Isa 45
45
OLUWA Yan Kirusi
1BAYI ni Oluwa wi fun ẹni-ororo rẹ̀, fun Kirusi, ẹniti mo di ọwọ́ ọtún rẹ̀ mu, lati ṣẹ́gun awọn orilẹ-ède niwaju rẹ̀; emi o si tú amure ẹgbẹ awọn ọba, lati ṣi ilẹkùn mejeji niwaju rẹ̀, a ki yio si tì ẹnu-bode na;
2Emi o lọ siwaju rẹ, emi o si sọ ibi wiwọ́ wọnni di titọ́: emi o fọ ilẹkùn idẹ wọnni tũtũ, emi o si ke ọjá-irin si meji.
3Emi o si fi iṣura okùnkun fun ọ, ati ọrọ̀ ti a pamọ nibi ikọkọ, ki iwọ le mọ̀ pe, emi Oluwa, ti o pè ọ li orukọ rẹ, li Ọlọrun Israeli.
4Nitori Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ayanfẹ mi, emi ti pè ọ li orukọ rẹ: mo ti fi apele kan fun ọ, bi iwọ ko tilẹ ti mọ̀ mi.
5Emi li Oluwa, ko si ẹlomiran, kò si Ọlọrun kan lẹhin mi: mo dì ọ li àmure, bi iwọ kò tilẹ ti mọ̀ mi.
6Ki nwọn le mọ̀ lati ila-õrun, ati lati iwọ-õrun wá pe, ko si ẹnikan lẹhin mi; Emi ni Oluwa, ko si ẹlomiran.
7Mo dá imọlẹ, mo si dá okunkun: mo ṣe alafia, mo si dá ibi: Emi Oluwa li o ṣe gbogbo wọnyi.
8Kán silẹ, ẹnyin ọrun, lati oke wá, ki ẹ si jẹ ki ofurufu rọ̀ ododo silẹ; jẹ ki ilẹ ki o là, ki o si mu igbala jade; si jẹ ki ododo ki o hù soke pẹlu rẹ̀; Emi Oluwa li o dá a.
OLUWA Ẹlẹ́dàá Ayé ati Ìtàn
9Egbe ni fun ẹniti o mbá Elẹda rẹ̀ jà, apãdi ninu awọn apãdi ilẹ! Amọ̀ yio ha wi fun ẹniti o mọ ọ pe, Kini iwọ nṣe? tabi iṣẹ rẹ pe, On kò li ọwọ́?
10Egbe ni fun ẹniti o wi fun baba rẹ̀ pe, Kini iwọ bi? tabi fun obinrin nì pe, Kini iwọ bi?
11Bayi li Oluwa wi, Ẹni-Mimọ Israeli, ati Ẹlẹda rẹ̀, Bere nkan ti mbọ̀ lọwọ mi, niti awọn ọmọ mi ọkunrin, ati niti iṣẹ ọwọ mi, ẹ paṣẹ fun mi.
12Mo ti dá aiye, mo si ti da enia sori rẹ̀; Emi, ani ọwọ́ mi, li o ti nà awọn ọrun, gbogbo awọn ogun wọn ni mo si ti paṣẹ fun.
13Mo ti gbe e dide ninu ododo, emi o si mu gbogbo ọ̀na rẹ̀ tọ́; on o kọ́ ilu mi, yio si dá awọn ondè mi silẹ: ki iṣe fun iye owo tabi ère, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
14Bayi li Oluwa wi, pe, Ere iṣẹ Egipti, ati ọjà Etiopia ati ti awọn ara Sabea, awọn enia ti o ṣigbọnlẹ yio kọja wá sọdọ rẹ, nwọn o si jẹ tirẹ: nwọn o tẹle ọ; ninu ẹwọ̀n ni nwọn o kọja wá, nwọn o foribalẹ fun ọ, nwọn o si bẹ̀ ọ, wipe, Nitotọ Ọlọrun wà ninu rẹ; kò si si ẹlomiran, kò si Ọlọrun miran.
15Lõtọ iwọ li Ọlọrun ti o fi ara rẹ pamọ, Ọlọrun Israeli, Olugbala.
16Oju yio tì wọn, gbogbo wọn o si dãmu pọ̀; gbogbo awọn ti nṣe ere yio si jumọ lọ si idãmu.
17Ṣugbọn a o fi igbala ainipẹkun gba Israeli là ninu Oluwa: oju ki yio tì nyin, bẹ̃ni ẹ ki yio dãmu titi aiye ainipẹkun.
18Nitori bayi li Oluwa wi, ẹniti o dá awọn ọrun; Ọlọrun tikararẹ̀ ti o mọ aiye, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò da a lasan, o mọ ọ ki a le gbe inu rẹ̀: Emi ni Oluwa; ko si ẹlomiran.
19Emi kò sọrọ ni ikọkọ ni ibi okùnkun aiye: Emi kò wi fun iru-ọmọ Jakobu pe, Ẹ wá mi lasan: emi Oluwa li o nsọ ododo, mo fi nkan wọnni ti o tọ́ hàn.
OLUWA Gbogbo Ayé ati Àwọn Oriṣa Babiloni
20Ko ara nyin jọ ki ẹ si wá; ẹ jọ sunmọ tosi, ẹnyin ti o salà ninu awọn orilẹ-ède: awọn ti o gbé igi ere gbigbẹ́ wọn kò ni ìmọ, nwọn si gbadura si ọlọrun ti ko le gba ni.
21Ẹ sọ ọ, ki ẹ si mu wá, lõtọ, ki nwọn ki o jọ gbimọ̀ pọ̀: tali o mu ni gbọ́ eyi lati igbãni wa? tali o ti sọ ọ lati igba na wá? emi Oluwa kọ? ko si Ọlọrun miran pẹlu mi; Ọlọrun ododo ati Olugbala; ko si ẹlomiran lẹhin mi.
22Kọju si mi, ki a si gba nyin là, gbogbo opin aiye: nitori emi li Ọlọrun, ko si ẹlomiran.
23Mo ti fi ara mi bura, ọ̀rọ na ti ti ẹnu ododo mi jade, ki yio si pada, pe, Gbogbo ẽkún yio kunlẹ fun mi, gbogbọ ahọn yio bura.
24Lõtọ, a o wipe, ninu Oluwa li emi ni ododo ati agbara: sọdọ rẹ̀ ni gbogbo enia yio wá; oju o si tì gbogbo awọn ti o binu si i.
25Ninu Oluwa li a o dá gbogbo iru-ọmọ Israeli lare, nwọn o si ṣogo.
Currently Selected:
Isa 45: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.