́ ọ?
14Tali o mba a gbìmọ, tali o si kọ́ ọ lẹkọ́, ti o si kọ́ ọ ni ọ̀na idajọ, ti o si kọ́ ọ ni ìmọ, ti o si fi ọ̀na oye hàn a?
15Kiyesi i, awọn orilẹ-ède dabi iró kan ninu omi ladugbo, a si kà wọn bi ekúru kiun ninu ìwọn: kiyesi i, o nmu awọn erekùṣu bi ohun diẹ kiun.
16Lebanoni kò si tó fi joná, bẹ̃ni awọn ẹranko ibẹ kò to lati fi rubọ sisun.
17Gbogbo orilẹ-ède li o dabi ofo niwaju rẹ̀; a si kà wọn si fun u bi ohun ti o rẹ̀hin jù ofo ati asan lọ.
18Tali ẹnyin o ha fi Ọlọrun we? tabi awòran kini ẹnyin o fi ṣe akàwe rẹ̀?
19Oniṣọ̀na ngbẹ́ ère, alagbẹdẹ wura si nfi wura bò o, o si ndà ẹ̀wọn fadakà.
20Ẹniti o talakà tobẹ̃ ti kò fi ni ohun ọrẹ, yàn igi ti kì yio rà; o nwá ọlọgbọn oniṣọ̀na fun ara rẹ̀ lati gbẹ́ ère gbigbẹ́ ti a ki yio ṣi nipò.
21Ẹnyin kò ti mọ̀? ẹnyin kò ti gbọ́? a kò ti sọ fun nyin li atètekọṣe? kò iti yé nyin lati ipilẹṣẹ aiye wá?
22On ni ẹniti o joko lori òbíri aiye, gbogbo awọn ti ngbe ibẹ si dabi ẹlẹngà; ẹniti o ta ọrun bi ohun tita, ti o si nà wọn bi àgọ lati gbe.
23Ẹniti o nsọ awọn ọmọ-alade di ofo; o ṣe awọn onidajọ aiye bi asan.
24Nitõtọ, a kì yio gbìn wọn; nitõtọ, a kì yio sú wọn: nitõtọ igi wọn kì yio fi gbòngbo mulẹ: on o si fẹ́ lù wọn pẹlu, nwọn o si rọ, ãja yio si mu wọn lọ bi akekù koriko.
25Njẹ tani ẹnyin o ha fi mi we, tabi tali emi o ba dọgbà? ni Ẹni-Mimọ wi.
26Gbe oju nyin soke sibi giga, ki ẹ si wò, tali o dá nkan wọnyi, ti nmu ogun wọn jade wá ni iye: o npè gbogbo wọn li orukọ nipa titobi ipá rẹ̀, nitoripe on le ni ipá; kò si ọkan ti o kù.
27Ẽṣe ti iwọ fi nwi, Iwọ Jakobu, ti iwọ si nsọ, Iwọ Israeli pe, Ọ̀na mi pamọ kuro lọdọ Oluwa, idajọ mi si rekọja kuro lọdọ Ọlọrun mi?
28Iwọ kò ti imọ? iwọ kò ti igbọ́ pe, Ọlọrun aiyeraiye, Oluwa, Ẹlẹda gbogbo ipẹkun aiye, kì iṣãrẹ̀, bẹ̃ni ãrẹ̀ kì imu u? kò si awari oye rẹ̀.
29O nfi agbara fun alãrẹ̀; o si fi agbara kún awọn ti kò ni ipá.
30Ani ãrẹ̀ yio mu awọn ọdọmọde, yio si rẹ̀ wọn, ati awọn ọdọmọkunrin yio tilẹ ṣubu patapata:
31Ṣugbọn awọn ti o ba duro de Oluwa yio tun agbara wọn ṣe; nwọn o fi iyẹ́ gùn oke bi idì; nwọn o sare, kì yio si rẹ̀ wọn; nwọn o rìn, ãrẹ̀ kì yio si mu wọn.
Currently Selected:
Isa 40: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.