A. Oni 19
19
Ọmọ Lefi Kan ati Obinrin Rẹ̀
1O si ṣe li ọjọ́ wọnni, nigbati kò sí ọba kan ni Israeli, ọkunrin Lefi kan nṣe atipo ni ìha ọhún ilẹ òke Efraimu, ẹniti o si mú àle kan lati Beti-lehemu-juda wá.
2Àle rẹ̀ na si ṣe panṣaga si i, o si lọ kuro lọdọ rẹ̀ si ile baba rẹ̀ si Beti-lehemu-juda, o si wà ni ibẹ̀ ni ìwọn oṣù mẹrin.
3Ọkọ rẹ̀ si dide, o si tọ̀ ọ lọ, lati tù u ninu, ati lati mú u pada, ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mbẹ pẹlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ meji: ọmọbinrin na si mú u wá sinu ile baba rẹ̀: nigbati baba rẹ̀ si ri i, o yọ̀ lati pade rẹ̀.
4Ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si da a duro; o si bá a joko ni ijọ́ mẹta; nwọn jẹ nwọn mu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.
5O si ṣe ni ijọ́ kẹrin, nwọn jí ni kùtukutu, o si dide lati lọ: baba ọmọbinrin na si wi fun ana rẹ̀ pe, Fi òkele onjẹ kan tẹlẹ inu, lẹhin na ki ẹ ma lọ.
6Nwọn si joko, awọn mejeji si jùmọ jẹ, nwọn si mu: baba ọmọbinrin na si wi fun ọkunrin na pe, Mo bẹ̀ ọ, farabalẹ, ki o si duro li oru oni, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn.
7Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, ana rẹ̀ si rọ̀ ọ, o si tun sùn sibẹ̀.
8On si dide ni kùtukutu ọjọ́ karun lati lọ, baba ọmọbinrin na si wipe, Mo bẹ̀ ọ, tù ara rẹ lara, ki ẹ si duro titi di irọlẹ; awọn mejeji si jẹun.
9Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, on, ati àle rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀, ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ọjọ́ di aṣalẹ tán, emi bẹ̀ ọ duro li oru yi: kiyesi i ọjọ́ lọ tán, sùn sihin, ki inu rẹ ki o le dùn: ni kùtukutu ọla ẹ tète bọ́ si ọ̀na nyin, ki iwọ ki o le lọ ile.
10Ọkunrin na si kọ̀ lati sùn, o si dide o si lọ, o si dé ọkankan Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): kẹtẹkẹtẹ meji ti a dì ni gãri wà lọdọ rẹ̀, àle rẹ̀ pẹlu si wà lọdọ rẹ̀.
11Nigbati nwọn si dé eti Jebusi, ọjọ́ lọ tán; ọmọ-ọdọ na si wi fun oluwa rẹ̀ pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a yà si ilu Jebusi yi, ki a si wọ̀ sibẹ̀.
12Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, Awa ki o yà si ilu ajeji kan, ti ki iṣe ti awọn ọmọ Israeli; awa o rekọja si Gibea.
13On si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Wá jẹ ki a sunmọ ọkan ninu ibi wọnyi; ki a si wọ̀ si Gibea, tabi Rama.
14Nwọn si rekọja, nwọn lọ: õrùn si wọ̀ bá wọn leti Gibea, ti iṣe ti Benjamini.
15Nwọn si yà si Gibea lati wọ̀ ọ, ati lati sùn nibẹ̀: o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, o joko ni igboro ilu na: nitoriti kò sí ẹnikan ti o gbà wọn sinu ile rẹ̀ lati wọ̀.
16Si kiyesi, i ọkunrin arugbo kan si nti ibi iṣẹ rẹ̀ bọ̀ lati inu oko wá li alẹ; ọkunrin na jẹ́ ara ilẹ òke Efraimu pẹlu, on si ṣe atipo ni Gibea: ṣugbọn ẹ̀ya Benjamini ni awọn ọkunrin ibẹ̀ iṣe.
17Nigbati o gbé oju rẹ̀ soke, o si ri èro kan ni igboro ilu; ọkunrin arugbo na si wipe, Nibo ni iwọ nrè? nibo ni iwọ si ti wá?
