Isa 53
53
1TALI o ti gbà ihìn wa gbọ́? tali a si ti fi apá Oluwa hàn fun?
2Nitori yio dàgba niwaju rẹ̀ bi ọ̀jẹlẹ ohun ọ̀gbin, ati bi gbòngbo lati inu ilẹ gbigbẹ: irísi rẹ̀ kò dara, bẹ̃ni kò li ẹwà, nigbati a ba si ri i, kò li ẹwà ti a ba fi fẹ ẹ.
3A kẹgan rẹ̀ a si kọ̀ ọ lọdọ awọn enia, ẹni-ikãnu, ti o si mọ̀ ibanujẹ: o si dabi ẹnipe o mu ki a pa oju wa mọ kuro lara rẹ̀; a kẹgàn rẹ̀, awa kò si kà a si.
4Lõtọ o ti ru ibinujẹ wa, o si gbe ikãnu wa lọ; ṣugbọn awa kà a si bi ẹniti a nà, ti a lù lati ọdọ Ọlọrun, ti a si pọ́n loju.
5Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da.
6Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹ̀le ọ̀na ara rẹ̀; Oluwa si ti mu aiṣedede wa gbogbo pade lara rẹ̀.
7A jẹ ẹ ni iyà, a si pọ́n ọ loju, ṣugbọn on kò yà ẹnu rẹ̀: a mu u wá bi ọdọ-agutan fun pipa, ati bi agutan ti o yadi niwaju olurẹ́run rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀.
8A mu u jade lati ibi ihamọ on idajọ: tani o si sọ iran rẹ̀? nitori a ti ke e kuro ni ilẹ alãye: nitori irekọja awọn enia mi li a ṣe lù u.
9O si ṣe ibojì rẹ̀ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrọ̀ ni ikú rẹ̀; nitori kò hù iwà-ipa, bẹ̃ni kò si arekereke li ẹnu rẹ̀.
10Ṣugbọn o wu Oluwa lati pa a lara; o ti fi i sinu ibanujẹ; nigbati iwọ o fi ẹmi rẹ̀ ṣẹbọ fun ẹ̀ṣẹ: yio ri iru-ọmọ rẹ̀, yio mu ọjọ rẹ̀ gùn, ifẹ Oluwa yio ṣẹ li ọwọ́ rẹ̀.
11Yio ri ninu eso lãlã ọkàn rẹ̀, yio si tẹ́ ẹ li ọrùn: nipa imọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi olododo yio da ọ̀pọlọpọ lare; nitori yio rù aiṣedede wọn wọnni.
12Nitorina emi o fun u ni ipín pẹlu awọn ẹni-nla, yio si ba awọn alagbara pín ikogun, nitori o ti tú ẹmi rẹ̀ jade si ikú: a si kà a mọ awọn alarekọja, o si rù ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ; o si nṣipẹ̀ fun awọn alarekọja.
Currently Selected:
Isa 53: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.