Isa 47
47
Ìdájọ́ lórí Babiloni
1SỌKALẸ, si joko ninu ekuru, iwọ wundia ọmọbinrin Babiloni, joko ni ilẹ: itẹ́ kò si, iwọ ọmọbinrin ara Kaldea: nitori a kì o pè ọ ni ẹlẹ́gẹ on aláfẹ mọ.
2Gbe ọlọ, si lọ̀ iyẹfun, ṣi iboju rẹ, ká aṣọ ẹsẹ, ká aṣọ itan, là odo wọnni kọja.
3A o ṣi ihoho rẹ, a o si ri itiju rẹ pẹlu; emi o gbẹsan, enia kì yio sí lati da mi duro.
4Olurapada wa, Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀, Ẹni-Mimọ Israeli.
5Joko, dakẹ jẹ, lọ sinu okùnkun, iwọ ọmọbinrin ara Kaldea, nitori a ki yio pe ọ ni Iyálode awọn ijọba mọ.
6Emi ti binu si enia mi, emi ti sọ ilẹ ini mi di aimọ́, mo si ti fi wọn le ọ lọwọ: iwọ kò kãnu wọn, iwọ fi ajàga wuwo le awọn alagba lori.
7Iwọ si wipe, Emi o ma jẹ Iyalode titi lai: bẹ̃ni iwọ kò fi nkan wọnyi si aiya rẹ, bẹ̃ni iwọ kò ranti igbẹhin rẹ.
8Nitorina gbọ́ eyi, iwọ alafẹ́, ti o joko li ainani, ti o wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, kò si si ẹlomiran lẹhin mi: emi ki yio joko bi opo, bẹ̃ni emi ki yio mọ̀ òfo ọmọ.
9Ṣugbọn nkan meji wọnyi ni yio deba ọ li ojiji, li ọjọ kan, òfo ọmọ ati opo: nwọn o ba ọ perepere, nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ ajẹ́ rẹ, ati nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ afọṣẹ rẹ.
10Nitori ti iwọ ti gbẹkẹle ìwa buburu rẹ: iwọ ti wipe, Kò si ẹnikan ti o ri mi. Ọgbọ́n rẹ ati ìmọ rẹ, o ti mu ọ ṣinà; iwọ si ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, ko si ẹlomiran lẹhin mi.
11Nitorina ni ibi yio ṣe ba ọ; iwọ ki yio mọ̀ ibẹrẹ rẹ̀: ibi yio si ṣubu lù ọ; ti iwọ kì yio le mu kuro: idahoro yio deba ọ lojiji, iwọ kì yio si mọ̀.
12Duro nisisiyi, ti iwọ ti iṣẹ afọṣẹ rẹ, ati ọpọlọpọ iṣẹ ajẹ́ rẹ, eyi ti o ti fi nṣe iṣẹ iṣe lati igba ewe rẹ wá; bi o ba ṣepe o lè jẹ erè fun ọ, bi o ba ṣe pe iwọ lè bori.
13Arẹ̀ mu ọ nipa ọpọlọpọ ìgbimọ rẹ. Jẹ ki awọn awoye-ọrun, awọn awoye-irawọ, awọn afi-oṣupasọ-asọtẹlẹ, dide duro nisisiyi, ki nwọn si gbà ọ lọwọ nkan wọnyi ti yio ba ọ.
14Kiye si i, nwọn o dabi akekù koriko: iná yio jo wọn: nwọn ki yio gba ara wọn lọwọ agbara ọwọ́ iná; ẹyin iná kan ki yio si lati yá, tabi iná lati joko niwaju rẹ̀.
15Bayi ni awọn ti iwọ ti ba ṣiṣẹ yio jẹ fun ọ, awọn oniṣowo rẹ, lati ewe rẹ wá; nwọn o kiri lọ, olukuluku si ẹkùn rẹ̀; ko si ẹnikan ti yio gbà ọ.
Currently Selected:
Isa 47: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.