18On si wi fun u pe, Awa nrekọja lati Beti-lehemu-juda lọ si ìha ọhùn ilẹ òke Efraimu; lati ibẹ̀ li emi ti wá, emi si ti lọ si Beti-lehemu-juda: nisisiyi emi nlọ si ile OLUWA; kò si sí ẹnikan ti o gbà mi si ile.
19Bẹ̃ni koriko ati ohunjijẹ mbẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ wa; onjẹ ati ọti-waini si mbẹ fun mi pẹlu, ati fun iranṣẹbinrin rẹ, ati fun ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ awọn iranṣẹ rẹ: kò si sí ainí ohunkohun.
20Ọkunrin arugbo na si wipe, Alafia fun ọ; bi o ti wù ki o ri, jẹ ki gbogbo ainí rẹ ki o pọ̀ si apa ọdọ mi; ọkanṣoṣo ni, máṣe sùn si igboro.
21Bẹ̃li o mú u wá sinu ile rẹ̀, o si fi onjẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ: nwọn wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, nwọn jẹ nwọn si mu.
22Njẹ bi nwọn ti nṣe ariya, kiyesi i, awọn ọkunrin ilu na, awọn ọmọ Beliali kan, yi ile na ká, nwọn si nlù ilẹkun; nwọn si sọ fun bale ile na ọkunrin arugbo nì, pe, Mú ọkunrin ti o wọ̀ sinu ile rẹ nì wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ.
23Ọkunrin, bale ile na si jade tọ̀ wọn lọ, o si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ẹnyin arakunrin mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ má ṣe hùwa buburu; nitoriti ọkunrin yi ti wọ̀ ile mi, ẹ má ṣe hùwa wère yi.
24Kiyesi i, ọmọbinrin mi li eyi, wundia, ati àle rẹ̀; awọn li emi o mú jade wá nisisiyi, ki ẹnyin tẹ́ wọn li ogo, ki ẹnyin ṣe si wọn bi o ti tọ́ li oju nyin: ṣugbọn ọkunrin yi ni ki ẹnyin má ṣe hùwa wère yi si.
25Ṣugbọn awọn ọkunrin na kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀: ọkunrin na si mú àle rẹ̀, o si mú u tọ̀ wọn wá; nwọn si mọ̀ ọ, nwọn si hù u niwakiwa ni gbogbo oru na, titi o fi di owurọ̀: nigbati o si di afẹmọjumọ́ nwọn jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.
26Nigbana li obinrin na wá li àfẹmọjumọ́, o si ṣubu lulẹ, li ẹnu-ilẹkun ile ọkunrin na nibiti oluwa rẹ̀ gbé wà, titi ilẹ fi mọ́.
27Oluwa rẹ̀ si dide li owurọ̀, o si ṣi ilẹkun ile na, o si jade lati ba ọ̀na rẹ̀ lọ: si kiyesi i obinrin na, àle rẹ̀, ṣubu lulẹ li ẹnu-ilẹkun ile na, ọwọ́ rẹ̀ si wà li ẹnu-ọ̀na na.
28On si wi fun u pe, Dide, jẹ ki a ma lọ; ṣugbọn kò sí ẹniti o dahùn: nigbana li ọkunrin na si gbé e lé ori kẹtẹkẹtẹ, ọkunrin na si dide, o si lọ si ilu rẹ̀.
29Nigbati o dé ile rẹ̀, on si mú ọbẹ, o si mú àle rẹ̀ na, o si kun u ni-ike-ni-ike, o si pín i si ọ̀na mejila, o si rán a lọ si gbogbo àgbegbe Israeli.
30O si ṣe, ti gbogbo awọn ẹniti o ri i wipe, A kò ti ìhu irú ìwa bayi, bẹ̃li a kò ti iri i lati ọjọ́ ti awọn ọmọ Israeli ti gòke ti ilẹ Egipti wá titi o fi di oni-oloni: ẹ rò o, ẹ gbimọ̀, ki ẹ si sọ̀rọ.
Currently Selected:
A. Oni 19: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: