A. Oni 20
20
Israẹli Múra Ogun
1NIGBANA ni gbogbo awọn ọmọ Israeli jade lọ, ijọ awọn enia si wọjọ pọ̀ bi ọkunrin kan, lati Dani lọ titi o fi dé Beeri-ṣeba, pẹlu ilẹ Gileadi, si ọdọ OLUWA ni Mispa.
2Awọn olori gbogbo enia na, ani ti gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, si pésẹ̀ larin ijọ awọn enia Ọlọrun, ogún ọkẹ ọkunrin ẹlẹsẹ̀ ti o kọ idà.
3(Awọn ọmọ Benjamini si gbọ́ pe awọn ọmọ Israeli gòke lọ si Mispa.) Awọn ọmọ Israeli si wipe, Sọ fun wa, bawo ni ti ìwabuburu yi ti ri?
4Ọkunrin Lefi na, bale obinrin na ti a pa, dahùn wipe, Mo wá si Gibea ti iṣe ti Benjamini, emi ati àle mi, lati wọ̀.
5Awọn ọkunrin Gibea si dide si mi, nwọn si yi ile na ká mọ́ mi li oru; nwọn si rò lati pa mi, nwọn si ba àle mi ṣe iṣekuṣe, o si kú.
6Mo si mú àle mi, mo ke e wẹ́wẹ, mo si rán a lọ si gbogbo ilẹ-iní Israeli: nitoriti nwọn hù ìwakiwa ati ìwa wère ni Israeli.
7Kiyesi i, ọmọ Israeli ni gbogbo nyin ṣe, ẹ mú èro ati ìmọran nyin wá.
8Gbogbo awọn enia na si dide bi ọkunrin kan, wipe, Kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio wọ̀ inu agọ́ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni kò sí ẹnikẹni ti yio pada si ile rẹ̀.
9Ṣugbọn nisisiyi eyi li ohun ti a o ṣe si Gibea; awa ṣẹ keké, awa o si gòke lọ sibẹ̀;
10Awa o si mú ọkunrin mẹwa ninu ọgọrun jalẹ ni gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, ati ọgọrun ninu ẹgbẹrun, ati ẹgbẹrun ninu ẹgbãrun, lati mú onjẹ fun awọn enia na wá, ki nwọn ki o le ṣe, nigbati nwọn ba dé Gibea ti Benjamini, gẹgẹ bi gbogbo ìwa-wère ti nwọn hù ni Israeli.
11Bẹ̃ni gbogbo ọkunrin Israeli dó tì ilu na, nwọn fi ìmọ ṣọkan bi enia kan.
12Awọn ẹ̀ya Israeli si rán ọkunrin si gbogbo ẹ̀ya Benjamini, wipe, Ìwa buburu kili eyiti a hù lãrin nyin yi?
13Njẹ nisisiyi ẹ mu awọn ọkunrin na fun wa wá, awọn ọmọ Beliali, ti nwọn wà ni Gibea, ki awa ki o le pa wọn, ki awa ki o le mú ìwabuburu kuro ni Israeli. Ṣugbọn awọn ọmọ Benjamini kò fẹ́ fetisi ohùn awọn ọmọ Israeli awọn arakunrin wọn.
14Awọn ọmọ Benjamini si kó ara wọn jọ lati ilu wọnni wá si Gibea, lati jade lọ ibá awọn ọmọ Israeli jagun.
15A si kà awọn ọmọ Benjamini li ọjọ́ na, lati ilu wọnni wá, nwọn jẹ́ ẹgbã mẹtala ọkunrin ti nkọ idà, lẹhin awọn ara Gibea ti a kà, ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin.
16Ninu gbogbo awọn enia yi, a ri ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin aṣòsi; olukuluku wọn le gbọ̀n kànakana ba fọnrán owu li aitase.
17Ati awọn ọkunrin Israeli, li àika Benjamini, si jẹ́ ogún ọkẹ enia ti o nkọ idà: gbogbo awọn wọnyi si jẹ́ ologun.
Israẹli Bá Ẹ̀yà Bẹnjamini Jagun
18Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si lọ si Beti-eli nwọn si bère lọdọ Ọlọrun, wipe, Tani ninu wa ti yio tètekọ gòke lọ ibá awọn ọmọ Benjamini jà? OLUWA si wipe, Juda ni yio tète gòke lọ.
19Awọn ọmọ Israeli si dide li owurọ̀, nwọn si dótì Gibea.
20Awọn ọkunrin Israeli si jade lọ ibá Benjamini jà; awọn ọkunrin Israeli si tẹ́gun dè wọn ni Gibea.
21Awọn ọmọ Benjamini si ti Gibea jade wá, nwọn si pa ẹgba mọkanla enia ninu awọn ọmọ Israeli.
22Awọn enia na, awọn ọkunrin Israeli si gbà ara wọn niyanju, nwọn si tun tẹ́gun ni ibi ti nwọn kọ́ tẹ́gun si ni ijọ́ kini.
23(Awọn ọmọ Israeli si gòke lọ, nwọn si sọkun niwaju OLUWA titi di aṣalẹ, nwọn si bère lọdọ OLUWA wipe, Ki emi ki o si tun lọ ibá awọn ọmọ Benjamini arakunrin mi jà bi? OLUWA si wipe, Ẹ gòke tọ̀ ọ.)
24Awọn ọmọ Israeli si sunmọ awọn ọmọ Benjamini ni ijọ́ keji.
25Benjamini si jade si wọn lati Gibea wa ni ijọ́ keji, nwọn si pa ninu awọn ọmọ Israeli ẹgba mẹsan ọkunrin; gbogbo awọn wọnyi li o nkọ idà.
26Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati gbogbo awọn enia na gòke lọ, nwọn wá si Beti-eli, nwọn sọkun, nwọn si joko nibẹ̀ niwaju OLUWA, nwọn si gbàwẹ li ọjọ́ na titi di aṣalẹ; nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju OLUWA.
27Awọn ọmọ Israeli si bère lọdọ OLUWA, (nitori ti apoti majẹmu Ọlọrun mbẹ nibẹ̀ li ọjọ́ wọnni.
28Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni si nduro niwaju rẹ̀ li ọjọ́ wọnni,) wipe, Ki emi ki o ha si tun gbogun jade si Benjamini arakunrin mi bi? tabi ki emi ki o dẹkun? OLUWA si wipe, Ẹ gòke lọ; nitoripe li ọla emi o fi i lé ọ lọwọ.
29Israeli si yàn awọn enia ti o ba yi Gibea ká.
30Awọn ọmọ Israeli si gòke tọ̀ awọn ọmọ Benjamini lọ ni ijọ́ kẹta, nwọn si tẹ́gun si Gibea, gẹgẹ bi ìgba iṣaju.
31Awọn ọmọ Benjamini si jade tọ̀ awọn enia na lọ, a si fà wọn kuro ni ilu; nwọn si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn enia, nwọn npa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju; li opópo wọnni ti o lọ si Beti-eli, ati ekeji si Gibea, ni pápa, nwọn pa ìwọn ọgbọ̀n ọkunrin ninu Israeli.
32Awọn ọmọ Benjamini si wipe, A lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli wipe, Ẹ jẹ ki a sá, ki a si fà wọn kuro ni ìlú si opópo.
33Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si dide kuro ni ipò wọn, nwọn si tẹ́gun ni Baali-tamari: awọn ti o wà ni ibuba ninu awọn enia Israeli si dide kuro ni ipo wọn, lati pápa Gibea wá.
34Ẹgba marun ọkunrin ti a ti yàn ninu gbogbo Israeli si lọ si Gibea, ìja na si le gidigidi: ṣugbọn nwọn kò si mọ̀ pe ibi sunmọ wọn.
35OLUWA si kọlù Benjamini niwaju Israeli: awọn ọmọ Israeli si pa ẹgba mejila ọkunrin o le ẹdẹgbẹfa li ọjọ́ na ninu awọn enia Benjamini: gbogbo awọn wọnyi li o kọ́ idà.
Ìṣẹ́gun Israẹli
36Bẹ̃li awọn ọmọ Benjamini wa ri pe a ṣẹgun wọn: nitoriti awọn ọkunrin Israeli bìsẹhin fun awọn ara Benjamini nitoriti nwọn gbẹkẹle awọn ti o wà ni ibùba, ti nwọn yàn si eti Gibea.
37Awọn ti o wà ni ibùba si yára, nwọn rọ́wọ̀ Gibea; awọn ti o wà ni ibuba si papọ̀, nwọn si fi oju idà kọlù gbogbo ilu na.
38Njẹ àmi ti o wà lãrin awọn ọkunrin Israeli, ati awọn ti o wà ni ibùba ni pe, ki nwọn jẹ ki ẹ̃fi nla ki o rú soke lati ilu na wá.
39Nigbati awọn ọkunrin Israeli si pẹhinda ni ibi ìja na, Benjamini si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn ọkunrin Israeli, o si pa bi ọgbọ̀n enia: nitoriti nwọn wipe, Nitõtọ a lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìja iṣaju.
40Ṣugbọn nigbati awọsanma bẹ̀rẹsi rú soke lati ilu na wá pẹlu gọ́gọ ẹ̃fi, awọn ara Benjamini wò ẹhin wọn, si kiyesi i, ẹ̃fi gbogbo ilu na gòke lọ si ọrun.
41Awọn ọkunrin Israeli si yipada, awọn ọkunrin Benjamini si damu: nitoriti nwọn ri pe ibi déba wọn.
42Nitorina, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọkunrin Israeli si ọ̀na ijù; ṣugbọn ogun na lepa wọn kikan; ati awọn ti o ti ilu wọnni jade wá ni nwọn pa lãrin wọn.
43Bẹ̃ni nwọn rọgba yi Benjamini ká, nwọn lepa wọn, nwọn tẹ̀ wọn mọlẹ ni ibi isimi, li ọkankan Gibea si ìha ila-õrùn.
44Ẹgba mẹsan ọkunrin li o si ṣubu ninu awọn enia Benjamini, gbogbo awọn wọnyi li akọni ọkunrin.
45Nwọn si yipada nwọn sálọ si ìha ijù sori okuta Rimmoni: nwọn si ṣà ẹgbẹdọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn li opópo; nwọn lepa wọn kikan dé Gidomu, nwọn si pa ẹgba ọkunrin ninu wọn.
46Bẹ̃ni gbogbo awọn ti o ṣubu ni ijọ́ na ninu awọn ara Benjamini jẹ́ ẹgba mejila ọkunrin o le ẹgbẹrun ti o nkọ idà; gbogbo awọn wọnyi li akọni ọkunrin.
47Ṣugbọn ẹgbẹta ọkunrin yipada, nwọn si sá si ìha ijù si ibi okuta Rimmoni, nwọn si joko sinu okuta Rimmoni li oṣù mẹrin.
48Awọn ọkunrin Israeli si pada tọ̀ awọn ọmọ Benjamini, nwọn si fi oju idà kọlù gbogbo ilu, ati ẹran, ati ohun gbogbo ti nwọn ní: gbogbo ilu ti nwọn ri ni nwọn fi iná kun pẹlu.
Currently Selected:
A. Oni 20: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: